Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́nẹ́sísì 35:1-29

35  Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ fún Jékọ́bù pé: “Dìde, gòkè lọ sí Bẹ́tẹ́lì, kí o sì máa gbé níbẹ̀,+ kí o sì ṣe pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Ọlọ́run tòótọ́ tí ó fara hàn ọ́ nígbà tí ìwọ fẹsẹ̀ fẹ kúrò lọ́dọ̀ Ísọ̀ arákùnrin rẹ.”+  Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù sọ fún agbo ilé rẹ̀ àti fún gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Ẹ mú àwọn ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè tí ó wà ní àárín yín kúrò,+ kí ẹ sì wẹ ara yín mọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ àlàbora yín,+  ẹ sì jẹ́ kí a dìde, kí a sì gòkè lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Ibẹ̀ ni èmi yóò sì ti ṣe pẹpẹ kan fún Ọlọ́run tòótọ́ tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ wàhálà mi,+ ní ti pé ó wà pẹ̀lú mi ní ọ̀nà tí mo ti lọ.”+  Nítorí náà, wọ́n kó gbogbo àwọn ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè+ tí ó wà ní ọwọ́ wọn àti àwọn yẹtí tí ó wà ní etí wọn fún Jékọ́bù, Jékọ́bù sì fi wọ́n pa mọ́+ sábẹ́ igi ńlá tí ó wà nítòsí Ṣékémù.  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ṣí kúrò, ìpayà Ọlọ́run sì wá wà lórí àwọn ìlú ńlá tí ó yí wọn ká,+ tí ó fi jẹ́ pé wọn kò lépa àwọn ọmọ Jékọ́bù.  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Jékọ́bù dé Lúsì,+ tí ó wà ní ilẹ̀ Kénáánì, èyíinì ni Bẹ́tẹ́lì, òun àti gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀.  Lẹ́yìn náà, ó mọ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pe ibẹ̀ ní Eli-bẹ́tẹ́lì, nítorí pé ibẹ̀ ni Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣí ara rẹ̀ payá fún un ní àkókò ìfẹsẹ̀fẹ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ arákùnrin rẹ̀.+  Lẹ́yìn náà, Dèbórà,+ obìnrin tí ń ṣètọ́jú Rèbékà kú, a sì sin ín sí ìsàlẹ̀ Bẹ́tẹ́lì, lábẹ́ igi ràgàjì kan. Nítorí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Aloni-bákútì.  Wàyí o, Ọlọ́run fara han Jékọ́bù lẹ́ẹ̀kan sí i, nígbà tí ó ń bọ̀ láti Padani-árámù,+ ó sì súre fún un.+ 10  Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí fún un pé: “Jékọ́bù+ ni orúkọ rẹ. A kì yóò tún pe orúkọ rẹ ní Jékọ́bù mọ́, ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì ni orúkọ rẹ yóò dà.” Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.+ 11  Ọlọ́run sì wí fún un síwájú sí i pé: “Èmi ni Ọlọ́run Olódùmarè.+ Máa so èso, kí o sì di púpọ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè àti ìjọ àwọn orílẹ̀-èdè yóò ti inú rẹ jáde, àwọn ọba yóò sì jáde wá láti abẹ́nú rẹ.+ 12  Ní ti ilẹ̀ tí mo ti fi fún Ábúráhámù àti fún Ísákì, ìwọ ni èmi yóò fi í fún, irú-ọmọ rẹ+ lẹ́yìn rẹ ni èmi yóò sì fi ilẹ̀ náà fún.”+ 13  Lẹ́yìn ìyẹn, Ọlọ́run gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ibi tí ó ti bá a sọ̀rọ̀.+ 14  Nítorí náà, Jékọ́bù gbé ọwọ̀n kan dúró ní ibi tí ó ti bá a sọ̀rọ̀,+ ọwọ̀n òkúta, ó sì da ọrẹ ẹbọ ohun mímu sórí rẹ̀, ó sì da òróró sórí rẹ̀.+ 15  Jékọ́bù sì ń bá a lọ láti pe orúkọ ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì.+ 16  Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ní Bẹ́tẹ́lì. Nígbà tí ilẹ̀ tí ó lọ salalu ṣì wà kí wọ́n tó dé Éfúrátì,+ Rákélì sì bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, ìbímọ náà sì ń nira fún un.+ 17  Ṣùgbọ́n, ó ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ó ní ìṣòro ìbímọ, agbẹ̀bí wí fún un pé: “Má fòyà, nítorí ìwọ yóò bí ọmọkùnrin yìí pẹ̀lú.”+ 18  Ìyọrísí rẹ̀ sì ni pé bí ọkàn+ rẹ̀ ti ń jáde lọ (nítorí pé ó kú)+ ó pe orúkọ rẹ̀ ní Bẹni-ónì; ṣùgbọ́n baba rẹ̀ pè é ní Bẹ́ńjámínì.+ 19  Nípa báyìí, Rákélì kú, a sì sin ín lójú ọ̀nà sí Éfúrátì, èyíinì ni, Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.+ 20  Nítorí náà, Jékọ́bù gbé ọwọ̀n kan dúró sórí sàréè rẹ̀. Èyí ni ọwọ̀n sàréè Rákélì títí di òní yìí.+ 21  Lẹ́yìn ìyẹn, Ísírẹ́lì ṣí kúrò, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ sí ibi kan tí ó jìnnà ré kọjá ilé gogoro Édérì.+ 22  Ó sì wá ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí Ísírẹ́lì pàgọ́+ sí ilẹ̀ yẹn, Rúbẹ́nì lọ sùn ti Bílíhà wáhàrì baba rẹ̀, Ísírẹ́lì sì gbọ́ nípa rẹ̀.+ Àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù sì wá jẹ́ méjìlá. 23  Àwọn ọmọkùnrin tí Léà bí ni Rúbẹ́nì,+ àkọ́bí Jékọ́bù àti Síméónì àti Léfì àti Júdà àti Ísákárì àti Sébúlúnì. 24  Àwọn ọmọkùnrin tí Rákélì bí ni Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì. 25  Àwọn ọmọkùnrin tí Bílíhà, ìránṣẹ́bìnrin Rákélì sì bí, ni Dánì àti Náfútálì. 26  Àwọn ọmọkùnrin tí Sílípà, ìránṣẹ́bìnrin Léà sì bí, ni Gádì àti Áṣérì. Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù tí a bí fún un ní Padani-árámù. 27  Níkẹyìn, Jékọ́bù dé ọ̀dọ̀ Ísákì baba rẹ̀ ní Mámúrè,+ ní Kiriati-ábà,+ èyíinì ni, Hébúrónì, níbi tí Ábúráhámù àti Ísákì pẹ̀lú ti ṣe àtìpó.+ 28  Ọjọ́ ayé Ísákì sì jẹ́ ọgọ́sàn-án ọdún.+ 29  Lẹ́yìn ìyẹn, Ísákì gbẹ́mìí mì, ó sì kú, a sì kó o jọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀, ó darúgbó, ó sì kún tẹ́rùn-tẹ́rùn fún ọjọ́,+ Ísọ̀ àti Jékọ́bù, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, sì sin ín.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé