Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 4:1-26

4  Wàyí o, Ádámù ní ìbádàpọ̀ pẹ̀lú Éfà aya rẹ̀, ó sì lóyún.+ Nígbà tí ó ṣe, ó bí Kéènì,+ ó sì wí pé: “Mo ti mú ọkùnrin kan jáde nípasẹ̀ àrànṣe Jèhófà.”+  Lẹ́yìn náà, ó tún bí arákùnrin rẹ̀, Ébẹ́lì.+ Ébẹ́lì sì wá jẹ́ ẹni tí ń da àgùntàn,+ ṣùgbọ́n Kéènì di ẹni tí ń ro ilẹ̀.+  Ó ṣẹlẹ̀ pé, ní òpin àwọn àkókò kan, Kéènì tẹ̀ síwájú láti mú àwọn èso kan tí ilẹ̀+ mú jáde, wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fún Jèhófà.+  Ṣùgbọ́n ní ti Ébẹ́lì, òun pẹ̀lú mú àwọn àkọ́bí+ nínú agbo ẹran rẹ̀ wá, àní àwọn apá tí ó lọ́ràá+ nínú wọn. Wàyí o, nígbà tí Jèhófà fi ojú rere wo Ébẹ́lì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀,+  òun kò fi ojú rere kankan wo Kéènì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀.+ Ìbínú+ Kéènì sì gbóná gidigidi, ojú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí rẹ̀wẹ̀sì.  Látàrí èyí, Jèhófà sọ fún Kéènì pé: “Èé ṣe tí ìbínú rẹ fi gbóná, èé sì ti ṣe tí ojú rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì?  Bí ìwọ bá yíjú sí ṣíṣe rere, ara rẹ kò ha ní yá gágá bí?+ Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá yíjú sí ṣíṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ lúgọ sí ẹnu ọ̀nà, ìfàsí-ọkàn rẹ̀ sì wà fún ọ;+ ní tìrẹ, ìwọ yóò ha sì kápá rẹ̀ bí?”+  Lẹ́yìn ìyẹn, Kéènì sọ fún Ébẹ́lì arákùnrin rẹ̀ pé: [“Jẹ́ kí a kọjá lọ sínú pápá.”] Ó wá ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí wọ́n wà nínú pápá, Kéènì bẹ̀rẹ̀ sí fipá kọlu Ébẹ́lì arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á.+  Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Kéènì pé: “Ibo ni Ébẹ́lì arákùnrin rẹ wà?”+ òun sì sọ pé: “Èmi kò mọ̀. Èmi ha ni olùtọ́jú arákùnrin mi bí?”+ 10  Látàrí èyí, ó wí pé: “Kí ni ìwọ ṣe? Fetí sílẹ̀! Ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń ké jáde sí mi láti inú ilẹ̀.+ 11  Wàyí o, a fi ọ́ gégùn-ún ní lílé ọ kúrò lórí ilẹ̀,+ èyí tí ó la ẹnu rẹ̀ láti gba ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ lọ́wọ́ rẹ.+ 12  Nígbà tí o bá ro ilẹ̀, kì yóò fi agbára+ rẹ̀ fún ọ padà. Alárìnká àti ìsáǹsá ni ìwọ yóò dà ní ilẹ̀ ayé.”+ 13  Látàrí èyí, Kéènì sọ fún Jèhófà pé: “Ìyà ìṣìnà mi pọ̀ jù fún mi láti rù. 14  Kíyè sí i, ìwọ ní ti tòótọ́ ń lé mi ní òní yìí kúrò ní ojú ilẹ̀, a ó sì fi mí pa mọ́ kúrò ní ojú rẹ;+ èmi yóò sì di alárìnká+ àti ìsáǹsá lórí ilẹ̀ ayé, ó sì dájú pé ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi yóò pa mí.”+ 15  Látàrí èyí, Jèhófà sọ fún un pé: “Fún ìdí yẹn, ẹnikẹ́ni tí ó bá pa Kéènì yóò jìyà ẹ̀san ní ìgbà méje.”+ Nítorí èyí, Jèhófà sì ṣe àmì kan nítorí Kéènì kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí i má bàa kọlù ú.+ 16  Pẹ̀lú èyí, Kéènì lọ kúrò ní ojú Jèhófà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ilẹ̀ Ìsáǹsá ní ìhà ìlà-oòrùn Édẹ́nì. 17  Lẹ́yìn ìgbà náà, Kéènì ní ìbádàpọ̀ pẹ̀lú aya rẹ̀,+ ó sì lóyún, ó sì bí Énọ́kù. Lẹ́yìn náà, ó dáwọ́ lé títẹ ìlú ńlá kan dó, ó sì fi orúkọ ọmọkùnrin rẹ̀ Énọ́kù+ pe ìlú ńlá náà. 18  Lẹ́yìn náà, a bí Írádì fún Énọ́kù. Írádì sì bí Mèhújáélì, Mèhújáélì sì bí Mètúṣáélì, Mètúṣáélì sì bí Lámékì. 19  Lámékì sì tẹ̀ síwájú láti mú aya méjì fún ara rẹ̀. Orúkọ èyí àkọ́kọ́ ni Ádà, orúkọ èyí èkejì sì ni Síláhì. 20  Nígbà tí ó ṣe, Ádà bí Jábálì. Ó jẹ́ olùpilẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí ń gbé inú àgọ́+ tí wọ́n sì ní ohun ọ̀sìn.+ 21  Orúkọ arákùnrin rẹ̀ sì ni Júbálì. Ó jẹ́ olùpilẹ̀ṣẹ̀ gbogbo àwọn tí ń lo háàpù+ àti fèrè ape.+ 22  Ní ti Síláhì, òun pẹ̀lú bí Tubali-kéénì, olùrọ gbogbo onírúurú irinṣẹ́ bàbà àti irin.+ Arábìnrin Tubali-kéénì sì ni Náámà. 23  Nítorí náà, Lámékì kó ọ̀rọ̀ wọ̀nyí jọ fún àwọn aya rẹ̀, Ádà àti Síláhì: “Ẹ gbọ́ ohùn mi, ẹ̀yin aya Lámékì; Ẹ fi etí sí àwọn àsọjáde mi: Ọkùnrin kan ni mo ti pa nítorí dídọ́gbẹ́ sí mi lára, Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀dọ́kùnrin kan nítorí gbígbá mi ní ẹ̀ṣẹ́. 24  Bí a óò bá gbẹ̀san+ Kéènì ní ìgbà méje. Nígbà náà, ti Lámékì yóò jẹ́ ní ìgbà àádọ́rin àti méje.” 25  Ádámù sì tún ń bá a lọ láti ní ìbádàpọ̀ pẹ̀lú aya rẹ̀, obìnrin náà sì tipa bẹ́ẹ̀ bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sẹ́ẹ̀tì,+ nítorí, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ: “Ọlọ́run ti fi irú-ọmọ mìíràn fún mi dípò Ébẹ́lì, nítorí pé Kéènì pa á.”+ 26  A sì bí ọmọkùnrin kan fún Sẹ́ẹ̀tì pẹ̀lú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ rẹ̀ ní Énọ́ṣì.+ Àkókò yẹn ni a bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé