Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 3:1-24

3  Wàyí o, ejò+ jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra+ jù lọ nínú gbogbo ẹranko inú pápá tí Jèhófà Ọlọ́run dá.+ Nítorí náà, ó sọ fún obìnrin náà pé:+ “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?”+  Látàrí èyí, obìnrin náà sọ fún ejò pé: “Àwa lè jẹ nínú àwọn èso igi ọgbà.+  Ṣùgbọ́n ní ti jíjẹ èso igi tí ó wà ní àárín ọgbà,+ Ọlọ́run ti sọ pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, rárá, ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn án, kí ẹ má bàa kú.’”+  Látàrí èyí, ejò náà sọ fún obìnrin náà pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú.+  Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.”+  Nítorí náà, obìnrin náà rí i pé igi náà dára fún oúnjẹ àti pé ohun kan tí ojú ń yánhànhàn fún ni, bẹ́ẹ̀ ni, igi náà fani lọ́kàn mọ́ra láti wò.+ Nítorí náà, ó mú nínú èso rẹ̀, ó sì jẹ ẹ́.+ Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀ ní díẹ̀ pẹ̀lú nígbà tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.  Nígbà náà ni ojú àwọn méjèèjì là, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mọ̀ pé àwọn wà ní ìhòòhò.+ Nítorí náà, wọ́n gán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì ṣe bàǹtẹ́ fún ara wọn.+  Lẹ́yìn náà, wọ́n gbọ́ ohùn Jèhófà Ọlọ́run tí ń rìn nínú ọgbà ní nǹkan bí ìgbà tí atẹ́gùn máa ń fẹ́ yẹ́ẹ́ ní ọjọ́,+ ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ sì lọ fara pa mọ́ kúrò ní ojú Jèhófà Ọlọ́run, sáàárín àwọn igi ọgbà.+  Jèhófà Ọlọ́run sì ń pe ọkùnrin náà, ó sì ń wí fún un pé: “Ibo ni ìwọ wà?”+ 10  Níkẹyìn, ó sọ pé: “Mo gbọ́ ohùn rẹ nínú ọgbà, ṣùgbọ́n àyà fò mí nítorí pé mo wà ní ìhòòhò nítorí náà mo fi ara mi pa mọ́.”+ 11  Látàrí èyí, ó wí pé: “Ta ní sọ fún ọ pé o wà ní ìhòòhò?+ Ìwọ ha ti jẹ nínú igi tí mo pa láṣẹ fún ọ pé kí o má jẹ bí?”+ 12  Ọkùnrin náà sì ń bá a lọ láti wí pé: “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi láti wà pẹ̀lú mi, òun ni ó fún mi ní èso láti ara igi náà, nítorí náà, mo sì jẹ.”+ 13  Látàrí èyí, Jèhófà Ọlọ́run sọ fún obìnrin náà pé: “Kí ni ìwọ ṣe yìí?” Obìnrin náà fèsì pé: “Ejò—òun ni ó tàn mí, nítorí náà, mo sì jẹ.”+ 14  Jèhófà Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún ejò+ náà pé: “Nítorí tí ìwọ ṣe nǹkan yìí, ẹni ègún ni ọ́ nínú gbogbo ẹran agbéléjẹ̀ àti nínú gbogbo ẹranko inú pápá. Ikùn rẹ ni ìwọ yóò máa fi wọ́, ekuru sì ni ohun tí ìwọ yóò máa jẹ ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ.+ 15  Èmi+ yóò sì fi ìṣọ̀tá+ sáàárín ìwọ+ àti obìnrin+ náà àti sáàárín irú-ọmọ+ rẹ àti irú-ọmọ+ rẹ̀. Òun+ yóò pa ọ́+ ní orí,+ ìwọ+ yóò sì pa á+ ní gìgísẹ̀.”+ 16  Ó wí fún obìnrin náà pé: “Èmi yóò mú ìrora ìlóyún+ rẹ pọ̀ sí i gidigidi; inú ìroragógó ìbímọ ni ìwọ yóò ti máa bí àwọn ọmọ,+ ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ sì ni ìfàsí-ọkàn rẹ yóò máa wà, òun yóò sì jọba lé ọ lórí.”+ 17  Àti fún Ádámù ni òun wí pé: “Nítorí tí o fetí sí ohùn aya rẹ, tí o sì jẹ nínú igi náà tí mo pa àṣẹ+ yìí fún ọ nípa rẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’ ègún ni fún ilẹ̀ ní tìtorí rẹ.+ Inú ìrora ni ìwọ yóò ti máa jẹ àmújáde rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ.+ 18  Ẹ̀gún àti òṣùṣú ni yóò sì máa hù jáde fún ọ,+ ìwọ yóò sì máa jẹ ewéko pápá. 19  Inú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò ti máa jẹ oúnjẹ títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí láti inú rẹ̀ ni a ti mú ọ jáde.+ Nítorí ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà+ sí ekuru.” 20  Lẹ́yìn èyí, Ádámù pe orúkọ aya rẹ̀ ní Éfà,+ nítorí pé òun ni yóò di ìyá gbogbo ẹni tí ń bẹ láàyè.+ 21  Jèhófà Ọlọ́run sì tẹ̀ síwájú láti fi awọ ṣe ẹ̀wù gígùn fún Ádámù àti fún aya rẹ̀, ó sì fi aṣọ wọ̀ wọ́n.+ 22  Jèhófà Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: “Kíyè sí i, ọkùnrin náà ti dà bí ọ̀kan lára wa ní mímọ rere àti búburú,+ wàyí o, kí ó má bàa na ọwọ́ rẹ̀ jáde, kí ó sì tún mú èso ní ti tòótọ́, láti ara igi ìyè,+ kí ó sì jẹ kí ó sì wà láàyè fún àkókò tí ó lọ kánrin,—” 23  Látàrí èyí, Jèhófà Ọlọ́run lé e jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì+ láti máa ro ilẹ̀ láti inú èyí tí a ti mú un jáde wá.+ 24  Nítorí náà, ó lé ọkùnrin náà jáde, ó sì yan àwọn kérúbù+ sí ìlà-oòrùn ọgbà Édẹ́nì+ àti abẹ idà tí ń jó lala, tí ń yí ara rẹ̀ láìdáwọ́ dúró láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ síbi igi ìyè náà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé