Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 40:1-23

40  Wàyí o, lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ó ṣẹlẹ̀ pé agbọ́tí+ ọba Íjíbítì àti olùṣe búrẹ́dì ṣẹ̀ sí olúwa wọn, ọba Íjíbítì.+  Ìkannú Fáráò sì ru sí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ méjèèjì,+ sí olórí àwọn agbọ́tí àti sí olórí àwọn olùṣe búrẹ́dì.+  Nítorí náà, ó fi wọ́n sínú túbú ilé olórí ẹ̀ṣọ́,+ sí ilé ẹ̀wọ̀n,+ níbi tí Jósẹ́fù ti jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n.  Nígbà náà, olórí ẹ̀ṣọ́ yan Jósẹ́fù láti wà pẹ̀lú wọn kí ó lè máa ṣèránṣẹ́ fún wọn;+ wọ́n sì ń bá a lọ láti wà nínú túbú fún ọjọ́ mélòó kan.  Àwọn méjèèjì sì bẹ̀rẹ̀ sí lá àlá,+ olúkúlùkù pẹ̀lú àlá tirẹ̀ ní òru kan,+ olúkúlùkù pẹ̀lú àlá rẹ̀ tí ó ní ìtumọ̀ tirẹ̀,+ agbọ́tí àti olùṣe búrẹ́dì tí wọ́n jẹ́ ti ọba Íjíbítì, àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n nínú ilé ẹ̀wọ̀n.+  Nígbà tí Jósẹ́fù wọlé wá bá wọn ní òwúrọ̀ tí ó sì rí wọn, họ́wù, kíyè sí i, ojú wọn rẹ̀wẹ̀sì.+  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wádìí lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ Fáráò tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú túbú ilé ọ̀gá rẹ̀ pé: “Kí ni ìdí tí ojú yín fi dá gùdẹ̀ lónìí?”+  Látàrí èyí, wọ́n wí fún un pé: “A lá àlá kan, kò sì sí olùtumọ̀ lọ́dọ̀ wa.” Nítorí náà Jósẹ́fù wí fún wọn pé: “Ìtúmọ̀ kò ha jẹ́ ti Ọlọ́run?+ Ẹ rọ́ ọ fún mi, ẹ jọ̀wọ́.”  Olórí àwọn agbọ́tí sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ́ àlá rẹ̀ fún Jósẹ́fù, ó sì wí fún un pé: “Lójú àlá mi, họ́wù, kíyè sí i, àjàrà kan wà ní iwájú mi. 10  Lórí àjàrà náà sì ni ẹ̀ka igi mẹ́ta wà, ó sì ń yọ ọ̀mùnú.+ Ìtànná rẹ̀ yọ jáde. Òṣùṣù rẹ̀ mú èso àjàrà wọn pọ́n. 11  Ife Fáráò sì wà ní ọwọ́ mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí mú èso àjàrà náà, mo sì fún wọn sínú ife Fáráò.+ Lẹ́yìn ìyẹn, mo gbé ife náà lé Fáráò lọ́wọ́.”+ 12  Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí fún un pé: “Èyí ni ìtumọ̀ rẹ̀:+ Ẹ̀ka igi mẹ́ta náà jẹ́ ọjọ́ mẹ́ta. 13  Ní ọjọ́ mẹ́ta òní, dájúdájú, Fáráò yóò gbé orí rẹ sókè, yóò sì dá ọ padà sí ipò iṣẹ́ rẹ;+ dájúdájú, ìwọ yóò gbé ife Fáráò lé e lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àtijọ́, nígbà tí ìwọ ń ṣe agbọ́tí rẹ̀.+ 14  Bí ó ti wù kí ó rí, gbàrà tí nǹkan bá ti ń lọ dáadáa fún ọ,+ kí o rántí mi, kí o sì jọ̀wọ́ ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí mi, kí o sì sọ nípa mi fún Fáráò,+ kí o sì mú mi jáde kúrò nínú ilé yìí. 15  Nítorí ní tòótọ́, a jí mi gbé kúrò ní ilẹ̀ àwọn Hébérù ni;+ àti pé níhìn-ín pẹ̀lú, èmi kò ṣe nǹkan kan rárá tí ó yẹ kí a tìtorí rẹ̀ fi mí sínú ihò ẹ̀wọ̀n.”+ 16  Nígbà tí olórí àwọn olùṣe búrẹ́dì rí i pé ó ti túmọ̀ ohun tí ó dára, òun, ẹ̀wẹ̀, sọ fún Jósẹ́fù pé: “Èmi náà wà lójú àlá mi, sì kíyè sí i, apẹ̀rẹ̀ mẹ́ta búrẹ́dì funfun wà lórí mi, 17  nínú apẹ̀rẹ̀ ti ó wà lókè pátápátá sì ni onírúurú gbogbo ohun jíjẹ wà fún Fáráò,+ àmújáde olùṣe búrẹ́dì, àwọn ẹ̀dá abìyẹ́+ sì wà tí wọ́n ń jẹ wọ́n nínú apẹ̀rẹ̀ tí ó wà ní orí mi.” 18  Nígbà náà ni Jósẹ́fù dáhùn pé: “Èyí ni ìtumọ̀ rẹ̀:+ Apẹ̀rẹ̀ mẹ́ta náà jẹ́ ọjọ́ mẹ́ta. 19  Ní ọjọ́ mẹ́ta òní, Fáráò yóò gbé orí rẹ sókè kúrò lọ́rùn rẹ, dájúdájú, òun yóò gbé ọ kọ́ sórí òpó igi;+ dájúdájú, àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ yóò jẹ ẹran ara rẹ kúrò lára rẹ.”+ 20  Wàyí o, ọjọ́ kẹta wá jẹ́ ọjọ́ ìbí Fáráò,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí se àsè fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì gbé orí olórí àwọn agbọ́tí sókè àti orí olórí àwọn olùṣe búrẹ́dì ní àárín àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+ 21  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó dá olórí àwọn agbọ́tí padà sí ipò agbọ́tí rẹ̀,+ òun sì ń bá a lọ láti gbé ife lé Fáráò lọ́wọ́. 22  Ṣùgbọ́n olórí àwọn olùṣe búrẹ́dì ni ó gbé kọ́,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jósẹ́fù ti fún wọn ní ìtumọ̀ náà.+ 23  Bí ó ti wù kí ó rí, olórí àwọn agbọ́tí náà kò rántí Jósẹ́fù, ó sì ń bá a lọ láti gbàgbé rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé