Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 41:1-57

41  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òpin ọdún méjì gbáko, pé Fáráò lá àlá,+ sì kíyè sí i, ó dúró lẹ́bàá Odò Náílì.  Sì kíyè sí i, abo màlúù méje tí wọ́n lẹ́wà ní ìrísí, tí wọ́n sì sanra bọ̀rọ̀kọ̀tọ̀, ń gòkè bọ̀ láti inú Odò Náílì, wọ́n sì ń jẹ̀ láàárín koríko Náílì.+  Sì kíyè sí i, abo màlúù méje mìíràn ń gòkè bọ̀ tẹ̀ lé wọn láti inú Odò Náílì, wọ́n burẹ́wà ní ìrísí, wọ́n sì rù kannago,+ wọ́n sì mú ìdúró wọn lẹ́bàá àwọn abo màlúù náà ní bèbè Odò Náílì.  Nígbà náà ni àwọn abo màlúù tí wọ́n burẹ́wà ní ìrísí, tí wọ́n sì rù kannago, bẹ̀rẹ̀ sí jẹ abo màlúù méje tí wọ́n lẹ́wà ní ìrísí, tí wọ́n sì sanra.+ Látàrí èyí, Fáráò jí.+  Bí ó ti wù kí ó rí, ó padà sùn, ó sì lá àlá ní ìgbà kejì. Sì kíyè sí i, ṣírí ọkà méje wà, tí ń jáde wá láti ara pòròpórò kan, wọ́n sanra, wọ́n sì dára.+  Sì kíyè sí i, ṣírí ọkà méje, tí wọ́n tín-ín-rín, tí ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn sì ti jó gbẹ,+ tí ń dàgbà sókè, tẹ̀ lé wọn.+  Àwọn ṣírí ọkà tín-ín-rín náà bẹ̀rẹ̀ sí gbé ṣírí ọkà méje tí wọ́n sanra, tí wọ́n sì jẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ṣírí ọkà, mì.+ Látàrí èyí, Fáráò jí, sì kíyè sí i, àlá ni.  Ó sì wá ṣẹlẹ̀ ní òwúrọ̀ pé, ṣìbáṣìbo bá ẹ̀mí rẹ̀.+ Nítorí náà, ó ránṣẹ́ pe gbogbo àwọn àlùfáà pidánpidán Íjíbítì+ àti gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀,+ Fáráò sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ́ àwọn àlá rẹ̀ fún wọn.+ Ṣùgbọ́n kò sí olùtumọ̀ wọn fún Fáráò.  Nígbà náà ni olórí àwọn agbọ́tí bá Fáráò sọ̀rọ̀+ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ mi ni èmi ń mẹ́nu kàn lónìí.+ 10  Ìkannú Fáráò ru sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+ Nípa bẹ́ẹ̀, ó fi wọ́n sínú túbú ilé olórí ẹ̀ṣọ́,+ èmi àti olórí àwọn olùṣe búrẹ́dì. 11  Lẹ́yìn ìyẹn, àwa méjèèjì lá àlá ní òru kan, èmi àti òun. Olúkúlùkù wa lá àlá rẹ̀ pẹ̀lú ìtumọ̀ tirẹ̀.+ 12  Ọ̀dọ́kùnrin kan, tí í ṣe Hébérù,+ ìránṣẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́,+ sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú wa. Nígbà tí a rọ́ wọn fún un,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ àwọn àlá wa fún wa. Ó túmọ̀ rẹ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú àlá rẹ̀. 13  Ó sì wá ṣẹlẹ̀ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ṣe túmọ̀ rẹ̀ fún wa, bẹ́ẹ̀ ni ó rí. Èmi ni ó dá padà sí ipò iṣẹ́ mi,+ ṣùgbọ́n òun ni ó gbé kọ́.”+ 14  Fáráò sì tẹ̀ síwájú láti ránṣẹ́ pe Jósẹ́fù,+ kí wọ́n lè mú un wá kíákíá láti inú ihò ẹ̀wọ̀n.+ Nítorí náà, ó fá irun rẹ̀,+ ó sì pààrọ̀ aṣọ àlàbora rẹ̀,+ ó sì wọlé lọ bá Fáráò. 15  Nígbà náà ni Fáráò wí fún Jósẹ́fù pé: “Mo lá àlá kan, ṣùgbọ́n kò sí olùtumọ̀ rẹ̀. Wàyí o, èmi fúnra mi ti gbọ́ tí a sọ nípa rẹ pé o lè gbọ́ àlá kí o sì túmọ̀ rẹ̀.”+ 16  Látàrí èyí, Jósẹ́fù dá Fáráò lóhùn pé: “Èmi kò yẹ ní kíkà sí! Ọlọ́run yóò kéde àlàáfíà fún Fáráò.”+ 17  Fáráò sì ń bá a lọ láti bá Jósẹ́fù sọ̀rọ̀ pé: “Ní ojú àlá mi, kíyè sí i, mo dúró ní bèbè Odò Náílì. 18  Sì kíyè sí i, abo màlúù méje tí wọ́n sanra bọ̀rọ̀kọ̀tọ̀ tí wọ́n sì lẹ́wà ní ìrísí ń gòkè láti inú Odò Náílì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ̀ láàárín koríko Náílì.+ 19  Sì kíyè sí i, abo màlúù méje mìíràn ń gòkè bọ̀ tẹ̀ lé wọn, wọ́n rí rán-un-ràn-un, ìrísí wọ́n sì burú gan-an ni, wọ́n sì rù kannago.+ Ní ti bíburú, èmi kò tíì rí èyí tí ó dà bí wọn rí ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. 20  Àwọn abo màlúù tí wọ́n rù hangogo náà sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ abo màlúù méje àkọ́kọ́ tí wọ́n sanra.+ 21  Nítorí náà, ìwọ̀nyí wọnú ikùn wọn, síbẹ̀ a kò sì lè mọ̀ pé wọ́n ti wọnú ikùn wọn, níwọ̀n bí ìrísí wọ́n ti burú gan-an gẹ́gẹ́ bí ti àkọ́kọ́.+ Látàrí èyí, mo jí. 22  “Lẹ́yìn ìyẹn, mo rí i nínú àlá mi, sì kíyè sí i, ṣírí ọkà méje ń jáde bọ̀ láti ara pòròpórò kan, ó kún, ó sì dára.+ 23  Sì kíyè sí i, ṣírí ọkà méje tí ó kíweje, tí ó tín-ín-rín, tí ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn jó gbẹ,+ ń dàgbà sókè lẹ́yìn wọn. 24  Àwọn ṣírí ọkà tí wọ́n tín-ín-rín sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ṣírí ọkà méje tí ó dára mì.+ Nítorí náà, mo ṣàlàyé fún àwọn àlùfáà pidánpidán,+ ṣùgbọ́n kò sí ìkankan tí ó sọ fún mi.”+ 25  Nígbà náà, Jósẹ́fù sọ fún Fáráò pé: “Àlá Fáráò jẹ́ ọ̀kan. Ohun tí Ọlọ́run tòótọ́ fẹ́ ṣe ni ó sọ fún Fáráò.+ 26  Abo màlúù méje dídára náà jẹ́ ọdún méje. Bákan náà, àwọn ṣírí ọkà méje dídára náà jẹ́ ọdún méje. Ọ̀kan náà ni àlá náà. 27  Abo màlúù méje tí wọ́n rù hangogo, tí wọ́n sì burú tí wọ́n jáde wá lẹ́yìn wọn jẹ́ ọdún méje; òfìfo ṣírí ọkà méje, tí ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn jó gbẹ,+ yóò jẹ́ ọdún méje ìyàn.+ 28  Èyí ni ohun tí mo sọ fún Fáráò: Ohun tí Ọlọ́run tòótọ́ fẹ́ ṣe ni òun jẹ́ kí Fáráò rí.+ 29  “Kíyè sí i, ọdún méje ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ńláǹlà ń bọ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. 30  Ṣùgbọ́n ọdún méje ìyàn yóò dé lẹ́yìn wọn dájúdájú, gbogbo ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ilẹ̀ Íjíbítì ni a ó sì gbàgbé dájúdájú, ìyàn náà yóò sì wulẹ̀ jẹ ilẹ̀ náà run.+ 31  Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìgbà kan rí ní ilẹ̀ náà ni a kì yóò sì mọ̀ nítorí ìyàn ẹ̀yìn ìgbà náà, nítorí ó dájú pé yóò mú gidigidi. 32  Òtítọ́ náà pé àlá náà ni a sì fi han Fáráò lẹ́ẹ̀mejì túmọ̀ sí pé nǹkan náà fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní ìhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́,+ Ọlọ́run tòótọ́ sì ń yára kánkán láti ṣe é.+ 33  “Ǹjẹ́ nísinsìnyí, kí Fáráò wá ọkùnrin kan tí ó jẹ́ olóye, tí ó sì gbọ́n, kí ó yàn án sórí ilẹ̀ Íjíbítì.+ 34  Kí Fáráò gbé ìgbésẹ̀, kí ó sì yan àwọn alábòójútó sípò lórí ilẹ̀ náà,+ kí ó sì gba ìdá márùn-ún ilẹ̀ Íjíbítì ní ọdún méje ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ.+ 35  Kí wọ́n sì kó gbogbo àwọn èlò oúnjẹ ti àwọn ọdún dáadáa tí ń bọ̀ wọ̀nyí jọ, kí wọ́n sì to ọkà jọ pelemọ lábẹ́ ọwọ́ Fáráò gẹ́gẹ́ bí àwọn èlò oúnjẹ nínú àwọn ìlú ńlá,+ kí wọ́n sì fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ. 36  Kí àwọn èlò oúnjẹ náà sì jẹ́ ìpèsè fún ilẹ̀ náà fún ọdún méje ìyàn, tí yóò mú ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ kí ìyàn náà má bàa ké ilẹ̀ náà kúrò.”+ 37  Tóò, ohun náà dára ní ojú Fáráò àti ní ojú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+ 38  Nítorí náà, Fáráò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ a lè rí ọkùnrin mìíràn tí ó dà bí ẹni yìí, tí ẹ̀mí Ọlọ́run wà nínú rẹ̀?”+ 39  Lẹ́yìn ìyẹn, Fáráò wí fún Jósẹ́fù pé: “Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti jẹ́ kí o mọ gbogbo èyí,+ kò sí ẹnì kankan tí ó jẹ́ olóye, tí ó sì gbọ́n tó ọ.+ 40  Ìwọ fúnra rẹ ni yóò ṣolórí ilé mi,+ gbogbo àwọn ènìyàn mi yóò sì fi gbogbo ara ṣègbọràn sí ọ.+ Lórí ọ̀ràn ìtẹ́ nìkan ni èmi yóò ti pọ̀ jù ọ́ lọ.”+ 41  Fáráò sì fi kún un fún Jósẹ́fù pé: “Wò ó, mo fi ọ́ ṣolórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.”+ 42  Pẹ̀lú ìyẹn, Fáráò mú òrùka àmì àṣẹ+ rẹ̀ kúrò ní ọwọ́ ara rẹ̀, ó sì fi í sí ọwọ́ Jósẹ́fù, ó sì fi ẹ̀wù aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà wọ̀ ọ́, ó sì fi ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tí a fi wúrà ṣe sí ọrùn rẹ̀.+ 43  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó mú un gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin kejì ti ọlá tí ó ní,+ kí wọ́n lè máa lọgun níwájú rẹ̀ pé, “Áfírékì!” tí a sì tipa báyìí fi í ṣólórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. 44  Fáráò sì wí fún Jósẹ́fù síwájú sí i pé: “Èmi ni Fáráò, ṣùgbọ́n láìsí ọlá àṣẹ rẹ, ẹnì kankan kò gbọ́dọ̀ gbé ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.”+ 45  Lẹ́yìn náà, Fáráò pe orúkọ Jósẹ́fù ní Safenati-pánéà, ó sì fi Ásénátì+ ọmọbìnrin Pọ́tíférà àlùfáà Ónì+ fún un gẹ́gẹ́ bí aya. Jósẹ́fù sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ káàkiri lórí ilẹ̀ Íjíbítì.+ 46  Jósẹ́fù sì jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún+ nígbà tí ó dúró níwájú Fáráò ọba Íjíbítì. Nígbà náà ni Jósẹ́fù jáde kúrò níwájú Fáráò, tí ó sì rìn kiri gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. 47  Ní ọdún méje ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ, ilẹ̀ náà sì ń so ní ẹ̀kúnwọ́-ẹ̀kúnwọ́.+ 48  Ó sì ń kó gbogbo àwọn èlò oúnjẹ ọdún méje tí ó dé sórí ilẹ̀ Íjíbítì jọ, òun a sì kó àwọn èlò oúnjẹ náà sínú àwọn ìlú ńlá.+ Àwọn èlò oúnjẹ pápá tí ó yí ìlú ńlá kan ká ni ó kó sí àárín rẹ̀.+ 49  Jósẹ́fù sì ń bá a lọ láti to ọkà jọ pelemọ ní ìwọ̀n púpọ̀ rẹpẹtẹ,+ bí iyanrìn òkun, tí ó fi jẹ́ pé, níkẹyìn, wọ́n jáwọ́ nínú kíkà á, nítorí pé kò níye.+ 50  Kí ọdún ìyàn sì tó dé, a bí ọmọkùnrin méjì fún Jósẹ́fù,+ tí Ásénátì ọmọbìnrin Pọ́tíférà àlùfáà Ónì bí fún un. 51  Nítorí náà, Jósẹ́fù pe orúkọ àkọ́bí ní Mánásè,+ nítorí pé, láti fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ, “Ọlọ́run ti mú kí n gbàgbé gbogbo ìdààmú mi àti gbogbo ilé baba mi.”+ 52  Orúkọ èkejì sì ni ó pè ní Éfúráímù,+ nítorí pé, láti fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ, “Ọlọ́run ti mú kí n so èso ní ilẹ̀ ipò ìráre mi.”+ 53  Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọdún méje ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ó ti wà ní ilẹ̀ Íjíbítì dópin,+ 54  ẹ̀wẹ̀, ọdún méje ìyàn sì dé, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jósẹ́fù ti wí.+ Ìyàn náà sì mú ní ilẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n oúnjẹ wà ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.+ 55  Níkẹyìn, ìyàn mú ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, àwọn ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Fáráò fún oúnjẹ.+ Nígbà náà, Fáráò sọ fún gbogbo ará Íjíbítì pé: “Ẹ lọ bá Jósẹ́fù. Ohun yòówù tí ó bá wí fún yín ni kí ẹ ṣe.”+ 56  Ìyàn náà sì wà lórí gbogbo ilẹ̀.+ Nígbà náà ni Jósẹ́fù bẹ̀rẹ̀ sí ṣí gbogbo àká ọkà tí ó wà ní àárín wọn, ó sì ń tà á fún àwọn ará Íjíbítì,+ nítorí ìyàn náà ti mú gidigidi lórí ilẹ̀ Íjíbítì. 57  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn ènìyàn gbogbo ilẹ̀ wá sí Íjíbítì láti ra oúnjẹ lọ́dọ̀ Jósẹ́fù, nítorí pé ìyàn náà mú gidigidi ní gbogbo ilẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé