Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́nẹ́sísì 27:1-46

27  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Ísákì darúgbó tí ojú rẹ̀ sì ti di bàìbàì jù láti fi ríran,+ nígbà náà, ó pe Ísọ̀ ọmọkùnrin rẹ̀ àgbà, ó sì wí fún un pé:+ “Ọmọkùnrin mi!” ó sì dá a lóhùn pé: “Èmi nìyí!”  Ó sì ń bá a lọ pé: “Kíyè sí i, nísinsìnyí, mo ti darúgbó.+ Èmi kò mọ ọjọ́ ikú+ mi.  Nítorí náà, nísinsìnyí, jọ̀wọ́, mú àwọn ohun èlò ìṣiṣẹ́ rẹ, apó rẹ àti ọrun rẹ, kí o sì jáde lọ sí pápá, kí o sì ṣọdẹ ẹran ìgbẹ́ fún mi.+  Lẹ́yìn náà, kí o se oúnjẹ olóyin-mọmọ, irú èyí tí mo kúndùn, kí o sì gbé e wá fún mi, àháà, kí n sì jẹ ẹ́, kí ọkàn mi lè súre fún ọ, kí n tó kú.”+  Bí ó ti wù kí ó rí, Rèbékà ń fetí sílẹ̀ nígbà tí Ísákì ń bá Ísọ̀ ọmọkùnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀. Ísọ̀ sì jáde lọ sí pápá láti ṣọdẹ ẹran ìgbẹ́, kí ó sì mú un wá.+  Rèbékà sì wí fún Jékọ́bù ọmọkùnrin rẹ̀ pé:+ “Kíyè sí i, mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ tí baba rẹ bá Ísọ̀ arákùnrin rẹ sọ̀rọ̀ tán ni, pé,  ‘Mú ẹran ìgbẹ́ wá fún mi, kí o sì se oúnjẹ olóyin-mọmọ, àháà, kí n sì jẹ ẹ́, kí n lè súre fún ọ níwájú Jèhófà, ṣáájú ikú+ mi.’  Wàyí o, ọmọkùnrin mi, fetí sí ohùn mi nínú ohun tí èmi yóò pa láṣẹ fún ọ.+  Jọ̀wọ́, lọ sínú ọ̀wọ́ ẹran, kí o sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì níbẹ̀ wá fún mi, àwọn tí ó dára, kí n lè fi wọ́n se oúnjẹ olóyin-mọmọ fún baba rẹ, irú èyí tí ó kúndùn. 10  Lẹ́yìn náà, kí o gbé e lọ sọ́dọ̀ baba rẹ, kí ó sì jẹ ẹ́, kí ó lè súre fún ọ, ṣáájú ikú rẹ̀.” 11  Jékọ́bù sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Rèbékà ìyá rẹ̀ pé: “Ṣùgbọ́n Ísọ̀ arákùnrin mi jẹ́ onírun lára, èmi sì jẹ́ alára ọ̀bọ̀rọ́.+ 12  Ǹjẹ́ bí baba mi bá fọwọ́ bà mí ńkọ́?+ Nígbà náà, dájúdájú, ní ojú rẹ̀ èmi yóò dà bí ẹni tí ń ṣẹlẹ́yà,+ dájúdájú, èmi a sì mú ìfiré wá sórí ara mi, kì í sì í ṣe ìbùkún.”+ 13  Látàrí èyí, ìyá rẹ̀ wí fún un pé: “Orí mi ni kí ìfiré tí ó wà fún ọ wá, ọmọkùnrin+ mi. Kìkì kí o fetí sí ohùn mi, kí o sì lọ mú [wọn] wá fún mi.”+ 14  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó lọ, ó sì mú [wọn] wá fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì se oúnjẹ olóyin-mọmọ, irú èyí tí baba rẹ̀ kúndùn. 15  Lẹ́yìn náà, Rèbékà mú ẹ̀wù Ísọ̀ ọmọkùnrin+ rẹ̀ àgbà, èyí tí ó jẹ́ ààyò, tí ó wà nínú ilé+ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì gbé e wọ Jékọ́bù ọmọkùnrin+ rẹ̀, èyí àbúrò. 16  Awọ àwọn ọmọ ewúrẹ́ náà ni ó sì fi bo ọwọ́ rẹ̀ àti ibi tí kò ní irun ní ọrùn+ rẹ̀. 17  Lẹ́yìn náà, ó gbé oúnjẹ olóyin-mọmọ àti búrẹ́dì tí ó ṣe lé Jékọ́bù ọmọkùnrin+ rẹ̀ lọ́wọ́. 18  Nítorí náà, ó wọlé lọ bá baba rẹ̀, ó sì wí pé: “Baba mi!” òun sì dáhùn pé: “Èmi nìyí! Ta ni ọ́, ọmọkùnrin mi?” 19  Jékọ́bù sì ń bá a lọ láti wí fún baba rẹ̀ pé: “Èmi ni Ísọ̀ àkọ́bí+ rẹ. Mo ti ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ fún mi. Jọ̀wọ́, gbéra nílẹ̀. Jókòó, kí o sì jẹ díẹ̀ lára ẹran ìgbẹ́ tí mo pa, kí ọkàn rẹ lè súre fún mi.”+ 20  Látàrí ìyẹn, Ísákì sọ fún ọmọkùnrin rẹ̀ pé: “Báwo ló ti jẹ́ tí o fi rí i ní kíá bẹ́ẹ̀, ọmọkùnrin mi?” Ẹ̀wẹ̀, òun wí pé: “Nítorí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ mú kí ó pàdé mi ni.” 21  Nígbà náà ni Ísákì wí fún Jékọ́bù pé: “Sún mọ́ tòsí, jọ̀wọ́, kí n lè fọwọ́ bà ọ́, ọmọkùnrin mi, láti mọ̀ bóyá ìwọ ni ọmọkùnrin mi Ísọ̀ ní tòótọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.”+ 22  Nítorí náà, Jékọ́bù sún mọ́ Ísákì baba rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fọwọ́ bà á, lẹ́yìn èyí ó wí pé: “Ohùn jẹ́ ohùn Jékọ́bù ṣùgbọ́n ọwọ́ jẹ́ ọwọ́ Ísọ̀.”+ 23  Òun kò sì dá a mọ̀, nítorí tí ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ onírun bí ọwọ́ Ísọ̀ arákùnrin rẹ̀. Nítorí náà, ó súre fún un.+ 24  Lẹ́yìn ìyẹn, ó wí pé: “Ìwọ ha ni ọmọkùnrin mi Ísọ̀ ní tòótọ́ bí?” ó dáhùn pé: “Èmi ni.”+ 25  Nígbà náà, ó wí pé: “Gbé e sún mọ́ mi, kí n lè jẹ lára ẹran ìgbẹ́ tí ọmọkùnrin mi pa, kí ọkàn mi lè súre fún ọ.”+ Pẹ̀lú ìyẹn, ó gbé e sún mọ́ ọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́, ó sì gbé wáìnì wá fún un, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mu ún. 26  Lẹ́yìn náà, Ísákì baba rẹ̀ wí fún un pé: “Sún mọ́ tòsí, jọ̀wọ́, kí o sì fi ẹnu kò mí lẹ́nu, ọmọkùnrin+ mi.” 27  Nítorí náà, ó sún mọ́ tòsí, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì gbóòórùn ìtasánsán ẹ̀wù rẹ̀.+ Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún un pé: “Wò ó, ìtasánsán ọmọkùnrin mi dà bí ìtasánsán pápá tí Jèhófà bù kún. 28  Kí Ọlọ́run tòótọ́ fi ìrì ojú ọ̀run+ àti àwọn ilẹ̀ ọlọ́ràá ilẹ̀ ayé+ àti ọ̀pọ̀ yanturu ọkà àti wáìnì tuntun+ fún ọ. 29  Kí àwọn ènìyàn máa sìn ọ́, kí àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè sì tẹrí ba mọ́lẹ̀ fún ọ.+ Di ọ̀gá lórí àwọn arákùnrin rẹ, kí àwọn ọmọ ìyá rẹ sì tẹrí ba mọ́lẹ̀ fún ọ.+ Ègún ni fún olúkúlùkù àwọn tí ń fi ọ́ gégùn-ún, ìbùkún sì ni fún olúkúlùkù àwọn tí ń súre fún ọ.”+ 30  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí Ísákì parí sísúre fún Jékọ́bù, bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣẹlẹ̀ ní tòótọ́ pé gẹ́rẹ́ tí Jékọ́bù jáde kúrò níwájú Ísákì baba rẹ̀, ni Ísọ̀ arákùnrin rẹ̀ padà dé láti oko ọdẹ.+ 31  Òun pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí se oúnjẹ olóyin-mọmọ. Lẹ́yìn náà, ó gbé e wá fún baba rẹ̀, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé: “Kí baba mi dìde, kí ó sì jẹ lára ẹran ìgbẹ́ tí ọmọkùnrin rẹ̀ pa, kí ọkàn rẹ lè súre fún mi.”+ 32  Látàrí èyí, Ísákì baba rẹ̀ wí fún un pé: “Ta ni ọ́?” ó dáhùn pé: “Èmi ọmọkùnrin rẹ ni, àkọ́bí rẹ, Ísọ̀.”+ 33  Ísákì sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n pẹ̀lú ìwárìrì ńláǹlà ní ìwọ̀n tí ó dé góńgó, nítorí náà, ó wí pé: “Nígbà náà, ta ni ó ṣọdẹ ẹran ìgbẹ́, tí ó sì wá gbé e fún mi, tí ó fi jẹ́ pé mo jẹ nínú ohun gbogbo, kí o tó wọlé wá, tí mo sì súre fún un? Òun pẹ̀lú yóò di alábùkún!”+ 34  Ní gbígbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ baba rẹ̀, Ísọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ké rara lọ́nà kíkorò kíkankíkan, ó sì wí fún baba+ rẹ̀ pé: “Súre fún mi, àní fún èmi náà, baba+ mi!” 35  Ṣùgbọ́n ó ń bá a lọ láti wí pé: “Arákùnrin rẹ wá pẹ̀lú ẹ̀tàn, kí ó lè gba ìbùkún tí ó wà fún ọ.”+ 36  Látàrí èyí, ó wí pé: “Ìyẹn ha kọ́ ni ìdí tí a fi pe orúkọ rẹ̀ ni Jékọ́bù, ní ti pé ó fèrú gbapò mi lẹ́ẹ̀mejì yìí?+ Ogún ìbí mi ni ó ti gbà ná,+ sì kíyè sí i, lọ́tẹ̀ yìí, ó ti gba ìbùkún mi!”+ Lẹ́yìn náà, ó fi kún un pé: “Ṣé ìwọ kò ṣẹ́ ìbùkún kan kù fún mi ni?” 37  Ṣùgbọ́n Ísákì ń bá a lọ láti dá Ísọ̀ lóhùn pé: “Kíyè sí i, mo ti yàn án ṣe ọ̀gá lórí rẹ,+ gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ sì ni mo ti fi fún un gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́,+ ọkà àti wáìnì tuntun ni mo sì ti fi jíǹkí rẹ̀ fún ìtìlẹyìn+ rẹ̀, ohunkóhun tí mo sì lè ṣe fún ọ dà, ọmọkùnrin mi?” 38  Nígbà náà ni Ísọ̀ wí fún baba rẹ̀ pé: “Ṣé ẹyọ ìbùkún kan ṣoṣo ni o ní, baba mi? Súre fún mi, àní fún èmi náà, baba+ mi!” Pẹ̀lú ìyẹn, Ísọ̀ gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì bú sẹ́kún.+ 39  Nítorí náà, ní ìdáhùn, Ísákì baba rẹ̀ wí fún un pé: “Kíyè sí i, ibi jíjìnnà sí ilẹ̀ ọlọ́ràá ilẹ̀ ayé ni a ó ti rí ibùgbé rẹ, àti ibi jíjìnnà sí ìrì òkè ọ̀run.+ 40  Nípa idà rẹ sì ni ìwọ yóò máa wà láàyè,+ arákùnrin rẹ sì ni ìwọ yóò máa sìn.+ Ṣùgbọ́n yóò ṣẹlẹ̀ dájúdájú pé, nígbà tí ìwọ bá di aláìlègbéjẹ́ẹ́, ìwọ yóò ṣẹ́ àjàgà rẹ̀ kúrò ní ọrùn+ rẹ ní ti gidi.” 41  Bí ó ti wù kí ó rí, Ísọ̀ di Jékọ́bù sínú ní tìtorí ìbùkún tí baba rẹ̀ ti fi súre fún un,+ Ísọ̀ sì ń sọ nínú ọkàn-àyà+ rẹ̀ pé: “Àwọn ọjọ́ ṣíṣọ̀fọ̀ baba mi ń sún mọ́lé.+ Lẹ́yìn ìyẹn, èmi yóò pa Jékọ́bù arákùnrin+ mi.” 42  Nígbà tí a sọ àwọn ọ̀rọ̀ Ísọ̀ ọmọkùnrin rẹ̀ àgbà fún Rèbékà, lójú-ẹsẹ̀, ó ránṣẹ́ pe Jékọ́bù ọmọkùnrin rẹ̀, èyí àbúrò, ó sì wí fún un pé: “Wò ó! Ísọ̀ arákùnrin rẹ ń tu ara rẹ̀ nínú nípa rẹ—láti pa ọ́.+ 43  Wàyí o, nígbà náà, ọmọkùnrin mi, fetí sí ohùn mi, kí o sì dìde,+ fẹsẹ̀ fẹ lọ sọ́dọ̀ Lábánì arákùnrin mi ní Háránì.+ 44  Kí o sì máa gbé pẹ̀lú rẹ̀ fún àwọn ọjọ́ mélòó kan, títí ìhónú arákùnrin rẹ yóò fi rọ̀ wọ̀ọ̀,+ 45  títí ìbínú arákùnrin rẹ yóò fi yí kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, tí yóò sì fi gbàgbé ohun tí o ṣe sí i.+ Dájúdájú, èmi yóò ránṣẹ́, èmi yóò sì mú ọ kúrò níbẹ̀. Èé ṣe ti a ó fi mú kí n ṣòfò ẹ̀yin méjèèjì ní ọjọ́ kan?” 46  Lẹ́yìn ìyẹn, Rèbékà ń wí ṣáá fún Ísákì pé: “Mo ti wá fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ìgbésí ayé tèmi yìí nítorí àwọn ọmọbìnrin Hétì.+ Bí Jékọ́bù bá lọ mú aya nínú àwọn ọmọbìnrin Hétì bí ìwọ̀nyí nínú àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ yìí, ire wo ni ìgbésí ayé jẹ́ fún mi?”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé