Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 36:1-43

36  Èyí sì ni ọ̀rọ̀-ìtàn nípa Ísọ̀, èyíinì ni Édómù.+  Ísọ̀ fẹ́ àwọn aya rẹ̀ láti inú àwọn ọmọbìnrin Kénáánì:+ Ádà+ ọmọbìnrin Élónì ọmọ Hétì+ àti Oholibámà+ ọmọbìnrin Ánáhì, ọmọbìnrin ọmọ Síbéónì tí í ṣe Hífì,  àti Básémátì,+ ọmọbìnrin Íṣímáẹ́lì, arábìnrin Nébáótì.+  Ádà sì bí Élífásì fún Ísọ̀, Básémátì sì bí Réúẹ́lì,  Oholibámà sì bí Jéúṣì àti Jálámù àti Kórà.+ Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Ísọ̀ tí a bí fún un ní ilẹ̀ Kénáánì.  Lẹ́yìn ìyẹn, Ísọ̀ kó àwọn aya rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo ọkàn tí ó jẹ́ ti ilé rẹ̀ àti ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀ àti gbogbo àwọn ẹranko rẹ̀ yòókù àti gbogbo ọlà rẹ̀,+ tí ó ti kó jọ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ Kénáánì, ó sì lọ sí ilẹ̀ kan tí ó jìnnà sí arákùnrin rẹ̀ Jékọ́bù,+  nítorí pé ẹrù wọ́n ti wá di èyí tí ó pọ̀ gan-an fún wọn láti máa gbé pa pọ̀, ilẹ̀ tí wọ́n ti ṣe àtìpó kò sì lè pèsè ohun ìgbẹ́mìíró fún wọn nítorí àwọn ọ̀wọ́ ẹran wọn.+  Nítorí náà, Ísọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Séírì.+ Ísọ̀ ni Édómù.+  Èyí sì ni ọ̀rọ̀-ìtàn nípa Ísọ̀, baba Édómù ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Séírì.+ 10  Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísọ̀: Élífásì ọmọkùnrin Ádà, aya Ísọ̀; Réúẹ́lì ọmọkùnrin Básémátì, aya Ísọ̀.+ 11  Àwọn ọmọkùnrin Élífásì sì ni Témánì,+ Ómárì, Séfò àti Gátámù àti Kénásì.+ 12  Tímínà+ sì di wáhàrì Élífásì, ọmọkùnrin Ísọ̀. Nígbà tí ó ṣe, ó bí Ámálékì+ fún Élífásì. Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Ádà, aya Ísọ̀. 13  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Réúẹ́lì: Náhátì àti Síírà, Sámáhì àti Mísà.+ Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Básémátì,+ aya Ísọ̀. 14  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọkùnrin Oholibámà ọmọbìnrin Ánáhì, ọmọbìnrin ọmọ Síbéónì, aya Ísọ̀, ní ti pé ó bí Jéúṣì àti Jálámù àti Kórà+ fún Ísọ̀. 15  Ìwọ̀nyí ni àwọn séríkí+ nínú àwọn ọmọ Ísọ̀: Àwọn ọmọkùnrin Élífásì, àkọ́bí Ísọ̀: Témánì+ séríkí, Ómárì séríkí, Séfò séríkí, Kénásì séríkí, 16  Kórà séríkí, Gátámù séríkí, Ámálékì séríkí. Ìwọ̀nyí ni àwọn séríkí ti Élífásì+ ní ilẹ̀ Édómù. Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Ádà bí. 17  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Réúẹ́lì, ọmọkùnrin Ísọ̀: Náhátì séríkí, Síírà séríkí, Sámáhì séríkí, Mísà séríkí. Ìwọ̀nyí ni àwọn séríkí ti Réúẹ́lì ní ilẹ̀ Édómù.+ Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Básémátì, aya Ísọ̀ bí. 18  Níkẹyìn, ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Oholibámà, aya Ísọ̀: Jéúṣì séríkí, Jálámù séríkí, Kórà séríkí. Ìwọ̀nyí ni àwọn séríkí ti Oholibámà ọmọbìnrin Ánáhì, aya Ísọ̀. 19  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Ísọ̀, ìwọ̀nyí sì ni àwọn séríkí wọn. Òun ni Édómù.+ 20  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Séírì tí í ṣe Hórì, àwọn olùgbé ilẹ̀ náà:+ Lótánì àti Ṣóbálì àti Síbéónì àti Ánáhì+ 21  àti Díṣónì àti Ésérì àti Díṣánì.+ Ìwọ̀nyí ni àwọn séríkí àwọn Hórì, àwọn ọmọkùnrin Séírì, ní ilẹ̀ Édómù. 22  Àwọn ọmọkùnrin Lótánì ni Hórì àti Hémámù; arábìnrin Lótánì sì ni Tímínà.+ 23  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọkùnrin Ṣóbálì: Álífánì àti Manáhátì àti Ébálì, Ṣẹ́fò àti Ónámù. 24  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọkùnrin Síbéónì: Áyà àti Ánáhì. Èyí ni Ánáhì tí ó rí àwọn ìsun gbígbóná nínú aginjù nígbà tí ó ń ṣètọ́jú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ fún Síbéónì baba rẹ̀.+ 25  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Ánáhì: Díṣónì àti Oholibámà ọmọbìnrin Ánáhì. 26  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọkùnrin Díṣónì: Hémúdánì àti Éṣíbánì àti Ítíránì àti Kéránì.+ 27  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọkùnrin Ésérì: Bílíhánì àti Sááfánì àti Ákánì. 28  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Díṣánì: Úsì àti Áránì.+ 29  Ìwọ̀nyí ni séríkí àwọn Hórì: Lótánì séríkí, Ṣóbálì séríkí, Síbéónì séríkí, Ánáhì séríkí, 30  Díṣónì séríkí, Ésérì séríkí, Díṣánì+ séríkí. Ìwọ̀nyí ni àwọn séríkí àwọn Hórì ní ìbámu pẹ̀lú àwọn séríkí wọn ní ilẹ̀ Séírì. 31  Wàyí o, ìwọ̀nyí ni àwọn ọba tí ó jẹ ní ilẹ̀ Édómù+ kí ọba èyíkéyìí tó jẹ lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 32  Bélà ọmọkùnrin Béórì sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní Édómù,+ orúkọ ìlú ńlá rẹ̀ sì ni Dínhábà. 33  Nígbà tí Bélà kú, Jóbábù ọmọkùnrin Síírà láti Bósírà+ bẹ̀rẹ̀ sí jọba dípò rẹ̀.+ 34  Nígbà tí Jóbábù kú, Húṣámù láti ilẹ̀ àwọn ará Témánì+ bẹ̀rẹ̀ sí jọba dípò rẹ̀.+ 35  Nígbà tí Húṣámù kú, Hádádì ọmọkùnrin Bédádì, ẹni tí ó ṣẹ́gun àwọn ọmọ Mídíánì+ ní pápá Móábù,+ bẹ̀rẹ̀ sí jọba dípò rẹ̀, orúkọ ìlú ńlá rẹ̀ sì ni Áfítì.+ 36  Nígbà tí Hádádì kú, Sámúlà láti Másírékà bẹ̀rẹ̀ sí jọba dípò rẹ̀.+ 37  Nígbà tí Sámúlà kú, Ṣọ́ọ̀lù láti Réhóbótì lẹ́bàá Odò bẹ̀rẹ̀ sí jọba dípò rẹ̀.+ 38  Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù kú, Baali-hánánì ọmọkùnrin Ákíbórì bẹ̀rẹ̀ sí jọba dípò rẹ̀.+ 39  Nígbà tí Baali-hánánì ọmọkùnrin Ákíbórì kú, Hádárì bẹ̀rẹ̀ sí jọba dípò rẹ̀; orúkọ ìlú ńlá rẹ̀ sì ni Páù, orúkọ aya rẹ̀ sì ni Méhétábélì ọmọbìnrin Mátírédì ọmọbìnrin Mésáhábù.+ 40  Nítorí náà, ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn séríkí ti Ísọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn, gẹ́gẹ́ bí ipò wọn, nípa orúkọ wọn: Tímínà séríkí, Álíífà séríkí, Jététì+ séríkí, 41  Oholibámà séríkí, Éláhì séríkí, Pínónì+ séríkí, 42  Kénásì séríkí, Témánì séríkí, Míbúsárì+ séríkí, 43  Mágídíélì séríkí, Írámù séríkí. Ìwọ̀nyí ni àwọn séríkí Édómù+ gẹ́gẹ́ bí ibùgbé wọn ní ilẹ̀ ìní+ wọn. Èyí ni Ísọ̀, baba Édómù.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé