Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́nẹ́sísì 25:1-34

25  Síwájú sí i, Ábúráhámù tún fẹ́ aya kan, orúkọ rẹ̀ sì ni Kétúrà.+  Nígbà tí ó ṣe, ó bí Símíránì àti Jókíṣánì àti Médánì àti Mídíánì+ àti Íṣíbákì àti Ṣúáhì.+  Jókíṣánì sì bí Ṣébà+ àti Dédánì.+ Àwọn ọmọ Dédánì sì wá jẹ́ Áṣúrímù àti Létúṣímù àti Léúmímù.  Àwọn ọmọkùnrin Mídíánì sì ni Eéfà+ àti Éférì àti Hánókù àti Ábíídà àti Élídáà.+ Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọkùnrin Kétúrà.  Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù fi ohun gbogbo tí ó ní fún Ísákì,+  ṣùgbọ́n àwọn ọmọ wáhàrì tí Ábúráhámù ní ni Ábúráhámù fún ní àwọn ẹ̀bùn.+ Lẹ́yìn náà, ó rán wọn lọ kúrò lọ́dọ̀ Ísákì ọmọkùnrin+ rẹ̀, nígbà tí ó ṣì wà láàyè, síhà ìlà-oòrùn, sí ilẹ̀ Ìlà-Oòrùn.+  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọjọ́ ọdún ìgbésí ayé Ábúráhámù tí ó gbé, ọdún márùn-dín-lọ́gọ́sàn-án.  Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù gbẹ́mìí mì, ó sì kú ní ọjọ́ ogbó gidi gan-an, ó darúgbó, ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn, a sì kó o jọpọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.+  Nítorí náà, Ísákì àti Íṣímáẹ́lì, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, sin ín sí hòrò Mákípẹ́là, ní pápá Éfúrónì ọmọkùnrin Sóhárì ọmọ Hétì tí ó wà ní iwájú Mámúrè,+ 10  pápá tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hétì. Ibẹ̀ ni a sin Ábúráhámù sí, àti Sárà+ aya rẹ̀ pẹ̀lú. 11  Ó sì wá ṣẹlẹ̀ pé lẹ́yìn ikú Ábúráhámù, Ọlọ́run ń bá a lọ láti bù kún Ísákì ọmọkùnrin rẹ̀,+ Ísákì sì ń gbé nítòsí Bia-laháí-róì.+ 12  Èyí sì ni ọ̀rọ̀-ìtàn nípa Íṣímáẹ́lì+ ọmọkùnrin Ábúráhámù, ẹni tí Hágárì ará Íjíbítì ìránṣẹ́bìnrin Sárà bí fún Ábúráhámù.+ 13  Wàyí o, ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọkùnrin Íṣímáẹ́lì, nípa orúkọ wọn, ní ibámu pẹ̀lú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìdílé wọn: Àkọ́bí Íṣímáẹ́lì Nébáótì+ àti Kídárì+ àti Ádíbéélì àti Míbúsámù+ 14  àti Míṣímà àti Dúmà àti Máásà, 15  Hádádì+ àti Témà,+ Jétúrì, Náfíṣì àti Kédémà.+ 16  Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Íṣímáẹ́lì, ìwọ̀nyí sì ni orúkọ wọn nípa àgbàlá wọn àti nípa ibùdó wọn tí a mọ ògiri yí ká:+ ìjòyè méjìlá ní ìbámu pẹ̀lú agbo ìdílé+ wọn. 17  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọdún ìgbésí ayé Íṣímáẹ́lì, ọdún mẹ́tàdínlógóje. Lẹ́yìn náà, ó gbẹ́mìí mì, ó sì kú, a sì kó o jọpọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.+ 18  Wọ́n sì pàgọ́ láti Háfílà+ nítòsí Ṣúrì,+ èyí tí ó wà ní iwájú Íjíbítì, títí dé Ásíríà. Ní iwájú gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ ni ó tẹ̀ dó sí.+ 19  Èyí sì ni ọ̀rọ̀-ìtàn nípa Ísákì ọmọkùnrin Ábúráhámù.+ Ábúráhámù bí Ísákì. 20  Ísákì sì wá jẹ́ ẹni ogójì ọdún nígbà tí ó mú Rèbékà, ọmọbìnrin Bẹ́túélì+ ará Síríà+ ti Padani-árámù, arábìnrin Lábánì ará Síríà, ṣe aya rẹ̀. 21  Ísákì sì ń pàrọwà ṣáá sí Jèhófà ní pàtàkì fún aya+ rẹ̀, nítorí pé ó yàgàn;+ nítorí náà, Jèhófà jẹ́ kí a pàrọwà sí òun nítorí rẹ̀,+ Rèbékà aya rẹ̀ sì lóyún. 22  Àwọn ọmọ tí ó wà nínú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn jìjàkadì,+ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi wí pé: “Bí ó bá jẹ́ pé bí ó ti rí nìyí, èé ṣe tí mo fi wà láàyè gan-an?” Pẹ̀lú ìyẹn, ó lọ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà.+ 23  Jèhófà sì wí fún un pé: “Orílẹ̀-èdè méjì ni ó wà ní ikùn+ rẹ, àwùjọ orílẹ̀-èdè méjì ni a ó sì yà sọ́tọ̀ láti àwọn ìhà inú+ rẹ; àwùjọ orílẹ̀-èdè kan yóò sì lágbára ju àwùjọ orílẹ̀-èdè kejì,+ ẹ̀gbọ́n ni yóò sì sin àbúrò.”+ 24  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ pé láti bímọ, sì wò ó! ìbejì wà nínú ikùn+ rẹ̀. 25  Nígbà náà, àkọ́kọ́ jáde wá ní pupa látòkèdélè bí ẹ̀wù oyè tí a fi irun+ ṣe; nítorí náà wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ísọ̀.+ 26  Lẹ́yìn ìyẹn, arákùnrin rẹ̀ sì jáde wá, ọwọ́ rẹ̀ sì di gìgísẹ̀ Ísọ̀+ mú; nítorí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Jékọ́bù.+ Ísákì sì jẹ́ ẹni ọgọ́ta ọdún nígbà tí ó bí wọn. 27  Àwọn ọmọdékùnrin náà sì ń dàgbà sí i, Ísọ̀ sì di ọkùnrin tí ó mọ bí a ti ṣé ń ṣọdẹ,+ ọkùnrin inú pápá, ṣùgbọ́n Jékọ́bù ọkùnrin aláìlẹ́gàn,+ tí ń gbé inú àwọn àgọ́.+ 28  Ísákì sì nífẹ̀ẹ́ Ísọ̀, nítorí tí ó túmọ̀ sí rírí ẹran ìgbẹ́ jẹ, nígbà tí ó jẹ́ pé Rèbékà nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù.+ 29  Lákòókò kan tí Jékọ́bù ń se ọbẹ̀, Ísọ̀ dé láti inú pápá, ó sì ti rẹ̀ ẹ́. 30  Nítorí náà, Ísọ̀ wí fún Jékọ́bù pé: “Jọ̀wọ́, tètè fún mi ní ìwọ̀n tí ó ṣe é gbé mì lẹ́ẹ̀kan lára pupa—pupa yẹn, nítorí àárẹ̀ ti mú mi!” Ìdí nìyẹn tí a fi pe orúkọ rẹ̀ ní Édómù.+ 31  Jékọ́bù fèsì pé: “Ta ẹ̀tọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí+ fún mi lákọ̀ọ́kọ́ ná!” 32  Ísọ̀ sì ń bá a lọ pé: “Èmi nìyí tí mo ń kú lọ, àǹfààní wo sì ni ogún ìbí jẹ́ fún mi?” 33  Jékọ́bù sì fi kún un pé: “Kọ́kọ́ búra fún mi ná!”+ Ó sì tẹ̀ síwájú láti búra fún un, ó sì ta ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí fún Jékọ́bù.+ 34  Jékọ́bù sì fún Ísọ̀ ní búrẹ́dì àti ọbẹ̀ ẹ̀wà lẹ́ńtìlì, ó sì jẹ, ó sì mu.+ Lẹ́yìn náà, ó dìde, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. Nítorí náà, Ísọ̀ tẹ́ńbẹ́lú ogún ìbí+ náà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé