Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́nẹ́sísì 37:1-36

37  Jékọ́bù sì ń bá a lọ láti gbé ní ilẹ̀ tí baba rẹ̀ ti ṣe àtìpó,+ ní ilẹ̀ Kénáánì.+  Èyí ni ọ̀rọ̀-ìtàn nípa Jékọ́bù. Ó ṣẹlẹ̀ pé, Jósẹ́fù,+ nígbà tí ó di ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún, ń ṣètọ́jú àgùntàn pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ láàárín agbo ẹran,+ àti pé, bí ó ti jẹ́ ọmọdékùnrin, ó wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Bílíhà+ àti àwọn ọmọ Sílípà,+ àwọn aya baba rẹ̀. Nítorí náà, Jósẹ́fù mú ìròyìn búburú nípa wọn wá fún baba wọn.+  Ísírẹ́lì sì nífẹ̀ẹ́ Jósẹ́fù ju gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ yòókù lọ,+ nítorí pé òun ni ọmọkùnrin ọjọ́ ogbó rẹ̀; ó sì ṣe ẹ̀wù gígùn, abilà tí ó dà bí ṣẹ́ẹ̀tì fún un.+  Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ wá rí i pé baba àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ju gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra rẹ̀,+ wọn kò sì lè bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà àlàáfíà.+  Lẹ́yìn náà, Jósẹ́fù lá àlá kan, ó sì rọ́ ọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀,+ wọ́n sì rí ìdí síwájú sí i láti kórìíra rẹ̀.  Ó sì ń bá a lọ láti sọ fún wọn pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fetí sí àlá tí mo lá yìí.+  Tóò, kíyè sí i, a ń di ìtí ní àárín pápá, nígbà tí ìtí tèmi dìde, ó sì dúró ṣánṣán, àwọn ìtí tiyín sì bẹ̀rẹ̀ sí pagbo yí ìtí mi ká, wọ́n sì ń tẹrí ba fún un.”+  Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún un pé: “Ìwọ yóò ha jọba lé wa lórí dájúdájú bí?+ tàbí, Ìwọ yóò ha jẹ gàba lé wa lórí dájúdájú bí?”+ Nítorí náà, wọ́n rí àkọ̀tun ìdí láti kórìíra rẹ̀ lórí àwọn àlá rẹ̀ àti lórí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀.  Lẹ́yìn ìyẹn, ó tún lá àlá mìíràn, ó sì rọ́ ọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Kíyè sí i, mo tún lá àlá lẹ́ẹ̀kan sí i, sì kíyè sí i, oòrùn àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ mọ́kànlá ń tẹrí ba fún mi.”+ 10  Lẹ́yìn náà, ó rọ́ ọ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ bákan náà, baba rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí lọ́nà mímúná,+ pé: “Kí ni àlá tí o lá yìí túmọ̀ sí? Èmi àti ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ pẹ̀lú yóò ha wá tẹrí ba mọ́lẹ̀ fún ọ dájúdájú bí?” 11  Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jowú rẹ̀,+ ṣùgbọ́n baba rẹ̀ pa àsọjáde náà mọ́.+ 12  Wàyí o, àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ bọ́ agbo ẹran baba wọn lẹ́bàá Ṣékémù.+ 13  Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, Ísírẹ́lì wí fún Jósẹ́fù pé: “Àwọn arákùnrin rẹ ń ṣètọ́jú agbo ẹran lẹ́bàá Ṣékémù, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Wá, sì jẹ́ kí n rán ọ sí wọn.” Látàrí èyí, ó sọ fún un pé: “Èmi nìyí!”+ 14  Nítorí náà, ó wí fún un pé: “Jọ̀wọ́, lọ. Wò ó, bóyá àwọn arákùnrin rẹ wà ní àlàáfíà, àti bóyá agbo ẹran náà wà ní àlàáfíà, kí o sì mú ọ̀rọ̀ padà tọ̀ mí wá.”+ Pẹ̀lú ìyẹn, ó rán an lọ láti ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ Hébúrónì,+ ó sì ń lọ síhà Ṣékémù. 15  Lẹ́yìn náà, ọkùnrin kan rí i, sì kíyè sí i, ó ń rìn gbéregbère nínú pápá. Ọkùnrin náà sì wádìí lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni o ń wá?” 16  Ó fèsì pé: “Àwọn arákùnrin mi ni mo ń wá. Jọ̀wọ́, sọ fún mi, Ibo ni wọn tí ń ṣètọ́jú agbo ẹran?” 17  Ọkùnrin náà sì ń bá a lọ pé: “Wọ́n ti ṣí kúrò níhìn-ín, nítorí pé mo gbọ́ tí wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ sí Dótánì.’” Nítorí náà, Jósẹ́fù ń bá a nìṣó láti tọpasẹ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì rí wọn ní Dótánì. 18  Tóò, wọ́n tajú kán rí i ní òkèèrè, kí ó sì tó sún mọ́ wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbìmọ̀ pọ̀ lọ́nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí sí i láti fi ikú pa á.+ 19  Nítorí náà, wọ́n wí fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Wò ó! Alálàá yẹn ní ń bọ̀ yìí.+ 20  Wàyí o, ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí a sì gbé e sọ sínú ọ̀kan nínú àwọn kòtò omi;+ àwa yóò sì sọ pé ẹranko ẹhànnà abèṣe ni ó pa á jẹ.+ Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí a rí ohun tí àwọn àlá rẹ̀ yóò dà.” 21  Nígbà tí Rúbẹ́nì gbọ́ èyí, ó gbìyànjú láti dá a nídè kúrò lọ́wọ́ wọn.+ Nítorí náà, ó wí pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a kọlu ọkàn rẹ̀ lọ́nà tí yóò yọrí sí ikú.”+ 22  Rúbẹ́nì sì ń bá a lọ láti sọ fún wọn pé: “Ẹ má ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+ Ẹ gbé e sọ sínú kòtò omi yìí, tí ó wà nínú aginjù, kí ẹ má sì gbé ọwọ́ líle nípá lé e.”+ Ète rẹ̀ ni láti dá a nídè kúrò ní ọwọ́ wọn, kí ó bàa lè dá a padà sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀. 23  Nítorí náà, ó ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí Jósẹ́fù dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ ẹ̀wù gígùn Jósẹ́fù kúrò lára rẹ̀, àní ẹ̀wù gígùn abilà tí ó wà lára rẹ̀;+ 24  lẹ́yìn èyí, wọ́n mú un, wọ́n sì gbé e sọ sínú kòtò omi.+ Kòtò náà ṣófo nígbà yẹn; kò sí omi nínú rẹ̀. 25  Lẹ́yìn náà, wọ́n jókòó láti jẹ oúnjẹ.+ Nígbà tí wọ́n gbé ojú wọn sókè tí wọ́n sì wò, họ́wù, ọ̀wọ́ èrò àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì+ rèé tí ń bọ̀ láti Gílíádì, ràkúnmí wọn sì ru gọ́ọ̀mù lábídánúmù àti básámù àti èèpo-igi olóje,+ wọ́n wà ní ojú ọ̀nà wọn láti gbé e lọ sí Íjíbítì. 26  Látàrí èyí, Júdà sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Èrè kí ni yóò jẹ́, bí a bá pa arákùnrin wa, tí a sì bo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀?+ 27  Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tà á fún àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì,+ ẹ má sì jẹ́ kí ọwọ́ wa wà lára rẹ̀.+ Ó ṣe tán, arákùnrin wa ni, ẹran ara wa.” Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n fetí sí arákùnrin wọn.+ 28  Wàyí o, àwọn ọkùnrin, àwọn ọmọ Mídíánì olówò+ ń kọjá lọ. Nítorí náà, wọ́n fa Jósẹ́fù, wọ́n sì gbé e jáde láti inú kòtò omi,+ wọ́n sì ta Jósẹ́fù fún àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì, ní ogún ẹyọ owó fàdákà.+ Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn wọ̀nyí mú Jósẹ́fù wá sí Íjíbítì. 29  Lẹ́yìn náà, Rúbẹ́nì padà sí ibi kòtò omi náà, sì kíyè sí i, Jósẹ́fù kò sí nínú kòtò omi náà. Nítorí náà, ó gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya.+ 30  Nígbà tí ó padà sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ yòókù, ó figbe ta pé: “Ọmọ náà ti lọ! Èmi—ibo gan-an ni èmi yóò lọ?”+ 31  Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n mú ẹ̀wù gígùn Jósẹ́fù, wọ́n sì pa akọ ewúrẹ́, wọ́n sì ti ẹ̀wù gígùn náà bọ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ léraléra.+ 32  Lẹ́yìn náà, wọ́n fi ẹ̀wù gígùn abilà náà ránṣẹ́, wọ́n sì mú un wá fún baba wọn, wọ́n sì wí pé: “Èyí ni ohun tí a rí. Jọ̀wọ́, yẹ̀ ẹ́ wò,+ bóyá ẹ̀wù gígùn ọmọkùnrin rẹ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.”+ 33  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí yẹ̀ ẹ́ wò, ó sì figbe ta pé: “Ẹ̀wù gígùn ọmọkùnrin mi ni! Ẹranko ẹhànnà abèṣe ti ní láti pa á jẹ!+ Dájúdájú, Jósẹ́fù ni a ti fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ!”+ 34  Pẹ̀lú ìyẹn, Jékọ́bù gbọn aṣọ àlàbora rẹ̀ ya, ó sì sán aṣọ àpò ìdọ̀họ mọ́ ìgbáròkó rẹ̀, ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣọ̀fọ̀ ọmọkùnrin rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́.+ 35  Gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ sì ń dìde láti tù ú nínú,+ ṣùgbọ́n ó ń kọ̀ láti gba ìtùnú, ó wí pé:+ “Nítorí èmi yóò máa bá a lọ láti ṣọ̀fọ̀ ọmọkùnrin mi wọnú Ṣìọ́ọ̀lù!” Baba rẹ̀ sì ń bá a lọ láti sunkún nítorí rẹ̀. 36  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ Mídíánì tà á sí Íjíbítì, fún Pọ́tífárì, olórí ẹ̀ṣọ́,+ òṣìṣẹ́ kan láàfin Fáráò.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé