Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 34:1-31

34   Wàyí o, Dínà ọmọbìnrin Léà,+ tí ó bí fún Jékọ́bù, sábà máa ń jáde lọ rí+ àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ náà.+  Ṣékémù, ọmọkùnrin Hámórì, tí í ṣe Hífì,+ ìjòyè kan ní ilẹ̀ náà sì rí i, lẹ́yìn náà, ó mú un, ó sùn tì í, ó sì tẹ́ ẹ lógo.+  Ọkàn rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ mọ́ Dínà ọmọbìnrin Jékọ́bù, ó sì kó sínú ìfẹ́ fún ọ̀dọ́bìnrin náà, ó sì ń bá ọ̀dọ́bìnrin náà sọ̀rọ̀ ṣáá lọ́nà tí ń yíni lérò padà.  Níkẹyìn, Ṣékémù sọ fún Hámórì baba rẹ̀+ pé: “Fẹ́ ọmọge yìí fún mi, kí n fi ṣe aya.”+  Jékọ́bù sì gbọ́ pé ó ti sọ Dínà ọmọbìnrin rẹ̀ di ẹlẹ́gbin. Ó sì ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wà pẹ̀lú ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀ nínú pápá;+ Jékọ́bù sì dákẹ́ títí di ìgbà tí wọn yóò dé.+  Lẹ́yìn náà, Hámórì, baba Ṣékémù, jáde lọ bá Jékọ́bù láti bá a sọ̀rọ̀.+  Àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù sì dé láti inú pápá ní gbàrà tí wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀; inú àwọn ọkùnrin náà sì bàjẹ́, inú sì bí wọn gidigidi,+ nítorí pé ó ti hu ìwà ẹ̀gọ̀ tí ń dójú tini sí Ísírẹ́lì, ní sísùn ti ọmọbìnrin Jékọ́bù,+ nígbà tí ó jẹ́ pé kò yẹ kí a ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀.+  Hámórì sì bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn sọ̀rọ̀, pé: “Ní ti Ṣékémù ọmọkùnrin mi, ọkàn rẹ̀ fà mọ́ ọmọbìnrin yín.+ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi fún un, kí ó fi ṣe aya,+  kí ẹ sì bá wa dána.+ Àwọn ọmọbìnrin yín ni kí ẹ fi fún wa, àwọn ọmọbìnrin wa ni kí ẹ sì mú fún ara yín.+ 10  Kí ẹ sì máa bá wa gbé, ilẹ̀ yìí yóò sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó yín. Ẹ máa gbé, kí ẹ sì máa ṣòwò nìṣó nínú rẹ̀, kí ẹ sì tẹ̀ dó sínú rẹ̀.”+ 11  Lẹ́yìn náà, Ṣékémù sọ fún baba ọmọbìnrin náà àti fún àwọn arákùnrin ọmọbìnrin náà pé: “Ẹ jẹ́ kí n rí ojú rere ní ojú yín, ohun yòówù tí ẹ bá sì sọ fún mi, èmi yóò san án. 12  Ẹ gbé owó ìgbéyàwó àti ẹ̀bùn tí a gbé kà mí lórí ga sókè gidigidi,+ mo sì múra tán láti fún yín ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ẹ ó sọ fún mi; kìkì pé kí ẹ fún mi ní ọ̀dọ́bìnrin náà, kí n fi ṣe aya.” 13  Àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀tàn dá Ṣékémù àti Hámórì baba rẹ̀ lóhùn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nítorí pé ó ti sọ Dínà arábìnrin wọn di ẹlẹ́gbin.+ 14  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún wọn pé: “Kò ṣeé ṣe fún wa láti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, láti fi arábìnrin wa fún ọkùnrin tí ó ní adọ̀dọ́,+ nítorí pé ìyẹn jẹ́ ẹ̀gàn fún wa. 15  Kìkì lábẹ́ ohun tí a fi lélẹ̀ yìí ni àwa lè gbà fún yín, pé kí ẹ̀yin dà bí àwa, nípa mímú kí olúkúlùkù ọkùnrin yín dá adọ̀dọ́.+ 16  Nígbà náà, àwọn ọmọbìnrin wa ni àwa yóò fi fún yín, àwọn ọmọbìnrin yín ni àwa yóò sì fẹ́ fún ara wa, dájúdájú, àwa yóò máa bá yín gbé, a óò sì di ènìyàn kan.+ 17  Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetí sí wa, kí ẹ sì dá adọ̀dọ́, nígbà náà, àwa yóò mú ọmọbìnrin wa, àwa yóò sì lọ.” 18  Ọ̀rọ̀ wọn sì jọ pé ó dára ní ojú Hámórì àti ní ojú Ṣékémù, ọmọkùnrin Hámórì,+ 19  ọ̀dọ́kùnrin náà kò sì jáfara láti ṣe ohun tí a fi lélẹ̀,+ nítorí pé ó ní inúdídùn sí ọmọbìnrin Jékọ́bù, ọ̀dọ́kùnrin náà sì ni ó ní ọlá jù lọ+ nínú gbogbo ilé baba rẹ̀.+ 20  Nítorí náà, Hámórì àti Ṣékémù ọmọkùnrin rẹ̀ lọ sí ẹnubodè ìlú ńlá wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọkùnrin ìlú ńlá wọn sọ̀rọ̀,+ pé: 21  “Olùfẹ́ àlàáfíà ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyí jẹ́ sí wa.+ Nítorì náà, ẹ jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ yìí, kí wọ́n sì máa ṣòwò nìṣó nínú rẹ̀, bí ó ti jẹ́ pé ilẹ̀ náà gbòòrò gidigidi níwájú wọn.+ Àwọn ọmọbìnrin wọn ni a lè fẹ́ ṣe aya fún ara wa, àwọn ọmọbìnrin wa ni a sì lè fi fún wọn.+ 22  Kìkì lábẹ́ ohun tí a fi lélẹ̀ yìí ni àwọn ọkùnrin yìí yóò fi gbà láti bá wa gbé, kí a lè di ènìyàn kan, pé kí olúkúlùkù ọkùnrin wa dá adọ̀dọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti dá adọ̀dọ́.+ 23  Nígbà náà, ohun ìní wọn àti ọlà wọn àti gbogbo ohun ọ̀sìn wọn, wọn kì yóò ha jẹ́ tiwa?+ Kìkì kí ẹ jẹ́ kí a gbà fún wọn pé kí wọ́n máa bá wa gbé.”+ 24  Nígbà náà, gbogbo àwọn tí ń jáde lọ láti ẹnubodè ìlú ńlá rẹ̀ fetí sí Hámórì àti sí Ṣékémù ọmọkùnrin rẹ̀, gbogbo àwọn ọkùnrin sì dá adọ̀dọ́, gbogbo àwọn tí ń jáde lọ láti ẹnubodè ìlú ńlá rẹ̀. 25  Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣẹlẹ̀ pé ní ọjọ́ kẹta, tí ara wọ́n gbẹ̀kan,+ àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù méjì, Síméónì àti Léfì,+ àwọn arákùnrin Dínà,+ olúkúlùkù wọn bẹ̀rẹ̀ sí mú idà rẹ̀, wọ́n sì yọ́ lọ sí ìlú ńlá náà, wọ́n sì pa olúkúlùkù ọkùnrin.+ 26  Hámórì àti Ṣékémù ọmọkùnrin rẹ̀ ni wọ́n sì fi ojú idà pa.+ Lẹ́yìn náà, wọ́n mú Dínà kúrò ní ilé Ṣékémù, wọ́n sì jáde lọ.+ 27  Ìyókù àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù gbéjà ko àwọn ọkùnrin tí ó gbọgbẹ́ lọ́nà tí ó lè yọrí sí ikú, wọ́n sì piyẹ́ ìlú ńlá náà, nítorí pé wọ́n sọ arábìnrin wọn di ẹlẹ́gbin.+ 28  Agbo ẹran wọn àti ọ̀wọ́ ẹran wọn àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn àti ohun tí ó wà nínú ìlú ńlá náà àti ohun tí ó wà nínú pápá ni wọ́n kó.+ 29  Gbogbo àlùmọ́ọ́nì ìgbọ́bùkátà wọn àti gbogbo àwọn ọmọ wọn kéékèèké, àti àwọn aya wọn ni wọ́n sì kó lọ ní òǹdè, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n piyẹ́ gbogbo àwọn ohun tí ó wà nínú àwọn ilé náà.+ 30  Látàrí èyí, Jékọ́bù wí fún Síméónì àti fún Léfì+ pé: “Ẹ ti mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá sórí mi ní sísọ mí di òórùn burúkú lójú àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí,+ pẹ̀lú àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn Pérísì; nígbà tí ó sì jẹ́ pé èmi kéré níye,+ dájúdájú, wọn yóò kóra jọpọ̀ lòdì sí mi, wọn yóò sì fipá kọlù mí, a ó sì pa mí rẹ́ ráúráú, èmi àti ilé mi.” 31  Ẹ̀wẹ̀, wọ́n sọ pé: “Ṣé ó yẹ kí ẹnikẹ́ni hùwà sí arábìnrin wa bí ẹni pé kárùwà ni?”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé