Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 19:1-38

19  Wàyí o, àwọn áńgẹ́lì méjì náà dé Sódómù ní alẹ́, Lọ́ọ̀tì sì jókòó ní ẹnubodè Sódómù.+ Nígbà tí Lọ́ọ̀tì tajú kán rí wọn, nígbà náà ni ó dìde láti pàdé wọn, ó sì dojú bolẹ̀.+  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ẹ jọ̀wọ́, nísinsìnyí, ẹ̀yin olúwa mi, ẹ jọ̀wọ́, ẹ yà sínú ilé ìránṣẹ́ yín, kí ẹ sì sùn mọ́jú, kí a sì wẹ ẹsẹ̀ yín.+ Lẹ́yìn náà kí ẹ dìde ní kùtùkùtù kí ẹ sì máa rin ìrìn àjò lọ ní ọ̀nà yín.”+ Wọ́n fèsì pé: “Rárá, ṣùgbọ́n ojúde ìlú ni ibi tí àwa yóò sùn mọ́jú.”+  Ṣùgbọ́n ó fi dandan lé e fún wọn,+ tí ó fi jẹ́ pé wọ́n yà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì wá sínú ilé rẹ̀. Ó sì se àsè fún wọn,+ ó sì yan àkàrà aláìwú,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹun.  Kí wọ́n tó dùbúlẹ̀, àwọn ọkùnrin ìlú ńlá náà, àwọn ọkùnrin Sódómù yí ilé náà ká,+ láti orí ọmọdékùnrin dórí àgbà ọkùnrin, gbogbo àwọn ènìyàn náà ní ìwọ́jọpọ̀ kan.+  Wọ́n sì ń bá a nìṣó láti nahùn pe Lọ́ọ̀tì, ní wíwí fún un pé: “Ibo ni àwọn ọkùnrin tí wọ́n wọlé wá bá ọ ní alẹ́ yìí wà? Mú wọn jáde fún wa kí a lè ní ìbádàpọ̀ pẹ̀lú wọn.”+  Níkẹyìn, Lọ́ọ̀tì jáde lọ bá wọn ní ẹnu ọ̀nà, ṣùgbọ́n ó ti ilẹ̀kùn lẹ́yìn tí ó jáde.  Nígbà náà ni ó wí pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ má ṣe hùwà búburú.+  Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kíyè sí i, àwọn ọmọbìnrin méjì ni mo ní tí wọn kò tíì ní ìbádàpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin rí.+ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n mú wọn jáde fún yín. Nígbà náà kí ẹ ṣe sí wọn bí ó bá ti dára ní ojú yín.+ Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí nìkan ni kí ẹ má ṣe ohunkóhun sí,+ ìdí rẹ̀ nìyẹn tí wọ́n fi wá sábẹ́ òjìji òrùlé mi.”+  Látàrí èyí, wọ́n wí pé: “Bìlà!” Wọ́n sì fi kún un pé: “Ọkùnrin anìkànjẹ̀ yìí wá ṣe àtìpó,+ síbẹ̀, òun ní ti gidi ń ṣe bí onídàájọ́.+ Nísinsìnyí, búburú tí àwa yóò ṣe sí ọ yóò ju tiwọn lọ.” Wọ́n sì rọ́lu ọkùnrin náà,+ Lọ́ọ̀tì, wọ́n sì sún mọ́ àtifọ́ ilẹ̀kùn wọlé.+ 10  Nítorí náà, àwọn ọkùnrin náà na ọwọ́ wọn jáde, wọ́n sì mú Lọ́ọ̀tì wọlé sọ́dọ̀ wọn nínú ilé, wọ́n sì ti ilẹ̀kùn. 11  Ṣùgbọ́n wọ́n bu ìfọ́jú lu àwọn ọkùnrin tí wọ́n wà ní ẹnu ọ̀nà ilé náà,+ láti orí ẹni tí ó kéré jù lọ dórí ẹni tí ó tóbi jù lọ,+ tí ó fi jẹ́ pé wọ́n ń dá ara wọn lágara ní gbígbìyànjú láti rí ẹnu ọ̀nà.+ 12  Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà wí fún Lọ́ọ̀tì pé: “Ǹjẹ́ o ní ẹnikẹ́ni mìíràn níhìn-ín? Ọkọ ọmọ rẹ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ àti gbogbo àwọn tí ó jẹ́ tìrẹ nínú ìlú ńlá yìí, ni kí o mú jáde kúrò ní ibí yìí!+ 13  Nítorí àwa yóò run ibí yìí, nítorí tí igbe ẹkún lòdì sí wọn ti ròkè lálá síwájú Jèhófà,+ tó bẹ́ẹ̀ tí Jèhófà fi rán wa láti run+ ìlú ńlá yìí.” 14  Fún ìdí yìí, Lọ́ọ̀tì jáde lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọkọ ọmọ rẹ̀ tí wọ́n fẹ́ mú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ṣe aya sọ̀rọ̀, ó sì ń bá a nìṣó ní wíwí pé: “Ẹ dìde! Ẹ jáde kúrò ní ibí yìí, nítorí pé Jèhófà yóò run+ ìlú ńlá yìí!” Ṣùgbọ́n ní ojú àwọn ọkọ ọmọ rẹ̀, ó dà bí ọkùnrin tí ń ṣàwàdà.+ 15  Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ọ̀yẹ̀ là, ìgbà náà ni àwọn áńgẹ́lì náà bẹ̀rẹ̀ sí kán Lọ́ọ̀tì lójú, pé: “Dìde! mú aya rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì tí a rí níhìn-ín,+ kí a má bàa gbá yín lọ nínú ìṣìnà ìlú ńlá yìí!”+ 16  Nígbà tí ó ń lọ́ra ṣáá,+ nígbà náà, nínú ìyọ́nú Jèhófà lórí rẹ̀,+ àwọn ọkùnrin náà gbá ọwọ́ rẹ̀ àti ọwọ́ aya rẹ̀ àti ọwọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì mú, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti mú un jáde àti láti mú un dúró ní òde ìlú ńlá náà.+ 17  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí wọ́n ti mú wọn jáde sí ẹ̀yìn odi, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Sá àsálà fún ọkàn rẹ!+ Má ṣe wo ẹ̀yìn rẹ,+ má sì ṣe dúró jẹ́ẹ́ ní gbogbo Àgbègbè yìí!+ Sá lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá kí a má bàa gbá ọ lọ!”+ 18  Nígbà náà ni Lọ́ọ̀tì wí fún wọn pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, jọ̀wọ́, Jèhófà! 19  Jọ̀wọ́, nísinsìnyí, tí ìránṣẹ́ rẹ ti rí ojú rere ní ojú rẹ,+ tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ fi ń gbé inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́+ ga lọ́lá, èyí tí o ti ṣe sí mi láti pa ọkàn mi mọ́ láàyè,+ ṣùgbọ́n èmi—èmi kò lè sá lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá kí ìyọnu àjálù má bàa sún mọ́ mi kí èmi sì kú.+ 20  Jọ̀wọ́, nísinsìnyí, ìlú ńlá yìí wà nítòsí láti sá lọ síbẹ̀, ó sì jẹ́ ohun kékeré.+ Jọ̀wọ́, ṣé kí n sá lọ síbẹ̀—kì í ha ṣe ohun kékeré ni?—ọkàn mi yóò sì máa bá a nìṣó láti wà láàyè.”+ 21  Nítorí náà, ó wí fún un pé: “Kíyè sí i, mo fi ìgbatẹnirò hàn sí ọ dé ìwọ̀n yìí pẹ̀lú,+ ní ti pé èmi kò ní bi ìlú ńlá náà tí ìwọ ti sọ ṣubú.+ 22  Ṣe wéré! Sá lọ síbẹ̀ nítorí pé èmi kò lè ṣe ohun kan títí tí ìwọ yóò fi dé ibẹ̀!”+ Ìdí nìyẹn tí ó fi pe orúkọ ìlú ńlá náà ní Sóárì.+ 23  Oòrùn ti yọ sórí ilẹ̀ nígbà tí Lọ́ọ̀tì dé Sóárì.+ 24  Nígbà náà ni Jèhófà mú kí òjò imí ọjọ́ àti iná rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, láti ọ̀run, sórí Sódómù àti sórí Gòmórà.+ 25  Nítorí náà, ó ń bá a lọ láti bi àwọn ìlú ńlá wọ̀nyí ṣubú, àní gbogbo Àgbègbè náà pátá àti gbogbo àwọn olùgbé ìlú ńlá náà àti àwọn ọ̀gbìn ilẹ̀ náà.+ 26  Aya rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí wò yí ká lẹ́yìn rẹ̀, ó sì di ọwọ̀n iyọ̀.+ 27  Wàyí o, Ábúráhámù bá ọ̀nà rẹ̀ lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀ sí ibi tí ó ti dúró níwájú Jèhófà.+ 28  Lẹ́yìn náà, ó bojú wo ìsàlẹ̀ síhà Sódómù àti Gòmórà àti gbogbo ilẹ̀ Àgbègbè náà, ó sì rí ìran kan. Họ́wù, kíyè sí i, èéfín nínípọn gòkè láti ilẹ̀ náà wá bí èéfín nínípọn ẹbu!+ 29  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Ọlọ́run run àwọn ìlú ńlá Àgbègbè náà, Ọlọ́run fi Ábúráhámù sọ́kàn ní ti pé ó gbé ìgbésẹ̀ láti rán Lọ́ọ̀tì jáde kúrò ní àárín ìbìṣubú náà nígbà tí ó ń bi àwọn ìlú ńlá náà tí Lọ́ọ̀tì ń gbé láàárín rẹ̀ ṣubú.+ 30  Níkẹyìn, Lọ́ọ̀tì gòkè lọ kúrò ní Sóárì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá, àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì pẹ̀lú rẹ̀,+ nítorí tí ó fòyà àtigbé ní Sóárì.+ Nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbé nínú hòrò, òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì. 31  Èyí àkọ́bí sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún èyí àbúrò pé: “Baba wa ti darúgbó, kò sì sí ọkùnrin kankan ní ilẹ̀ yìí láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wa ní gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ti gbogbo ilẹ̀ ayé.+ 32  Wá, jẹ́ kí a fún baba wa ní wáìnì mu+ kí o sì jẹ́ kí a sùn tì í kí a sì mú kí irú-ọmọ máa wà nìṣó láti ọ̀dọ̀ baba wa.”+ 33  Nítorí náà, wọ́n ń fún baba wọn ní wáìnì mu ṣáá ní òru yẹn;+ nígbà náà ni èyí àkọ́bí wọlé lọ, ó sì sùn ti baba rẹ̀, ṣùgbọ́n òun kò mọ ìgbà tí ó sùn ti òun àti ìgbà tí ó dìde. 34  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kejì pé èyí àkọ́bí sọ fún èyí àbúrò pé: “Kíyè sí i, mo sùn ti baba mi ní òru àná. Jẹ́ kí a fún un ní wáìnì mu ní òru òní pẹ̀lú. Nígbà náà, kí ìwọ wọlé lọ, kí o sùn tì í, kí o sì jẹ́ kí a pa ọmọ mọ́ láti ọ̀dọ̀ baba wa.” 35  Nítorí náà, wọ́n fún baba wọn ní wáìnì mu léraléra ní òru yẹn pẹ̀lú; lẹ́yìn náà, èyí àbúrò dìde, ó sì sùn tì í, ṣùgbọ́n òun kò mọ ìgbà tí ó sùn ti òun àti ìgbà tí ó dìde. 36  Àwọn ọmọbìnrin Lọ́ọ̀tì méjèèjì sì lóyún láti ọ̀dọ̀ baba wọn.+ 37  Nígbà tí ó ṣe, èyí àkọ́bí bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Móábù.+ Òun ni baba Móábù, títí di òní yìí.+ 38  Ní ti èyí àbúrò, òun pẹ̀lú bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bẹni-ámì. Òun ni baba àwọn ọmọ Ámónì,+ títí di òní yìí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé