Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́nẹ́sísì 28:1-22

28  Nítorí náà, Ísákì pe Jékọ́bù, ó sì súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un, ó sì wí fún un pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú aya nínú àwọn ọmọbìnrin Kénáánì.+  Dìde, lọ sí Padani-árámù sí ilé Bẹ́túélì baba ìyá rẹ, ibẹ̀ ni kí o sì ti mú aya nínú àwọn ọmọbìnrin Lábánì arákùnrin ìyá rẹ.+  Ọlọ́run Olódùmarè yóò sì bù kún ọ, yóò sì mú ọ máa so èso, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, dájúdájú, ìwọ yóò di ìjọ àwọn ènìyàn.+  Òun yóò sì fi ìbùkún Ábúráhámù+ fún ọ, fún ìwọ àti fún irú-ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ,+ kí o lè gba ilẹ̀ tí o ti ṣe àtìpó,+ èyí tí Ọlọ́run ti fi fún Ábúráhámù.”+  Nítorí náà, Ísákì rán Jékọ́bù lọ, ó sì forí lé Padani-árámù, sọ́dọ̀ Lábánì ọmọkùnrin Bẹ́túélì ará Síríà,+ arákùnrin Rèbékà,+ ìyá Jékọ́bù àti Ísọ̀.+  Nígbà tí Ísọ̀ rí i pé Ísákì ti súre fún Jékọ́bù, tí ó sì ti rán an lọ sí Padani-árámù láti mú aya níbẹ̀ fún ara rẹ̀, àti pé nígbà tí ó súre fún un, ó gbé àṣẹ kalẹ̀ fún un, pé: “Má ṣe mú aya nínú àwọn ọmọbìnrin Kénáánì”;+  àti pé Jékọ́bù ń ṣègbọràn sí baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ sí Padani-árámù;+  nígbà náà ni Ísọ̀ rí i pé àwọn ọmọbìnrin Kénáánì jẹ́ okùnfà ìbìnújẹ́ ní ojú Ísákì baba+ rẹ̀.  Nítorí náà, Ísọ̀ lọ sọ́dọ̀ Íṣímáẹ́lì, ó sì mú Máhálátì ọmọbìnrin Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Ábúráhámù, arábìnrin Nébáótì ṣe aya, ní àfikún sí àwọn aya+ rẹ̀ yòókù. 10  Jékọ́bù sì ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ kúrò ní Bíá-ṣébà, ó sì ń lọ sí Háránì.+ 11  Nígbà tí ó ṣe, ó dé ibì kan, ó sì múra láti sùn mọ́jú níbẹ̀ nítorí pé oòrùn ti wọ̀. Nítorí náà, ó gbé ọ̀kan lára àwọn òkúta ibẹ̀, ó sì gbé e lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìgbórílé rẹ̀, ó sì dùbúlẹ̀ ní ibẹ̀.+ 12  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lá àlá,+ sì wò ó! àkàsọ̀ kan tí a gbé dúró sórí ilẹ̀ ayé, tí orí rẹ̀ sì kan ọ̀run; sì wò ó! àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run wà, tí wọ́n ń gòkè, tí wọ́n sì ń sọ̀ kalẹ̀ lórí rẹ̀.+ 13  Sì wò ó! Jèhófà dúró lókè rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé:+ “Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run Ábúráhámù baba rẹ àti Ọlọ́run Ísákì.+ Ilẹ̀ tí ìwọ dùbúlẹ̀ lé yìí, ìwọ àti irú-ọmọ+ rẹ ni èmi yóò fi fún. 14  Irú-ọmọ rẹ yóò sì dà bí àwọn egunrín ekuru ilẹ̀+ dájúdájú, ìwọ yóò sì tàn káàkiri dé ìwọ̀-oòrùn àti dé ìlà-oòrùn àti dé àríwá àti dé gúúsù+ dájúdájú, àti nípasẹ̀ rẹ àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni gbogbo àwọn ìdílé ilẹ̀ yóò bù kún ara wọn dájúdájú.+ 15  Sì kíyè sí i, èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà tí ìwọ ń lọ, èmi yóò sì mú ọ padà sí ilẹ̀+ yìí, nítorí pé èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀ títí èmi yóò fi ṣe ohun tí mo ti sọ fún ọ ní tòótọ́.”+ 16  Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù jí lójú oorun rẹ̀, ó sí wí pé: “Lóòótọ́, Jèhófà wà ní ibí yìí, èmi fúnra mi kò sì mọ̀.” 17  Ẹ̀rù sì bà á, ó sì fi kún un pé:+ “Ẹ wo bí ibí yìí ti jẹ́ amúni-kún-fún-ẹ̀rù tó!+ Èyí kì í ṣe nǹkan mìíràn bí kò ṣe ilé Ọlọ́run,+ èyí sì ni ẹnubodè ọ̀run.” 18  Nítorí náà, Jékọ́bù dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì mú òkúta tí ó fi ṣe ohun ìgbórílé, ó sì gbé e kalẹ̀ bí ọwọ̀n, ó sì da òróró lé orí rẹ̀.+ 19  Síwájú sí i, ó pe orúkọ ibẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì;+ ṣùgbọ́n òtítọ́ náà ni pé, Lúsì ni orúkọ ìlú ńlá náà tẹ́lẹ̀ rí.+ 20  Jékọ́bù sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́ ẹ̀jẹ́+ kan pé: “Bí Ọlọ́run yóò bá máa bá a lọ pẹ̀lú mi, tí yóò sì pa mí mọ́ dájúdájú ní ọ̀nà yìí tí èmi ń lọ, tí yóò sì fi oúnjẹ fún mi láti jẹ àti ẹ̀wù láti wọ̀+ dájúdájú, 21  tí èmi yóò sì padà ní àlàáfíà sí ilé baba mi dájúdájú, nígbà náà, Jèhófà yóò fi hàn pé òun ni Ọlọ́run+ mi. 22  Òkúta yìí tí mo ti gbé kalẹ̀ bí ọwọ̀n yóò sì di ilé Ọlọ́run,+ ní ti ohun gbogbo tí ìwọ yóò sì fi fún mi ni èmi yóò san ìdá mẹ́wàá rẹ̀ fún ọ+ láìkùnà.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé