Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 39:1-23

39  Ní ti Jósẹ́fù, a mú un sọ̀ kalẹ̀ wá sí Íjíbítì,+ Pọ́tífárì,+ olórí ẹ̀ṣọ́, òṣìṣẹ́ kan láàfin Fáráò, ará Íjíbítì, sì rà á lọ́wọ́ àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì+ tí ó mú un sọ̀ kalẹ̀ wá sí ibẹ̀.  Ṣùgbọ́n Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, tí ó fi jẹ́ pé ó di aláṣeyọrí sí rere,+ tí ó sì wá jẹ́ ẹni tí ń bójútó ilé ọ̀gá rẹ̀, ará Íjíbítì.  Ọ̀gá rẹ̀ sì rí i pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀ àti pé ohun gbogbo tí ó ń ṣe ni Jèhófà ń mú kí ó yọrí sí rere ní ọwọ́ rẹ̀.  Jósẹ́fù sì ń rí ojú rere ṣáá ní ojú rẹ̀, ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣèránṣẹ́ fún un, tí ó fi jẹ́ pé ó yàn án ṣe olórí ilé rẹ̀,+ gbogbo ohun tí ó sì jẹ́ tirẹ̀ ni ó fi lé e lọ́wọ́.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé láti ìgbà tí ó ti yàn án ṣe olórí ilé rẹ̀ àti sí àbójútó gbogbo ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ ni Jèhófà tí ń bù kún ilé ará Íjíbítì náà nítorí Jósẹ́fù, ìbùkún Jèhófà sì wá wà lórí gbogbo ohun tí ó ní ní ilé àti ní pápá.+  Níkẹyìn, ó fi ohun gbogbo tí ó jẹ́ tirẹ̀ sí ọwọ́ Jósẹ́fù;+ òun kò sì mọ ohun tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ rárá àyàfi oúnjẹ tí ó ń jẹ. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jósẹ́fù wá di ẹlẹ́wà ní wíwò àti ẹlẹ́wà ní ìrísí.  Wàyí o, lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ó ṣẹlẹ̀ pé aya ọ̀gá rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí gbé ojú rẹ̀ sókè+ lé Jósẹ́fù, ó sì ń wí pé: “Sùn tì mí.”+  Ṣùgbọ́n òun yóò kọ̀,+ yóò sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé: “Kíyè sí i, ọ̀gá mi kò mọ ohun tí ó wà pẹ̀lú mi nínú ilé, ohun gbogbo ni ó sì ti fi sí ọwọ́ mi.+  Kò sí ẹnì kankan tí ó tóbi jù mí lọ nínú ilé yìí, òun kò sì tíì fawọ́ ohunkóhun sẹ́yìn fún mi, bí kò ṣe ìwọ, nítorí pé aya rẹ̀ ni ọ́.+ Nítorí náà, báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?”+ 10  Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣẹlẹ̀ pé bí ó ti ń bá Jósẹ́fù sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́, òun kò fetí sílẹ̀ sí i láé láti sùn tì í, láti máa bá a lọ pẹ̀lú rẹ̀.+ 11  Ṣùgbọ́n ó ṣẹlẹ̀ pé ní ọjọ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ àtẹ̀yìnwá, ó lọ sínú ilé láti ṣe iṣẹ́ àmójútó rẹ̀, kò sì sí ìkankan nínú àwọn ènìyàn inú ilé ibẹ̀ ní ilé.+ 12  Nígbà náà ni ó dì í ní ẹ̀wù mú+ pé: “Sùn tì mí!”+ Ṣùgbọ́n òun fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí i lọ́wọ́, ó sì fẹsẹ̀ fẹ, ó sì bọ́ síta.+ 13  Nítorí náà, ó ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ó rí i pé ó ti fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, kí ó bàa lè sá síta, 14  ó bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde sí àwọn ènìyàn ilé rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! Ó mú ọkùnrin Hébérù kan wá bá wa láti sọ wá di ohun ìfirẹ́rìn-ín. Ó wá bá mi láti sùn tì mí, ṣùgbọ́n mo bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde bí ohùn mí ṣe lè ròkè tó.+ 15  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ó gbọ́ pé mo gbé ohùn mi sókè, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde, nígbà náà, ó fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ó sì fẹsẹ̀ fẹ, ó sì bọ́ síta.” 16  Lẹ́yìn ìyẹn, obìnrin náà tọ́jú ẹ̀wù rẹ̀ pa mọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ títí ọ̀gá rẹ̀ fi dé sí ilé rẹ̀.+ 17  Nígbà náà, ó bá a sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, pé: “Hébérù ìránṣẹ́ tí o mú wá fún wa, wá bá mi láti sọ mí di ohun ìfirẹ́rìn-ín. 18  Ṣùgbọ́n, ó ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí mo gbé ohùn mi sókè, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde, nígbà náà ni ó fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ó sì sá lọ síta.”+ 19  Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, gbàrà tí ọ̀gá rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ aya rẹ̀ tí ó sọ fún un, pé: “Báyìí-báyìí ni ìránṣẹ́ rẹ ṣe sí mi,” ìbínú rẹ̀ ru.+ 20  Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀gá Jósẹ́fù mú un, ó sì fi í sí ilé ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ń pa àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba mọ́ sí lábẹ́ ìfàṣẹ-ọba-múni, ó sì ń bá a lọ láti wà níbẹ̀ nínú ilé ẹ̀wọ̀n.+ 21  Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhófà ń bá a lọ láti wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ó sì ń nawọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí i ṣáá, ó sì ń yọ̀ǹda fún un láti rí ojú rere ní ojú ọ̀gá àgbà ní ilé ẹ̀wọ̀n.+ 22  Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀gá àgbà ní ilé ẹ̀wọ̀n náà fi gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n wà ní ilé ẹ̀wọ̀n lé Jósẹ́fù lọ́wọ́; gbogbo ohun tí wọ́n bá sì ń ṣe níbẹ̀, òun ni ń mú kí ó di ṣíṣe.+ 23  Ọ̀gá àgbà ní ilé ẹ̀wọ̀n náà kò bojú wo nǹkan kan tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ rárá, nítorí pé Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ohun tí ó sì ń ṣe ni Jèhófà ń mú kí ó yọrí sí rere.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé