Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́nẹ́sísì 24:1-67

24  Wàyí o, Ábúráhámù ti darúgbó, ó pọ̀ ní ọdún; Jèhófà sì ti bù kún Ábúráhámù nínú ohun gbogbo.+  Nítorí náà, Ábúráhámù sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀, èyí tí ó dàgbà jù lọ nínú agbo ilé rẹ̀, tí ń mójú tó gbogbo ohun tí ó ní pé:+ “Jọ̀wọ́, fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi,+  bí èmi yóò ti mú ọ fi Jèhófà,+ Ọlọ́run ọ̀run àti Ọlọ́run ilẹ̀ ayé búra, pé ìwọ kì yóò mú aya fún ọmọkùnrin mi nínú àwọn ọmọbìnrin Kénáánì láàárín àwọn ẹni tí mo ń gbé,+  ṣùgbọ́n ìwọ yóò lọ sí ilẹ̀ mi àti sọ́dọ̀ àwọn ìbátan mi,+ dájúdájú, ìwọ yóò sì mú aya fún ọmọkùnrin mi, fún Ísákì.”  Bí ó ti wù kí ó rí, ìránṣẹ́ náà sọ fún un pé: “Bí obìnrin náà kò bá fẹ́ bá mi wá sí ilẹ̀ yìí ńkọ́? Ṣé kí èmi rí i dájú pé mo dá ọmọkùnrin rẹ padà sí ilẹ̀ tí o ti jáde kúrò?”+  Látàrí èyí, Ábúráhámù wí fún un pé: “Ṣọ́ra rẹ kí o má ṣe dá ọmọkùnrin mi padà sí ibẹ̀.+  Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run, ẹni tí ó mú mi kúrò ní ilé baba mi àti kúrò ní ilẹ̀ àwọn ìbátan mi,+ tí ó sì bá mi sọ̀rọ̀, tí ó sì búra fún mi,+ pé, ‘Irú-ọmọ+ rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún,’+ òun yóò rán áńgẹ́lì rẹ̀ lọ ṣáájú rẹ,+ ìwọ yóò sì mú aya fún ọmọkùnrin mi láti ibẹ̀ wá dájúdájú.+  Ṣùgbọ́n bí obìnrin náà kò bá fẹ́ láti bá ọ wá, ìwọ pẹ̀lú yóò bọ́ lọ́wọ́ ìbúra tí o ṣe fún mi yìí.+ Kìkì pé ìwọ kò gbọ́dọ̀ dá ọmọkùnrin mi padà sí ibẹ̀.”  Pẹ̀lú ìyẹn, ìránṣẹ́ náà fi ọwọ́ rẹ̀ sí abẹ́ itan Ábúráhámù ọ̀gá rẹ̀, ó sì búra fún un nípa ọ̀ràn yìí.+ 10  Nítorí náà, ìránṣẹ́ náà mú ràkúnmí mẹ́wàá láti inú àwọn ràkúnmí ọ̀gá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú gbogbo onírúurú ohun rere tí ó jẹ́ ti ọ̀gá rẹ̀ dání pẹ̀lú rẹ̀.+ Lẹ́yìn náà, ó dìde, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí Mesopotámíà sí ìlú ńlá ti Náhórì. 11  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó mú kí àwọn ràkúnmí náà kúnlẹ̀ ní òde ìlú ńlá náà ní ibi kànga omi kan ní nǹkan bí ọwọ́ ìrọ̀lẹ́,+ ní nǹkan bí àkókò tí àwọn obìnrin tí ń fa omi sábà máa ń jáde.+ 12  Ó sì ń bá a lọ láti wí pé: “Jèhófà Ọlọ́run ọ̀gá mi Ábúráhámù,+ jọ̀wọ́, mú kí ó ṣẹlẹ̀ níwájú mi ní òní yìí, kí o sì ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ sí ọ̀gá mi Ábúráhámù.+ 13  Kíyè sí i, èmi dúró níbi ìsun omi, àwọn ọmọbìnrin àwọn ọkùnrin ìlú ńlá náà sì ń jáde bọ̀ wá fa omi.+ 14  Kí ó ṣẹlẹ̀ pé ọ̀dọ́bìnrin tí èmi bá wí fún pé, ‘Jọ̀wọ́, sọ ìṣà omi rẹ kalẹ̀, kí èmi lè mu,’ tí yóò sì wí ní ti gidi pé, ‘Mu, èmi yóò sì tún fi omi fún àwọn ràkúnmí rẹ,’ ẹni yìí ni kí o yàn fún ìránṣẹ́ rẹ,+ fún Ísákì; kí o sì tipa èyí jẹ́ kí n mọ̀ pé o ti fi ìfẹ́ dídúró ṣinṣin hàn sí ọ̀gá mi.”+ 15  Tóò, ó ṣẹlẹ̀ pé kí ó tó parí ọ̀rọ̀ sísọ,+ họ́wù, kíyè sí i, ẹni tí ó jáde wá ni Rèbékà, tí a bí fún Bẹ́túélì,+ ọmọkùnrin Mílíkà,+ aya Náhórì,+ arákùnrin Ábúráhámù, ìṣà omi rẹ̀ sì wà lórí èjìká rẹ̀.+ 16  Wàyí o, ọ̀dọ́bìnrin náà fani mọ́ra gidigidi ní ìrísí,+ wúńdíá ni, kò sì sí ọkùnrin kankan tí ó tíì ní ìbádàpọ̀ takọtabo pẹ̀lú rẹ̀;+ ó sì sọ̀ kalẹ̀ lọ ní ọ̀nà rẹ̀ sí ibi ìsun omi náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pọn omi kún ìṣà rẹ̀, ó sì gòkè wá. 17  Ní kíá, ìránṣẹ́ náà sáré pàdé rẹ̀, ó sì wí pé: “Jọ̀wọ́ fún mi ní òfèrè omi díẹ̀ láti inú ìṣà omi rẹ.”+ 18  Ẹ̀wẹ̀, obìnrin náà wí pé: “Mu, olúwa mi.” Pẹ̀lú ìyẹn, ó yára sọ ìṣà rẹ̀ ka ọwọ́ rẹ̀, ó sì fún un ní omi mu.+ 19  Nígbà tí ó parí fífún un ní omi mu, ó wá wí pé: “Àwọn ràkúnmí rẹ ni èmi yóò tún fa omi fún títí tí wọn yóò fi mu tẹ́rùn.”+ 20  Nítorí náà, ó yára tú ìṣà rẹ̀ sínú ọpọ́n ìmumi, ó sì sáré léraléra lọ síbi kànga náà láti fa omi,+ ó sì ń bá a nìṣó láti fa omi fún gbogbo àwọn ràkúnmí rẹ̀. 21  Ní gbogbo àkókò yìí, ọkùnrin náà tẹjú mọ́ ọn pẹ̀lú kàyéfì, ní dídákẹ́jẹ́ẹ́ láti mọ̀ bóyá Jèhófà ti mú kí ìrìnnà àjò òun yọrí sí rere tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.+ 22  Nítorí náà, ó ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí àwọn ràkúnmí parí mímu omi, ìgbà náà ni ọkùnrin náà mú òrùka imú ti wúrà+ tí ó jẹ́ ìlàjì ṣékélì ní ìwọ̀n àti júfù+ méjì fún àwọn ọwọ́ rẹ̀, ṣékélì wúrà mẹ́wàá ni ìwọ̀n wọn, 23  ó sì ń bá a lọ láti wí pé: “Ọmọbìnrin ta ni ìwọ? Jọ̀wọ́, sọ fún mi. Yàrá ha wà ní ilé baba rẹ fún wa láti sùn mọ́jú bí?”+ 24  Látàrí ìyẹn, ó sọ fún un pé: “Èmi ni ọmọbìnrin Bẹ́túélì,+ ọmọkùnrin Mílíkà, tí ó bí fún Náhórì.”+ 25  Ó sì sọ fún un síwájú sí i pé: “Èérún pòròpórò àti oúnjẹ ẹran púpọ̀ wà lọ́dọ̀ wa, àyè tún wà láti sùn mọ́jú.”+ 26  Ọkùnrin náà sì ń bá a lọ láti tẹrí ba, ó sì wólẹ̀ níwájú Jèhófà,+ 27  ó sì wí pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà+ Ọlọ́run ọ̀gá mi Ábúráhámù, ẹni tí kò fi inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ àti jíjẹ́ aṣeégbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sí ọ̀gá mi sílẹ̀. Bi mo ti wà lójú ọ̀nà, Jèhófà ti ṣamọ̀nà mi sí ilé àwọn arákùnrin ọ̀gá mi.”+ 28  Ọ̀dọ́bìnrin náà sì sáré lọ, ó sì sọ nípa àwọn ohun wọ̀nyí fún agbo ilé ìyá rẹ̀. 29  Wàyí o, Rèbékà ní arákùnrin kan, orúkọ rẹ̀ sì ni Lábánì.+ Nítorí náà, Lábánì sì sáré lọ bá ọkùnrin náà tí ó wà ní òde níbi ìsun omi. 30  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé bí ó ti rí òrùka imú àti júfù+ tí ó wà ní ọwọ́ arábìnrin rẹ̀, tí ó sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Rèbékà arábìnrin rẹ̀, pé: “Bí ọkùnrin náà ti bá mi sọ̀rọ̀ nìyí,” nígbà náà ni ó wá sọ́dọ̀ ọkùnrin náà, ó sì wà níbẹ̀, tí ó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ràkúnmí níbi ìsun omi. 31  Lójú-ẹsẹ̀, ó wí pé: “Wá, ìwọ alábùkún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.+ Èé ṣe tí o fi ń bá a nìṣó láti dúró lóde níhìn-ín, nígbà tí èmi fúnra mi ti pèsè ilé sílẹ̀ àti àyè fún àwọn ràkúnmí?” 32  Pẹ̀lú ìyẹn, ọkùnrin náà wá sínú ilé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tú ìjánu àwọn ràkúnmí, ó sì fún àwọn ràkúnmí náà ní èérún pòròpórò àti oúnjẹ ẹran àti omi láti wẹ ẹsẹ̀ rẹ̀ àti ẹsẹ̀ àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 33  Lẹ́yìn náà, a gbé ohun jíjẹ kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Èmi kò ní jẹun títí di ìgbà tí mo bá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀ràn mi.” Nítorí náà ó wí pé: “Sọ̀rọ̀!”+ 34  Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Ìránṣẹ́ Ábúráhámù ni mí.+ 35  Jèhófà sì ti bù kún ọ̀gá mi gidigidi, ní ti pé ó ń mú un pọ̀ sí i ní fífún un ní àwọn àgùntàn àti àwọn màlúù àti fàdákà àti wúrà àti àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ràkúnmí àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+ 36  Síwájú sí i, Sárà aya ọ̀gá mi bí ọmọkùnrin kan fún ọ̀gá mi lẹ́yìn tí ó ti darúgbó;+ ọ̀gá mi yóò sì fi ohun gbogbo tí ó ní fún un.+ 37  Nítorí náà, ọ̀gá mi mú kí n búra, pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú aya fún ọmọkùnrin mi láti inú àwọn ọmọbìnrin Kénáánì, ilẹ̀ àwọn ẹni tí mo ń gbé.+ 38  Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n ìwọ yóò lọ sí ilé baba mi àti sí ọ̀dọ̀ ìdílé mi,+ ìwọ yóò sì mú aya fún ọmọkùnrin mi.’+ 39  Ṣùgbọ́n mo sọ fún ọ̀gá mi pé, ‘Bí obìnrin náà kò bá ní bá mi wá ńkọ́?’+ 40  Nígbà náà, ó wí fún mi pé, ‘Jèhófà, níwájú ẹni tí mo ti rìn,+ yóò rán áńgẹ́lì+ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ, yóò sì mú kí o ní àṣeyọrí sí rere ní ọ̀nà rẹ dájúdájú;+ kí ìwọ sì mú aya fún ọmọkùnrin mi láti inú ìdílé mi àti láti inú ilé baba mi.+ 41  Ní àkókò yẹn, ìwọ yóò di òmìnira kúrò nínú iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe fún mi nípasẹ̀ ìbúra nígbà tí o bá dé ọ̀dọ̀ ìdílé mi, bí wọn kò bá sì ní fi í fún ọ, nígbà náà, ìwọ yóò bọ́ lọ́wọ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe fún mi nípasẹ̀ ìbúra.’+ 42  “Nígbà tí mo dé ibi ìsun omi lónìí, nígbà náà ni mo wí pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run ọ̀gá mi Ábúráhámù, bí ìwọ ní ti tòótọ́ bá máa mú kí n ní àṣeyọrí sí rere ní ọ̀nà mi tí mo ń lọ,+ 43  kíyè sí i, mo dúró ní ibi ìsun omi. Kí ó ṣẹlẹ̀ pé omidan+ tí ó bá jáde wá fa omi, tí èmi yóò sọ ní ti gidi fún pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n mu omi díẹ̀ láti inú ìṣà rẹ,” 44  tí yóò sì sọ fún mi ní tòótọ́ pé: “Ẹ mu omi, èmi yóò sì tún fa omi fún àwọn ràkúnmí rẹ,” òun ni obìnrin tí Jèhófà yàn fún ọmọkùnrin ọ̀gá+ mi.’ 45  “Kí ń tó sọ̀rọ̀ tán+ nínú ọkàn-àyà+ mi, họ́wù, Rèbékà rèé tí ń jáde bọ̀, pẹ̀lú ìṣà rẹ̀ lórí èjìká rẹ̀; ó sì sọ̀ kalẹ̀ lọ ní ọ̀nà rẹ̀ síbi ìsun omi náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fa omi.+ Nígbà náà ni mo wí fún un pé, ‘Jọ̀wọ́, fún mi lómi mu.’+ 46  Nítorí náà, ó yára sọ ìṣà rẹ̀ kalẹ̀ kúrò lórí, ó sì wí pé, ‘Mu omi,+ èmi yóò sì tún fi omi fún àwọn ràkúnmí rẹ.’ Nígbà náà ni mo mu omi, ó sì tún fi omi fún àwọn ràkúnmí náà. 47  Lẹ́yìn ìyẹn, mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, mo sì wí pé, ‘Ọmọbìnrin ta ni ìwọ?’+ ó dáhùn pé, ‘Ọmọbìnrin Bẹ́túélì, ọmọkùnrin Náhórì, tí Mílíkà bí fún un.’ Nítorí náà, mo fi òrùka imú náà sí imú rẹ̀ àti júfù náà sí ọwọ́ rẹ̀.+ 48  Mo sì ń bá a lọ láti tẹrí ba, mo sì wólẹ̀ níwájú Jèhófà, mo sì fi ìbùkún fún Jèhófà, Ọlọ́run ọ̀gá mi Ábúráhámù,+ ẹni tí ó ṣamọ̀nà mi ní ọ̀nà+ tòótọ́ láti mú ọmọbìnrin arákùnrin ọ̀gá mi fún ọmọkùnrin rẹ̀. 49  Wàyí o, bí ẹ̀yín yóò bá sì lo inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ìṣeégbẹ́kẹ̀lé sí ọ̀gá+ mi ní ti gidi, ẹ sọ fún mi; ṣùgbọ́n bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ sọ fún mi, kí n lè yíjú sí ọwọ́ ọ̀tún tàbí sí òsì.”+ 50  Nígbà náà ni Lábánì àti Bẹ́túélì dáhùn wọ́n sì wí pé: “Láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni nǹkan yìí ti wá.+ Àwa kò lè sọ búburú tàbí rere fún ọ.+ 51  Rèbékà nìyí níwájú rẹ. Máa mú un lọ, sì jẹ́ kí ó di aya fún ọmọkùnrin ọ̀gá rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe sọ.”+ 52  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí ìránṣẹ́ Ábúráhámù gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, lójú-ẹsẹ̀, ó wólẹ̀ sórí ilẹ̀ níwájú Jèhófà.+ 53  Ìránṣẹ́ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ohun èlò fàdákà àti àwọn ohun èlò wúrà àti àwọn ẹ̀wù jáde, ó sì fi wọ́n fún Rèbékà; ó sì fi àwọn ohun ààyò fún arákùnrin rẹ̀ àti ìyá rẹ̀.+ 54  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu, òun àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì sùn mọ́jú níbẹ̀, wọ́n sì dìde ní òwúrọ̀. Nígbà náà ni ó wí pé: “Ẹ rán mi lọ sọ́dọ̀ ọ̀gá+ mi.” 55  Arákùnrin rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ wí pé: “Jẹ́ kí ọ̀dọ́bìnrin náà wà pẹ̀lú wa ó kéré tán fún ọjọ́ mẹ́wàá. Lẹ́yìn náà, ó lè máa lọ.” 56  Ṣùgbọ́n ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe dá mi dúró, ní rírí i pé Jèhófà ti mú kí n ní àṣeyọrí sí rere ní ọ̀nà+ mi. Ẹ rán mi lọ, kí n lè lọ sọ́dọ̀ ọ̀gá+ mi.” 57  Nítorí náà, wọ́n sọ pé: “Jẹ́ kí a pe ọ̀dọ́bìnrin náà kí a sì wádìí lẹ́nu+ rẹ̀.” 58  Nígbà náà ni wọ́n pe Rèbékà tí wọ́n sì wí fún un pé: “Ìwọ yóò ha bá ọkùnrin yìí lọ bí?” Ẹ̀wẹ̀, ó wí pé: “Mo múra tán láti lọ.”+ 59  Látàrí ìyẹn, wọ́n rán Rèbékà+ arábìnrin wọn lọ àti olùṣètọ́jú+ rẹ̀ àti ìránṣẹ́ Ábúráhámù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀. 60  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún Rèbékà, wọ́n sì wí fún un pé: “Kí ìwọ, arábìnrin wa, di ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá, kí irú-ọmọ rẹ̀ sì gba ẹnubodè àwọn tí ó kórìíra rẹ̀.”+ 61  Lẹ́yìn ìyẹn, Rèbékà àti àwọn ẹmẹ̀wà+ rẹ̀ obìnrin dìde, wọ́n sì ń gun àwọn ràkúnmí+ lọ, wọ́n sì ń tẹ̀ lé ọkùnrin náà; ìránṣẹ́ náà sì mú Rèbékà, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n. 62  Wàyí o, ọ̀nà tí ó lọ sí Bia-laháí-róì+ ni Ísákì gbà wá, nítorí ó ń gbé ní ilẹ̀ Négébù.+ 63  Ísákì sì ń rìn níta kí ó lè ṣe àṣàrò+ nínú pápá nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú lọ ní ìrọ̀lẹ́. Nígbà tí ó gbé ojú rẹ̀ sókè tí ó sì wò, họ́wù, àwọn ràkúnmí ń bọ̀! 64  Nígbà tí Rèbékà gbé ojú rẹ̀ sókè, ó tajú kán rí Ísákì, ó sì tọ sílẹ̀ láti orí ràkúnmí. 65  Nígbà náà ni ó sọ fún ìránṣẹ́ náà pé: “Ta ni ọkùnrin yẹn tí ó wà lọ́hùn-ún, tí ń rìn nínú pápá láti pàdé wa?” ìránṣẹ́ náà sì sọ pé: “Ọ̀gá mi ni.” Obìnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí mú aṣọ ìwérí, ó sì bo ara rẹ̀.+ 66  Ìránṣẹ́ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣèròyìn fún Ísákì nípa gbogbo ohun tí òun ti ṣe. 67  Lẹ́yìn ìyẹn, Ísákì mú obìnrin náà wọ inú àgọ́ Sárà ìyá+ rẹ̀. Nípa báyìí, ó mú Rèbékà, ó sì di aya+ rẹ̀; ó sì kó sínú ìfẹ́ fún obìnrin náà,+ Ísákì sì rí ìtùnú lẹ́yìn tí ó ti pàdánù ìyá+ rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé