Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 21:1-34

21  Jèhófà sì yí àfiyèsí rẹ̀ sí Sárà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ gan-an, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ+ gan-an ni ó wá ṣe fún Sárà.  Sárà sì lóyún,+ ó sì wá bí ọmọkùnrin kan fún Ábúráhámù ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ní àkókò tí a yàn kalẹ̀ nípa èyí tí Ọlọ́run ti sọ fún un.+  Nítorí náà, Ábúráhámù pe orúkọ ọmọkùnrin rẹ̀ tí a bí fún un, ẹni tí Sárà bí fún un ní Ísákì.+  Ábúráhámù sì tẹ̀ síwájú láti dádọ̀dọ́ Ísákì ọmọkùnrin rẹ̀ nígbà tí ó pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe pàṣẹ fún un+ gan-an.  Ábúráhámù sì jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún nígbà tí a bí Ísákì ọmọkùnrin rẹ̀ fún un.  Nígbà náà ni Sárà wí pé: “Ọlọ́run ti pèsè ẹ̀rín sílẹ̀ fún mi: gbogbo ènìyàn tí yóò gbọ́ nípa rẹ̀ yóò fi mí rẹ́rìn-ín.”+  Ó sì fi kún un pé: “Ta ni ì bá ti sọ jáde fún Ábúráhámù pé, ‘Dájúdájú, Sárà yóò fún àwọn ọmọ lọ́mú,’ ṣùgbọ́n mo ti bí ọmọkùnrin kan ní ọjọ́ ogbó rẹ̀?”  Wàyí o, ọmọ náà ń dàgbà, a sì já a lẹ́nu ọmú; lẹ́yìn náà, Ábúráhámù se àsè ńlá ní ọjọ́ tí a já Ísákì lẹ́nu ọmú.+  Sárà sì ń kíyè sí ọmọkùnrin Hágárì ará Íjíbítì náà,+ tí ó bí fún Ábúráhámù, tí ó ń dá àpárá.+ 10  Nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Ábúráhámù pé: “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọkùnrin rẹ̀ jáde, nítorí ọmọkùnrin ẹrúbìnrin yìí kò ní jẹ́ ajogún pẹ̀lú ọmọkùnrin mi, pẹ̀lú Ísákì!”+ 11  Ṣùgbọ́n ohun náà kò dùn mọ́ Ábúráhámù nínú rárá, ní ti ọmọkùnrin rẹ̀.+ 12  Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run wí fún Ábúráhámù pé: “Má ṣe jẹ́ kí ohun tí Sárà ń sọ fún ọ di ohun tí kò dùn mọ́ ọ nínú nípa ọmọdékùnrin náà àti nípa ẹrúbìnrin rẹ. Fetí sí ohùn rẹ̀, nítorí pé nípasẹ̀ Ísákì ni ohun tí a ó pè ní irú-ọmọ rẹ yóò wà.+ 13  Àti ní ti ọmọkùnrin ẹrúbìnrin náà,+ èmi pẹ̀lú yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè, nítorí pé ọmọ+ tí ó jẹ́ tìrẹ ni òun.” 14  Nítorí náà, Ábúráhámù dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì gbé oúnjẹ àti ìgò omi tí a fi awọ ṣe, ó sì fi í fún Hágárì,+ ní gbígbé e lé èjìká rẹ̀, àti ọmọ náà,+ ó sì rán an lọ lẹ́yìn náà. Òun sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó sì ń rìn káàkiri nínú aginjù Bíá-ṣébà.+ 15  Níkẹyìn, omi náà tán pátápátá+ nínú ìgò awọ náà, ó sì sọ+ ọmọ náà sábẹ́ ọ̀kan nínú àwọn igi kékeré. 16  Lẹ́yìn náà, ó sì lọ dá jókòó, ní nǹkan bí ìrìnjìnnà ìtafàsí, nítorí tí ó sọ pé: “Kí n má ṣe rí i nígbà tí ọmọ náà yóò kú.”+ Nítorí náà, ó jókòó ní òkèèrè, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ohùn rẹ̀ sókè ó sì ń sunkún.+ 17  Látàrí èyí, Ọlọ́run gbọ́ ohùn ọmọdékùnrin náà,+ áńgẹ́lì Ọlọ́run sì pe Hágárì láti ọ̀run wá, ó sì wí fún un+ pé: “Kí ní ń ṣe ọ́, Hágárì? Má fòyà, nítorí pé Ọlọ́run ti fetí sí ohùn ọmọdékùnrin náà níbi tí ó wà yẹn. 18  Dìde, gbé ọmọdékùnrin náà nílẹ̀ kí o sì fi ọwọ́ rẹ dì í mú, nítorí tí èmi yóò sọ òun di orílẹ̀-èdè ńlá.”+ 19  Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run la ojú rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé ó tajú kán rí kànga omi kan;+ ó sì lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ omi kún ìgò awọ náà, ó sì fi omi fún ọmọdékùnrin náà mu. 20  Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wà pẹ̀lú ọmọdékùnrin náà,+ ó sì ń dàgbà, ó sì ń gbé nínú aginjù; ó sì di tafàtafà.+ 21  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé nínú aginjù Páránì,+ ìyá rẹ̀ sì tẹ̀ síwájú láti mú aya fún un láti ilẹ̀ Íjíbítì. 22  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní àkókò yẹn pé Ábímélékì pa pọ̀ pẹ̀lú Fíkólì olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ sọ fún Ábúráhámù pé: “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ nínú ohun gbogbo tí ìwọ ń ṣe.+ 23  Ǹjẹ́ nísinsìnyí, fi Ọlọ́run+ búra fún mi nísinsìnyí níhìn-ín, pé ìwọ kì yóò já sí èké fún èmi àti àwọn ọmọ mi àti fún ìran àtẹ̀lé+ tí ó jẹ́ tèmi; pé, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ dídúró ṣinṣin tí mo ti fi bá ọ lò,+ ni ìwọ yóò bá èmi àti ilẹ̀ lórí èyí tí ìwọ ti ń ṣe àtìpó+ lò.” 24  Nítorí náà, Ábúráhámù sọ pé: “Èmi yóò búra.”+ 25  Nígbà tí Ábúráhámù fi àṣìṣe Ábímélékì hàn lọ́nà mímúná janjan ní ti kànga omi tí àwọn ìránṣẹ́ Ábímélékì fi ipá+ gbà, 26  nígbà náà ni Ábímélékì wí pé: “Èmi kò mọ ẹni tí ó ṣe nǹkan yìí, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ alára kò sọ ọ́ fún mi, èmi alára pẹ̀lú kò tíì gbọ́ nípa rẹ̀ bí kò ṣe lónìí.”+ 27  Pẹ̀lú ìyẹn, Ábúráhámù mú àgùntàn àti màlúù, ó sì fi wọ́n fún Ábímélékì,+ àwọn méjèèjì sì tẹ̀ síwájú láti dá májẹ̀mú.+ 28  Nígbà tí Ábúráhámù ya abo ọ̀dọ́ àgùntàn méje sọ́tọ̀ ní àwọn nìkan nínú agbo ẹran, 29  Ábímélékì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Ábúráhámù pé: “Kí ni ìtumọ̀ àwọn abo ọ̀dọ́ àgùntàn méje wọ̀nyí tí o yà sọ́tọ̀ ní àwọn nìkan yìí?” 30  Nígbà náà ni ó wí pé: “Ó yẹ kí o gba abo ọ̀dọ́ àgùntàn méje náà lọ́wọ́ mi, kí ó lè jẹ́ ẹ̀rí+ fún mi pé èmi ni ó gbẹ́ kànga yìí.” 31  Ìdí nìyẹn tí ó fi pe ibẹ̀ ní Bíá-ṣébà,+ nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn méjèèjì ti búra. 32  Nítorí náà, wọ́n dá májẹ̀mú+ ní Bíá-ṣébà, lẹ́yìn èyí tí Ábímélékì dìde pa pọ̀ pẹ̀lú Fíkólì olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sì padà sí ilẹ̀ àwọn Filísínì.+ 33  Lẹ́yìn ìyẹn, ó gbin igi támáríkì kan sí Bíá-ṣébà, ó sì pe orúkọ Jèhófà+ níbẹ̀, Ọlọ́run tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 34  Ábúráhámù sì mú ọjọ́ tí ó fi ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àwọn Filísínì gùn sí i.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé