Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 42:1-38

42  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Jékọ́bù rí i pé hóró ọkà wà ní Íjíbítì.+ Nígbà náà ni Jékọ́bù sọ fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń bá a lọ ní wíwo ara yín lójú?”  Ó sì fi kún un pé: “Kíyè sí i, mo gbọ́ pé hóró ọkà wà ní Íjíbítì.+ Ẹ sọ̀ kalẹ̀ lọ síbẹ̀, kí ẹ sì rà fún wa láti ibẹ̀, kí a lè máa wà láàyè nìṣó, kí a má sì kú dànù.”  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, mẹ́wàá lára àwọn arákùnrin+ Jósẹ́fù sọ̀ kalẹ̀ lọ láti ra ọkà ní Íjíbítì.  Ṣùgbọ́n Jékọ́bù kò rán Bẹ́ńjámínì,+ arákùnrin Jósẹ́fù, pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ yòókù, nítorí tí ó sọ pé: “Kí jàǹbá aṣekúpani má bàa ṣẹlẹ̀ sí i.”+  Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì wá pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn mìíràn tí wọ́n ń bọ̀ láti ra oúnjẹ, nítorí pé ìyàn náà wà ní ilẹ̀ Kénáánì.+  Jósẹ́fù sì ni ẹni tí ó wà ní ipò agbára lórí ilẹ̀ náà.+ Òun ni ẹni tí ń tà á fún gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà.+ Nítorí náà, àwọn arákùnrin Jósẹ́fù wá, wọ́n sì tẹrí ba mọ́lẹ̀ fún un, ní dídojúbolẹ̀.+  Nígbà tí Jósẹ́fù rí àwọn arákùnrin rẹ̀, ó dá wọn mọ̀ lójú-ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n ó ṣe ara rẹ̀ ní ẹni tí kò ṣeé dá mọ̀ fún wọn.+ Nítorí náà, ó bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà lílekoko, ó sì wí fún wọn pé: “Ibo ni ẹ ti wá?” wọ́n sì dáhùn pé: “Láti ilẹ̀ Kénáánì, láti ra àwọn èlò oúnjẹ.”+  Nípa báyìí, Jósẹ́fù dá àwọn arákùnrin rẹ̀ mọ̀, ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn kò dá a mọ̀.  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jósẹ́fù rántí àwọn àlá tí ó ti lá nípa wọn,+ ó sì ń bá a lọ láti wí fún wọn pé: “Amí ni yín! Ẹ wá wo ipò ìṣísílẹ̀ ilẹ̀ yìí ni!”+ 10  Nígbà náà ni wọ́n sọ fún un pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, olúwa mi,+ ṣùgbọ́n àwa ìránṣẹ́ rẹ+ wá láti ra àwọn èlò oúnjẹ ni. 11  Gbogbo wa jẹ́ ọmọkùnrin ọkùnrin kan náà. Adúróṣánṣán ni wá. Àwa ìránṣẹ́ rẹ kì í ṣe amí.”+ 12  Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Nítorí pé ipò ìṣísílẹ̀ ilẹ̀ yìí ni ẹ wá wò!”+ 13  Látàrí èyí, wọ́n wí pé: “Arákùnrin méjìlá ni àwa ìránṣẹ́ rẹ.+ A jẹ́ ọmọkùnrin ọkùnrin kan náà+ ní ilẹ̀ Kénáánì; sì kíyè sí i, àbíkẹ́yìn wà pẹ̀lú baba wa lónìí,+ nígbà tí ó jẹ́ pé èyí èkejì kò sí mọ́.”+ 14  Bí ó ti wù kí ó rí, Jósẹ́fù wí fún wọn pé: “Ohun tí mo sọ fún yín náà ni ó jẹ́, pé, ‘Amí ni yín!’ 15  Èyí ni a óò fi dán yín wò. Bí Farao ti ń bẹ, ẹ̀yin kì yóò lọ kúrò níhìn-ín àyàfi ìgbà tí arákùnrin yín àbíkẹ́yìn bá wá síhìn-ín.+ 16  Ẹ rán ọ̀kan nínú yín, kí ó lọ mú arákùnrin yín wá, nígbà tí ẹ̀yin bá wà ní dídè, kí a lè dán ọ̀rọ̀ yín wò bóyá òtítọ́ ni ọ̀ràn yín jẹ́.+ Bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, nígbà náà, bí Farao ti ń bẹ, amí ni yín.” 17  Pẹ̀lú ìyẹn, wọ́n kó wọn pọ̀ sínú ìhámọ́ fún ọjọ́ mẹ́ta. 18  Lẹ́yìn ìyẹn, Jósẹ́fù sọ fún wọn ní ọjọ́ kẹta pé: “Ẹ ṣe èyí, kí ẹ sì máa wà láàyè nìṣó. Mo bẹ̀rù+ Ọlọ́run tòótọ́. 19  Bí ẹ bá jẹ́ adúróṣánṣán, ẹ jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin yín wà ní dídè ní ilé ìhámọ́ yín,+ ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin yòókù lọ, kí ẹ gbé hóró ọkà lọ nítorí ìyàn tí ó mú ní ilé yín.+ 20  Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin yóò mú arákùnrin yín àbíkẹ́yìn wá sọ́dọ̀ mi, kí a lè rí i pé ọ̀rọ̀ yín ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé; ẹ̀yin kì yóò sì kú.”+ Wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti ṣe bẹ́ẹ̀. 21  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ara wọn pé: “Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, a jẹ̀bi nípa arákùnrin wa,+ nítorí pé a rí wàhálà ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó fi taratara bẹ̀bẹ̀ fún ìyọ́nú lọ́dọ̀ wa, ṣùgbọ́n àwa kò fetí sílẹ̀. Ìdí nìyẹn tí wàhálà yìí fi dé bá wa.”+ 22  Nígbà náà ni Rúbẹ́nì dá wọn lóhùn pé: “Èmi kò ha sọ fún yín pé, ‘Ẹ má ṣe ṣẹ̀ sí ọmọ náà,’ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sílẹ̀?+ Kíyè sí i, ní báyìí, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a ń béèrè padà dájúdájú.”+ 23  Ní tiwọn, wọn kò mọ̀ pé Jósẹ́fù ń fetí sílẹ̀, nítorí pé olùtumọ̀ wà láàárín wọn. 24  Nítorí náà, ó kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún.+ Lẹ́yìn náà, ó padà sọ́dọ̀ wọn, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì mú Síméónì+ láàárín wọn, ó sì dè é lójú wọn.+ 25  Lẹ́yìn ìyẹn, Jósẹ́fù pàṣẹ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ọkà kún ìkóhunsí wọn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, kí a dá owó àwọn ọkùnrin náà padà sínú àpò ìdọ̀họ+ olúkúlùkù wọn, kí wọ́n sì fún wọn ní ìpèsè oúnjẹ fún ìrìn àjò.+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a ṣe fún wọn. 26  Nítorí náà, wọn di hóró ọkà wọn lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n láti ibẹ̀. 27  Nígbà tí ọ̀kan ṣí àpò ìdọ̀họ rẹ̀ láti fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní oúnjẹ ẹran ní ibùwọ̀,+ ó rí owó rẹ̀, òun rèé ní ẹnu àpò rẹ̀.+ 28  Látàrí ìyẹn, ó sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “A ti dá owó mi padà, nísinsìnyí, òun rèé nínú àpò mi!” Nígbà náà ni ọkàn-àyà wọn rẹ̀wẹ̀sì, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n yíjú sí ara wọn pẹ̀lú ìwárìrí,+ pé: “Kí ni Ọlọ́run ṣe fún wa yìí?”+ 29  Níkẹyìn, wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jékọ́bù baba wọn ní ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n sì sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn fún un, pé: 30  “Ọkùnrin tí ó jẹ́ olúwa ilẹ̀ náà bá wa sọ̀rọ̀ lọ́nà lílekoko,+ níwọ̀n bí ó ti fi wá pe àwọn ọkùnrin tí ń ṣe amí ilẹ̀ náà.+ 31  Ṣùgbọ́n a sọ fún un pé, ‘Adúróṣánṣán ni wá.+ A kì í ṣe amí. 32  Arákùnrin méjìlá ni wá,+ ọmọkùnrin baba wa.+ Ọ̀kan kò sí mọ́,+ àbíkẹ́yìn sì wà pẹ̀lú baba wa lónìí ní ilẹ̀ Kénáánì.’+ 33  Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà tí ó jẹ́ olúwa ilẹ̀ náà wí fún wa pé,+ ‘Èyí ni èmi yóò fi mọ̀ pé ẹ jẹ́ adúróṣánṣán:+ Ẹ jẹ́ kí arákùnrin yín kan dúró lọ́dọ̀ mi.+ Lẹ́yìn náà, kí ẹ mú nǹkan dání nítorí ìyàn ilé yín, kí ẹ sì lọ.+ 34  Kí ẹ sì mú arákùnrin yín àbíkẹ́yìn wá sọ́dọ̀ mi, kí èmi lè mọ̀ pé ẹ̀yin kì í ṣe amí ṣùgbọ́n pé adúróṣánṣán ni yín. Arákùnrin yín ni èmi yóò sì fún yín padà, ẹ̀yin sì lè máa ṣòwò nìṣó ní ilẹ̀ yìí.’”+ 35  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí wọ́n ń tú àpò ìdọ̀họ wọn síta, ìdì owó olúkúlùkù rèé nínù àpò ìdọ̀họ rẹ̀. Àwọn àti baba wọn sì wá rí ìdì owó wọn, àyà sì fò wọ́n. 36  Nígbà náà ni Jékọ́bù baba wọn fi ohùn rara sọ fún wọn pé: “Èmi ni ẹ mú kí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀!+ Jósẹ́fù kò sí mọ́, Síméónì kò sì sí mọ́,+ Bẹ́ńjámínì ni ẹ sì fẹ́ mú lọ! Orí mi ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá!” 37  Ṣùgbọ́n Rúbẹ́nì sọ fún baba rẹ̀ pé: “Ọmọkùnrin mi méjèèjì ni kí o fi ikú pa bí èmi kò bá mú un padà wá fún ọ.+ Fi í sí abẹ́ àbójútó mi, èmi ni yóò sì dá a padà fún ọ.”+ 38  Bí ó ti wù kí ó rí, ó sọ pé: “Ọmọkùnrin mi kì yóò bá yín sọ̀ kalẹ̀ lọ, nítorí pé arákùnrin rẹ̀ ti kú, òun nìkan ni ó sì ṣẹ́ kù.+ Bí jàǹbá aṣekúpani bá ṣẹlẹ̀ sí i lójú ọ̀nà tí ẹ ń lọ, nígbà náà, dájúdájú, ẹ̀yin yóò mú ewú mi sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú Ṣìọ́ọ̀lù+ pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé