Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 22:1-24

22  Wàyí o, lẹ́yìn àwọn nǹkan wọ̀nyí, ó ṣẹlẹ̀ pé Ọlọ́run tòótọ́ dán Ábúráhámù wò.+ Nítorí náà, ó wí fún un pé: “Ábúráhámù!” ó dáhùn pé: “Èmi nìyí!”+  Ó sì ń bá a lọ láti wí pé: “Jọ̀wọ́, mú ọmọkùnrin rẹ, ọmọkùnrin rẹ kan ṣoṣo tí o nífẹ̀ẹ́+ gidigidi, Ísákì,+ kí o sì rìnnà àjò lọ sí ilẹ̀ Móráyà,+ kí o sì fi í rúbọ níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè ńlá tí èmi yóò tọ́ka sí fún ọ.”+  Nítorí náà, Ábúráhámù dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì mú méjì nínú àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ àti Ísákì ọmọkùnrin rẹ̀;+ ó sì la igi fún ọrẹ ẹbọ sísun náà. Lẹ́yìn náà, ó dìde, ó sì rìnnà àjò lọ sí ibi tí Ọlọ́run tòótọ́ tọ́ka sí fún un.  Ọjọ́ kẹta ni ìgbà àkọ́kọ́ tí Ábúráhámù gbé ojú rẹ̀ sókè tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rí ibẹ̀ láti òkèèrè.  Wàyí o, Ábúráhámù sọ fún àwọn ẹmẹ̀wà+ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ẹ dúró síhìn-ín ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ṣùgbọ́n èmi àti ọmọdékùnrin náà fẹ́ tẹ̀ síwájú lọ sí ọ̀hún yẹn láti jọ́sìn+ kí a sì padà wá bá yín.”  Lẹ́yìn ìyẹn, Ábúráhámù mú igi ọrẹ ẹbọ sísun náà, ó sì gbé e sórí Ísákì ọmọkùnrin rẹ̀,+ ó sì mú iná àti ọ̀bẹ ìpẹran lọ́wọ́, àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ lọ.+  Ísákì sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún Ábúráhámù baba rẹ̀ pé: “Baba mi!”+ Òun ẹ̀wẹ̀ sì wí pé: “Èmi nìyí, ọmọkùnrin mi!”+ Nítorí náà, ó ń bá a lọ pé: “Iná àti igi rèé, ṣùgbọ́n ibo ni àgùntàn fún ọrẹ ẹbọ sísun wà?”+  Ábúráhámù fèsì pé: “Ọlọ́run yóò pèsè àgùntàn ọrẹ ẹbọ sísun+ náà fúnra rẹ̀, ọmọkùnrin mi.” Àwọn méjèèjì sì jọ ń rìn lọ.  Níkẹyìn, wọ́n dé ibi tí Ọlọ́run tòótọ́ tọ́ka sí fún un, Ábúráhámù sì mọ pẹpẹ+ kan síbẹ̀, ó sì to igi, ó sì de Ísákì ọmọkùnrin rẹ̀ tọwọ́ tẹsẹ̀, ó sì gbé e lé pẹpẹ náà lórí igi.+ 10  Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì mú ọ̀bẹ ìpẹran láti pa ọmọkùnrin rẹ̀.+ 11  Ṣùgbọ́n áńgẹ́lì Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí pè é láti ọ̀run, ó sì wí pé:+ “Ábúráhámù, Ábúráhámù!” ó sì dáhùn pé: “Èmi nìyí!” 12  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Má ṣe na ọwọ́ rẹ jáde lòdì sí ọmọdékùnrin náà, má sì ṣe ohunkóhun sí i rárá,+ nítorí nísinsìnyí ni mo mọ̀ pé olùbẹ̀rù Ọlọ́run ni ìwọ ní ti pé ìwọ kò fawọ́ ọmọkùnrin rẹ, ọ̀kan ṣoṣo tí o ní, sẹ́yìn fún mi.”+ 13  Látàrí ìyẹn, Ábúráhámù gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wò, sì kíyè sí i, ní ọ̀kánkán iwájú rẹ̀, ni àgbò kan wà tí ìwo rẹ̀ há sínú ìgbòrò. Nítorí náà, Ábúráhámù lọ, ó sì mú àgbò náà, ó sì fi í rú ọrẹ ẹbọ sísun dípò ọmọkùnrin rẹ̀.+ 14  Ábúráhámù sì bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ ibẹ̀ ní Jèhófá-jirè. Ìdí nìyí tí a fi ń sọ ọ́ lọ́nà àṣà lónìí pé: “Òkè ńlá Jèhófà ni a ó ti pèsè rẹ̀.”+ 15  Áńgẹ́lì Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí pe Ábúráhámù ní ìgbà kejì láti ọ̀run 16  ó sì wí pé: “‘Mo fi ara mi búra,’ ni àsọjáde Jèhófà,+ ‘pé nítorí òtítọ́ náà pé o ṣe nǹkan yìí, tí ìwọ kò sì fawọ́ ọmọkùnrin rẹ sẹ́yìn, ọ̀kan ṣoṣo tí o ní,+ 17  èmi yóò bù kún ọ dájúdájú, èmi yóò sì sọ irú-ọmọ rẹ di púpọ̀ dájúdájú bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun;+ irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnubodè àwọn ọ̀tá rẹ̀.+ 18  Nípasẹ̀ irú-ọmọ+ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ ti fetí sí ohùn mi.’”+ 19  Lẹ́yìn ìyẹn, Ábúráhámù padà sọ́dọ̀ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, wọ́n sì dìde, wọ́n sì bá ọ̀nà wọn lọ pa pọ̀ sí Bíá-ṣébà;+ Ábúráhámù sì ń bá a lọ láti gbé ní Bíá-ṣébà. 20  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn àwọn nǹkan wọ̀nyí pé ìròyìn dé ọ̀dọ̀ Ábúráhámù pé: “Kíyè sí i, Mílíkà+ alára ti tún bí àwọn ọmọ fún Náhórì+ arákùnrin rẹ: 21  Úsì àkọ́bí rẹ̀ àti Búsì+ arákùnrin rẹ̀ àti Kémúélì baba Árámù, 22  àti Késédì àti Hásò àti Pílídáṣì àti Jídíláfù àti Bẹ́túélì.”+ 23  Bẹ́túélì sì bí Rèbékà.+ Àwọn mẹ́jọ wọ̀nyí ni Mílíkà bí fún Náhórì arákùnrin Ábúráhámù. 24  Wáhàrì rẹ̀ tún wà, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Réúmà. Nígbà tí ó ṣe, òun náà tún bí Tébà àti Gáhámù àti Táháṣì àti Máákà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé