Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́nẹ́sísì 17:1-27

17  Nígbà tí Ábúrámù di ẹni ọdún mọ́kàn-dín-lọ́gọ́rùn-ún, ìgbà náà ni Jèhófà fara han Ábúrámù tí ó sì wí fún un pé:+ “Èmi ni Ọlọ́run Olódùmarè.+ Máa rìn níwájú mi kí o sì fi ara rẹ hàn ní aláìní-àléébù.+  Èmi yóò sì fi májẹ̀mú mi sáàárín èmi àti ìwọ,+ kí n lè sọ ọ́ di púpọ̀ gidi gan-an.”+  Látàrí èyí, Ábúrámù dojú bolẹ̀,+ Ọlọ́run sì ń ba á lọ láti bá a sọ̀rọ̀ pé:  “Ní tèmi, wò ó! májẹ̀mú mi wà pẹ̀lú rẹ,+ ìwọ yóò sì di baba ogunlọ́gọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.+  Orúkọ rẹ ni a kì yóò sì pè ní Ábúrámù mọ́, orúkọ rẹ yóò sì di Ábúráhámù, nítorí baba ogunlọ́gọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ni èmi yóò ṣe ọ́.  Èmi yóò sì mú ọ so èso gidigidi, èmi yóò sì sọ ọ́ di àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ọba yóò sì ti inú rẹ jáde wá.+  “Èmi yóò sì mú májẹ̀mú mi ṣẹ láàárín èmi àti ìwọ+ àti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ, ní ìbámu pẹ̀lú ìran-ìran wọn fún májẹ̀mú fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ láti fi ara mi hàn ní Ọlọ́run fún ọ àti fún irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ.+  Èmi yóò sì fi àwọn ilẹ tí o ti ṣe àtìpó+ fún ìwọ àti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ, àní gbogbo ilẹ̀ Kénáánì pátá, gẹ́gẹ́ bí ohun ìní fún àkókò tí ó lọ kánrin; èmi yóò sì fi ara mi hàn ní Ọlọ́run fún wọn.”+  Ọlọ́run sì wí fún Ábúráhámù síwájú sí i pé: “Ní tìrẹ, kí o pa májẹ̀mú mi mọ́, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ, ní ìbámu pẹ̀lú ìran-ìran wọn.+ 10  Èyí ni májẹ̀mú mi tí ẹ̀yin yóò pa mọ́, láàárín èmi àti ẹ̀yin, àní irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ:+ Gbogbo tiyín tí ó jẹ́ ọkùnrin ni a gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́ wọn.+ 11  Kí a sì dá adọ̀dọ́ yín, kí ó sì jẹ́ àmì májẹ̀mú láàárín èmi àti ẹ̀yin.+ 12  Gbogbo ọmọkùnrin yín ní ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ ni kí a dádọ̀dọ́ fún,+ ní ìbámu pẹ̀lú ìran-ìran yín, ẹnikẹ́ni tí a bí ní ilé àti ẹnikẹ́ni tí a fi owó rà láti ọwọ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè èyíkéyìí tí kì í ṣe láti inú irú-ọmọ rẹ. 13  Gbogbo ọkùnrin tí a bí ní ilé rẹ àti gbogbo ọkùnrin tí a fi owó rẹ rà ni kí a dádọ̀dọ́ wọn láìkùnà;+ kí májẹ̀mú mi tí ó wà ní ẹran ara yín sì jẹ́ májẹ̀mú kan fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 14  Ọkùnrin aláìdádọ̀dọ́ tí kì yóò dá adọ̀dọ́ rẹ̀, àní ọkàn yẹn ni kí a ké kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.+ Ó ti da májẹ̀mú mi.” 15  Ọlọ́run sì ń ba á lọ láti wí fún Ábúráhámù pé: “Ní ti Sáráì aya rẹ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ pe orúkọ rẹ̀ ní Sáráì, nítorí pé Sárà ni orúkọ rẹ̀.+ 16  Èmi yóò sì bù kún un, èmi yóò sì tún fi ọmọkùnrin kan fún ọ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀;+ èmi yóò sì bù kún un, òun ó sì di àwọn orílẹ̀-èdè;+ àwọn ọba àwọn ènìyàn yóò sì wá láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.”+ 17  Látàrí èyí, Ábúráhámù dojú bolẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rẹ́rìn-ín, ó sì ń wí nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé:+ “Ọkùnrin ọgọ́rùn-ún ọdún yóò ha bí ọmọ, àti Sárà, bẹ́ẹ̀ ni, obìnrin àádọ́rùn-ún ọdún yóò ha bímọ bí?”+ 18  Lẹ́yìn ìyẹn, Ábúráhámù sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Kí Íṣímáẹ́lì wà láàyè níwájú rẹ!”+ 19  Ọlọ́run fèsì pé: “Sárà aya rẹ yóò bí ọmọkùnrin kan fún ọ ní tòótọ́, kí ìwọ sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ísákì.+ Èmi yóò sì fìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ fún májẹ̀mú kan fún àkókò tí ó lọ kánrin fún irú-ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.+ 20  Ṣùgbọ́n ní ti Íṣímáẹ́lì, mo ti gbọ́ ọ. Wò ó! Èmi yóò bù kún un, èmi yóò sì mú un so èso, èmi yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀ gidi gan-an.+ Dájúdájú, òun yóò mú ìjòyè méjìlá jáde, èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.+ 21  Bí ó ti wù kí ó rí, májẹ̀mú mi ni èmi yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú Ísákì,+ ẹni tí Sárà yóò bí fún ọ ní àkókò tí a yàn kalẹ̀ yìí ní ọdún tí ń bọ̀.”+ 22  Pẹ̀lú ìyẹn, Ọlọ́run parí bíbá a sọ̀rọ̀, ó sí gòkè lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ Ábúráhámù.+ 23  Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù tẹ̀ síwájú láti mú Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọkùnrin tí a bí nínú ilé rẹ̀ àti gbogbo ẹni tí a fi owó rẹ̀ rà, gbogbo ọkùnrin nínú àwọn ènìyàn agbo ilé Ábúráhámù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dá adọ̀dọ́ wọn ní ọjọ́ yìí gan-an, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀.+ 24  Ẹni ọdún mọ́kàn-dín-lọ́gọ́rùn-ún sì ni Ábúráhámù nígbà tí ó dá adọ̀dọ́ rẹ̀.+ 25  Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá nígbà tí ó dá adọ̀dọ́ rẹ̀.+ 26  Ọjọ́ yìí gan-an ni Ábúráhámù di ẹni tí a dádọ̀dọ́ rẹ̀, àti Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin rẹ̀+ pẹ̀lú. 27  Àti gbogbo ọkùnrin agbo ilé rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí a bí nínú ilé náà àti ẹnikẹ́ni tí a fi owó rà láti ọwọ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè, ni a dádọ̀dọ́ wọn pẹ̀lú rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé