Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 30:1-43

30  Nígbà tí Rákélì wá rí i pé òun kò tíì bí ọmọ kankan fún Jékọ́bù, Rákélì bẹ̀rẹ̀ sí jowú arábìnrin rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún Jékọ́bù+ pé: “Fún mi ní àwọn ọmọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò di òkú.”+  Látàrí èyí, ìbínú Jékọ́bù ru sí Rákélì, ó sì wí pé:+ “Èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run, ẹni tí ó fawọ́ èso ikùn sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ?”+  Nítorí náà, ó wí pé: “Bílíhà+ ẹrúbìnrin mi rèé. Ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kí ó lè bímọ lórí eékún mi àti pé kí èmi, àní èmi, lè ní àwọn ọmọ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.”+  Pẹ̀lú ìyẹn, ó fi Bílíhà ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí aya, Jékọ́bù sì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.+  Bílíhà sì lóyún, nígbà tí ó sì ṣe, ó bí ọmọkùnrin+ kan fún Jékọ́bù.  Nígbà náà ni Rákélì wí pé: “Ọlọ́run ti ṣe bí onídàájọ́+ fún mi, ó sì tún ti fetí sí ohùn mi, tí ó fi jẹ́ pé ó fi ọmọkùnrin kan fún mi.” Ìdí nìyẹn tí ó fi pe orúkọ rẹ̀ ní Dánì.+  Bílíhà, ìránṣẹ́bìnrin Rákélì, sì lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, nígbà tí ó sì ṣe, ó bí ọmọkùnrin kejì fún Jékọ́bù.  Nígbà náà ni Rákélì wí pé: “Gídígbò tí a jà ní àjàkú-akátá ni mo bá arábìnrin mi jà. Mo sì ti mókè!” Nítorí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Náfútálì.+  Nígbà tí Léà wá rí i pé òun ti dẹ́kun bíbímọ, ó tẹ̀ síwájú láti mú Sílípà ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀, ó sì fi í fún Jékọ́bù láti fi ṣe aya.+ 10  Nígbà tí ó ṣe, Sílípà, ìránṣẹ́bìnrin Léà, bí ọmọkùnrin kan fún Jékọ́bù. 11  Nígbà náà ni Léà wí pé: “Pẹ̀lú ire!” Nítorí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Gádì.+ 12  Lẹ́yìn ìyẹn, Sílípà, ìránṣẹ́bìnrin Léà, bí ọmọkùnrin kejì fún Jékọ́bù. 13  Nígbá náà ni Léà sọ pé: “Ayọ̀ mi kún! Nítorí dájúdájú àwọn ọmọbìnrin yóò pè mí ní aláyọ̀.”+ Nítorí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Áṣérì.+ 14  Wàyí o, Rúbẹ́nì+ ń rìn ní ọjọ́ ìkórè+ àlìkámà, ó sì wá rí àwọn máńdírékì nínú pápá. Nítorí náà, ó mú wọn wá fún Léà ìyá rẹ̀. Nígbà náà ni Rákélì wí fún Léà pé: “Jọ̀wọ́, fún mi ní díẹ̀ lára àwọn máńdírékì+ ọmọkùnrin rẹ.” 15  Látàrí èyí, ó wí fún un pé: “Ohun kékeré ha nìyí, lẹ́yìn tí ìwọ ti gba ọkọ mi,+ o tún fẹ́ gba àwọn máńdírékì ọmọkùnrin mi pẹ̀lú?” Nítorí náà, Rákélì wí pé: “Nítorí ìdí yẹn, òun yóò sùn tì ọ́ ní òru òní ní pàṣípààrọ̀ fún àwọn máńdírékì ọmọkùnrin rẹ.” 16  Nígbà tí Jékọ́bù ń bọ̀ láti inú pápá ní ìrọ̀lẹ́,+ Léà jáde lọ pàdé rẹ̀, ó sì wí pé: “Èmi ni ìwọ yóò bá ní ìbálòpọ̀, nítorí pé mo ti fi àwọn máńdírékì ọmọkùnrin mi háyà rẹ pátápátá.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó sùn tì í ní òru+ yẹn. 17  Ọlọ́run sì gbọ́, ó sì dá Léà lóhùn, ó sì lóyún, nígbà tí ó sì ṣe, ó bí ọmọkùnrin+ karùn-ún fún Jékọ́bù. 18  Nígbà náà, Léà wí pé: “Ọlọ́run ti san owó ọ̀yà fún mi, nítorí tí mo ti fi ìránṣẹ́bìnrin mi fún ọkọ mi.” Nítorí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ísákárì.+ 19  Léà sì lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, nígbà tí ó sì ṣe, ó bí ọmọkùnrin kẹfà fún Jékọ́bù.+ 20  Nígbà náà ni Léà wí pé: “Ọlọ́run ti bùn mí, àní èmi, ní ẹ̀bùn tí ó dára. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ọkọ mi yóò fi àyè gbà mí,+ nítorí pé mo ti bí ọmọkùnrin+ mẹ́fà fún un.” Nítorí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Sébúlúnì.+ 21  Lẹ́yìn ìgbà náà, ó bí ọmọbìnrin kan, ó sì wá pe orúkọ rẹ̀ ní Dínà.+ 22  Níkẹyìn Ọlọ́run rántí Rákélì, Ọlọ́run sì gbọ́, ó sì dá a lóhùn, ní ti pé ó ṣí ilé ọlẹ̀+ rẹ̀. 23  Ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Nígbà náà ni ó wí pé: “Ọlọ́run ti mú ẹ̀gàn+ mi kúrò!” 24  Nítorí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Jósẹ́fù,+ ó wí pé: “Jèhófà fi ọmọkùnrin mìíràn kún un fún mi.” 25  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Rákélì bí Jósẹ́fù, Jékọ́bù sọ fún Lábánì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé: “Rán mi lọ, kí n lè lọ sí àyè mi àti sí ilẹ̀+ mi. 26  Fi àwọn aya mi àti àwọn ọmọ mi, àwọn tí mo tìtorí wọn sìn ọ́, lé mi lọ́wọ́, kí n lè lọ; nítorí ó yẹ kí ìwọ fúnra rẹ mọ iṣẹ́ ìsìn tí mo ti ṣe fún ọ.”+ 27  Nígbà náà ni Lábánì wí fún un pé: “Wàyí o, bí mo bá ti rí ojú rere ní ojú rẹ,—mo ti lóye àmì ìṣẹ̀lẹ̀ náà sí pé Jèhófà ń bù kún mi nítorí rẹ.”+ 28  Ó sì fi kún un pé: “Ṣe àdéhùn pàtó ní ti owó ọ̀yà rẹ fún mi, èmi yóò sì san wọ́n.”+ 29  Nítorí náà, ó wí fún un pé: “Ìwọ fúnra rẹ mọ bí mo ṣe sìn ọ́ àti bi ọ̀wọ́ àwọn ẹran rẹ ti ṣe sí lọ́dọ̀ mi;+ 30  pé díẹ̀ ni o ní ní ti gidi ṣáájú dídé mi, ó sì ń gbòòrò di ògìdìgbó, ní ti pé Jèhófà bù kún ọ láti ìgbà tí mo ti dé.+ Ǹjẹ́ nísinsìnyí, ìgbà wo ni èmi yóò ṣe ohun kan fún ilé+ tèmi pẹ̀lú?” 31  Nígbà náà ni ó wí pé: “Kí ni kí n fún ọ?” Jékọ́bù sì ń bá a lọ láti wí pé: “Ìwọ kì yóò fún mi ní nǹkan kan rárá!+ Bí ìwọ yóò bá ṣe nǹkan yìí fún mi, èmi yóò padà bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran+ rẹ. Èmi yóò máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí rẹ̀.+ 32  Èmi yóò kọjá láàárín gbogbo agbo ẹran rẹ lónìí. Kí ìwọ ya olúkúlùkù àgùntàn aláwọ̀ tó-tò-tó sọ́tọ̀, àti àwọn tí ó ní àwọ̀ pàtápàtá, àti olúkúlùkù àgùntàn aláwọ̀ pupa rúsúrúsú láàárín àwọn ẹgbọrọ àgbò àti èyíkéyìí tí ó jẹ́ aláwọ̀ pàtápàtá àti aláwọ̀ tó-tò-tó láàárín àwọn abo ewúrẹ́. Ní ọjọ́ iwájú, irú ìwọ̀nyẹn ni kí ó jẹ́ owó ọ̀yà+ mi. 33  Kí ohun títọ́ tí mo ń ṣe sì dáhùn fún mi ní ọjọ́ iwájú yòówù tí ìwọ yóò wá wo owó ọ̀yà+ mi; olúkúlùkù èyí tí kò bá jẹ́ aláwọ̀ tó-tò-tó àti aláwọ̀ pàtápàtá láàárín àwọn abo ewúrẹ́ àti aláwọ̀ pupa rúsúrúsú láàárín àwọn ẹgbọrọ àgbò jẹ́ ohun tí a jí, bí ó bá wà pẹ̀lú mi.”+ 34  Lábánì fèsì pé: “Họ́wù, ìyẹn dára púpọ̀! Jẹ́ kí ó rí bí ọ̀rọ̀+ rẹ.” 35  Nígbà náà ni ó ya òbúkọ abilà sọ́tọ̀ àti aláwọ̀ pàtápàtá àti gbogbo abo ewúrẹ́ aláwọ̀ tó-tò-tó àti aláwọ̀ pàtápàtá ní ọjọ́ yẹn, olúkúlùkù èyí tí ó ní funfun èyíkéyìí lára àti olúkúlùkù tí ó bá jẹ́ aláwọ̀ pupa rúsúrúsú láàárín àwọn ẹgbọrọ àgbò, ṣùgbọ́n ó fi wọ́n lé àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. 36  Lẹ́yìn ìyẹn, ó fi àyè tí ó gùn tó ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta sí àárín òun àti Jékọ́bù, Jékọ́bù sì ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran Lábánì tí ó ṣẹ́ kù. 37  Lẹ́yìn náà ni Jékọ́bù mú ọ̀pá tí ó ṣì ní ọ̀rinrin láti ara igi tórásì+ àti ara igi álímọ́ńdì+ àti láti ara igi adánra+ fún ìlò rẹ̀, ó sì bó wọn sí funfun tó-tò-tó nípa ṣíṣí àwọn ibi funfun tí ó wà lára àwọn ọ̀pá+ náà síta. 38  Níkẹyìn, àwọn ọ̀pá tí ó bó náà ni ó kó síwájú agbo ẹran, nínú àwọn kòtò omi, nínú àwọn ọpọ́n+ ìmumi, níbi tí àwọn agbo ẹran náà yóò ti wá mumi, kí wọ́n lè múra tán láti gùn níwájú wọn nígbà tí wọ́n bá wá mumi. 39  Nítorí náà, àwọn agbo ẹran náà yóò múra tán láti gùn níwájú àwọn ọ̀pá náà, àwọn agbo ẹran náà yóò sì bí ọmọ abilà, aláwọ̀ tó-tò-tó àti aláwọ̀ pàtápàtá.+ 40  Jékọ́bù sì ya àwọn ẹgbọrọ àgbò sọ́tọ̀, ó sì yí ojú àwọn agbo ẹran sí àwọn èyí abilà àti gbogbo àwọn aláwọ̀ pupa rúsúrúsú láàárín àwọn agbo ẹran Lábánì. Lẹ́yìn náà, ó kó agbo ẹran ọ̀sìn tirẹ̀ sọ́tọ̀, kò sì kó wọn sí ẹ̀bá agbo ẹran Lábánì. 41  Ó sì ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo pé nígbàkígbà tí agbo ẹran sísanra bọ̀kíbọ̀kí+ bá múra tán láti gùn, Jékọ́bù yóò kó ọ̀pá náà sí ojú kòtò omi+ níwájú àwọn agbo ẹran náà, kí wọ́n lè múra tán láti gùn lẹ́bàá àwọn ọ̀pá náà. 42  Ṣùgbọ́n nígbà tí agbo ẹran bá jẹ́ ahẹrẹpẹ, òun kì yóò fi wọ́n sí ibẹ̀. Nítorí náà, ìgbà gbogbo ni àwọn tí ó jẹ́ ahẹrẹpẹ máa ń jẹ́ ti Lábánì, ṣùgbọ́n àwọn tí ó sanra bọ̀kíbọ̀kí a jẹ́ ti Jékọ́bù.+ 43  Ọkùnrin náà sì ń pọ̀ síwájú àti síwájú sí i, ọ̀pọ̀ agbo ẹran àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti àwọn ràkúnmí àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì wá jẹ́ tirẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé