Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 29:1-35

29  Lẹ́yìn ìyẹn, Jékọ́bù ti ẹsẹ̀ bọ ìrìn, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ àwọn Ará Ìlà-Oòrùn.+  Ó sì wò, sì kíyè sí i, kànga kan nìyí nínú pápá, sì kíyè sí i, agbo ẹran ọ̀sìn mẹ́ta ti àwọn àgùntàn dùbúlẹ̀ níbẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, nítorí pé ó ti jẹ́ àṣà wọn láti máa fi omi fún àwọn agbo ẹran ọ̀sìn+ láti inú kànga yẹn; òkúta ńlá kan sì wà ní ẹnu kànga+ náà.  Nígbà tí a ti kó gbogbo agbo ẹran ọ̀sìn jọ sí ibẹ̀ tán, wọ́n yí òkúta kúrò ní ẹnu kànga náà, wọ́n sì fi omi fún àwọn agbo ẹran, lẹ́yìn náà, wọ́n dá òkúta náà padà sí ẹnu kànga, sí àyè rẹ̀.  Nítorí náà, Jékọ́bù sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin arákùnrin mi, ibo ni ẹ ti wá?” wọ́n sì dáhùn pé: “Háránì+ ni a ti wá.”  Ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ha mọ Lábánì+ ọmọ-ọmọ Náhórì?”+ wọ́n sì dáhùn pé: “A mọ̀ ọ́n.”  Látàrí èyí, ó wí fún wọn pé: “Ṣé dáadáa ni ó wà?”+ Ẹ̀wẹ̀, wọ́n wí pé: “Dáadáa ni. Sì kíyè sí i, Rákélì+ ọmọbìnrin rẹ̀ ní ń da àwọn àgùntàn+ bọ̀ yìí!”  Ó sì ń bá a lọ láti wí pé: “Họ́wù, ọjọ́ ṣì wà. Àkókò kíkó ọ̀wọ́ ẹran jọ kò tíì tó. Ẹ fi omi fún àwọn àgùntàn, lẹ́yìn náà, kí ẹ lọ bọ́ wọn.”+  Wọ́n fèsì pé: “A kò yọ̀ǹda fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ títí di ìgbà tí a bá kó gbogbo àwọn agbo ẹran ọ̀sìn jọ tí wọ́n sì yí òkúta kúrò ní ẹnu kànga náà ní tòótọ́. Nígbà náà ni a ó fi omi fún àwọn àgùntàn.”  Nígbà tí ó ṣì ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Rákélì+ kó àwọn àgùntàn tí ó jẹ́ ti baba rẹ̀ dé, nítorí tí ó jẹ́ obìnrin olùṣọ́ àgùntàn.+ 10  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí Jékọ́bù rí Rákélì, ọmọbìnrin Lábánì, arákùnrin ìyá rẹ̀, àti àwọn àgùntàn Lábánì arákùnrin ìyá rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jékọ́bù sún mọ́ ibẹ̀, ó sì yí òkúta kúrò ní ẹnu kànga, ó sì fi omi fún àwọn àgùntàn Lábánì arákùnrin+ ìyá rẹ̀. 11  Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù fi ẹnu ko Rákélì lẹ́nu,+ ó sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì bú sí ẹkún.+ 12  Jékọ́bù sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Rákélì pé òun ni arákùnrin+ baba rẹ̀ àti pé òun ni ọmọkùnrin Rèbékà. Obìnrin náà sì sáré lọ sọ fún baba+ rẹ̀. 13  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Lábánì gbọ́ ìròyìn nípa Jékọ́bù ọmọkùnrin arábìnrin rẹ̀, ó sáré lọ láti pàdé rẹ̀.+ Lẹ́yìn náà, ó gbá a mọ́ra, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì mú un wá sínú ilé+ rẹ̀. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣèròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún Lábánì. 14  Lẹ́yìn ìyẹn, Lábánì wí fún un pé: “Egungun mi àti ẹran ara+ mi ni ìwọ ní tòótọ́.” Nítorí náà, ó bá a gbé fún oṣù kan gbáko. 15  Lẹ́yìn ìyẹn, Lábánì wí fún Jékọ́bù pé: “Arákùnrin+ mi ha ni ọ́, ó ha sì yẹ kí o sìn mí lásán+ bí? Sọ fún mi, Kí ni owó ọ̀yà rẹ yóò jẹ́?”+ 16  Ní ti Lábánì, ó ní ọmọbìnrin méjì. Orúkọ ẹ̀gbọ́n ni Léà,+ orúkọ àbúrò sì ni Rákélì. 17  Ṣùgbọ́n ojú Léà kò dán, nígbà tí ó jẹ́ pé Rákélì+ jẹ́ arẹwà ní ìrísí, ó sì lẹ́wà ní ojú.+ 18  Jékọ́bù sì nífẹ̀ẹ́ Rákélì gidigidi. Nítorí náà, ó wí pé: “Mo ṣe tán láti sìn ọ́ fún ọdún méje nítorí Rákélì ọmọbìnrin+ rẹ, èyí àbúrò.” 19  Lábánì wí pé: “Ó sàn fún mi láti fi í fún ọ ju kí n fi í fún ọkùnrin+ mìíràn lọ. Máa bá mi gbé nìṣó.” 20  Jékọ́bù sì bẹ̀rẹ̀ sí sìn fún ọdún méje nítorí Rákélì,+ ṣùgbọ́n ní ojú rẹ̀, ó dà bí ọjọ́ díẹ̀ nítorí ìfẹ́ rẹ̀ fún ọmọbìnrin náà.+ 21  Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù wí fún Lábánì pé: “Fún mi ní aya mi, nítorí pé ọjọ́ mi ti pé, kí o sì jẹ́ kí n ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”+ 22  Pẹ̀lú ìyẹn, Lábánì kó gbogbo àwọn ènìyàn ibẹ̀ jọ, ó sì se àsè.+ 23  Ṣùgbọ́n ó wá ṣẹlẹ̀ pé ní alẹ́, ó yíjú sí mímú Léà ọmọbìnrin rẹ̀ lọ fún un, kí ó lè ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. 24  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Lábánì fi Sílípà+ ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún un, àní fún Léà ọmọbìnrin rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́bìnrin. 25  Nítorí náà, ó ṣẹlẹ̀ pé, ní òwúrọ̀, kíyè sí i, Léà ni! Nítorí náà, ó sọ fún Lábánì pé: “Kí ni ìwọ ṣe fún mi yìí? Kì í ha ṣe nítorí Rákélì ni mo fi sìn ọ́? Nítorí náà, èé ṣe tí o fi ṣe àgálámàṣà sí mi?”+ 26  Lábánì fèsì pé: “Kì í ṣe àṣà láti ṣe báyìí lọ́dọ̀ wa, láti fi obìnrin tí ó jẹ́ àbúrò fúnni ṣáájú àkọ́bí. 27  Ṣe ayẹyẹ+ ọ̀sẹ̀ obìnrin yìí pé. Lẹ́yìn ìyẹn, a ó sì fi obìnrin kejì yìí fún ọ pẹ̀lú fún iṣẹ́ ìsìn tí ìwọ bá lè ṣe fún mi fún ọdún méje sí i.”+ 28  Nítorí náà, Jékọ́bù ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì ṣe ayẹyẹ ọ̀sẹ̀ obìnrin yìí pé, lẹ́yìn èyí tí ó fi Rákélì ọmọbìnrin rẹ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí aya rẹ̀. 29  Ní àfikún, Lábánì fi Bílíhà+ ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún Rákélì ọmọbìnrin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀. 30  Lẹ́yìn náà, ó bá Rákélì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú, ó sì tún fi ìfẹ́ púpọ̀ hàn sí Rákélì jù sí Léà+ lọ, ó sì ń bá a lọ láti sìn ín fún ọdún méje mìíràn sí i.+ 31  Nígbà tí Jèhófà wá rí i pé a kórìíra Léà, nígbà náà, ó ṣí ilé ọlẹ̀+ rẹ̀, ṣùgbọ́n Rákélì yàgàn.+ 32  Léà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Rúbẹ́nì,+ nítorí ó wí pé: “Ó jẹ́ nítorí pé Jèhófà ti wo ipò ìráre+ mi, ní ti pé, nísinsìnyí, ọkọ mi yóò bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ mi.” 33  Ó sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì wí pé: “Ó jẹ́ nítorí pé Jèhófà ti fetí sílẹ̀,+ ní ti pé a kórìíra mi, nítorí náà, ó tún fi eléyìí fún mi.” Nítorí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Síméónì.+ 34  Ó sì tún lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ lẹ́yìn náà pé: “Wàyí o, lọ́tẹ̀ yìí, ọkọ mi yóò dara pọ̀ mọ́ mi, nítorí tí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún un.” Nítorí náà, orúkọ rẹ̀ ni a pè ní Léfì.+ 35  Ó sì lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, ó sì bí ọmọkùnrin kan, lẹ́yìn náà, ó wí pé: “Lọ́tẹ̀ yìí, èmi yóò gbé Jèhófà lárugẹ.” Nítorí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Júdà.+ Lẹ́yìn ìyẹn, ó dẹ́kun bíbímọ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé