Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́nẹ́sísì 16:1-16

16  Wàyí o, Sáráì, aya Ábúrámù, kò tíì bí ọmọ kankan fún un+; ṣùgbọ́n ó ní ìránṣẹ́bìnrin kan tí ó jẹ́ ará Íjíbítì, orúkọ rẹ̀ sì ni Hágárì.+  Nítorí náà, Sáráì wí fún Ábúrámù pé: “Wàyí o, jọ̀wọ́! Jèhófà ti sé mi mọ́ kúrò nínú bíbímọ.+ Jọ̀wọ́, ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìránṣẹ́bìnrin mi. Bóyá mo lè ní àwọn ọmọ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.”+ Nítorí náà, Ábúrámù fetí sí ohùn Sáráì.+  Nígbà náà ni Sáráì, aya Ábúrámù, mú Hágárì, ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ará Íjíbítì, ní òpin ọdún mẹ́wàá tí Ábúrámù fi gbé ilẹ̀ Kénáánì, ó sì fi í fún Ábúrámù ọkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aya rẹ̀.+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Hágárì, ó sì lóyún. Nígbà tí ó wá mọ̀ pé òun ti lóyún, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ obìnrin wá di ẹni ìtẹ́ńbẹ́lú ní ojú rẹ̀.+  Látàrí èyí, Sáráì wí fún Ábúrámù pé: “Kí ohun àìtọ́ tí a ṣe sí mi wà lórí rẹ. Èmi fúnra mi fi ìránṣẹ́bìnrin mi fún oókan àyà rẹ, ó sì wá mọ̀ pé òun ti lóyún, mo sì wá di ẹni ìtẹ́ńbẹ́lú ní ojú rẹ̀. Kí Jèhófà ṣe ìdájọ́ láàárín èmi àti ìwọ.”+  Nítorí náà, Ábúrámù wí fún Sáráì+ pé: “Wò ó! Ìránṣẹ́bìnrin rẹ wà ní ìkáwọ́ rẹ. Ṣe ohun tí ó bá dára ní ojú rẹ+ sí i.” Nígbà náà ni Sáráì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ ẹ lógo tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi fẹsẹ̀ fẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.+  Nígbà tí ó yá, áńgẹ́lì Jèhófà+ rí i ní ibi ìsun omi kan ní aginjù, ní ibi ìsun omi lójú ọ̀nà Ṣúrì.+  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Hágárì, ìránṣẹ́bìnrin Sáráì, ibo gan-an ni o ti ń bọ̀, ibo sì ni o ń lọ?” Ó fèsì pé: “Họ́wù, láti ọ̀dọ̀ Sáráì olúwa mi obìnrin ni mo ti fẹsẹ̀ fẹ.”  Áńgẹ́lì Jèhófà sì ń ba á lọ láti wí fún un pé: “Padà sọ́dọ̀ olúwa rẹ obìnrin kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”+ 10  Lẹ́yìn náà, áńgẹ́lì Jèhófà wí fún un pé: “Èmi yóò sọ irú-ọmọ rẹ di púpọ̀ gidigidi,+ tó bẹ́ẹ̀ tí kì yóò níye nítorí jíjẹ́ ògìdìgbó.”+ 11  Síwájú sí i, áńgẹ́lì Jèhófà fi kún un fún un pé: “Kíyè sí i, o ti lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Íṣímáẹ́lì;+ nítorí Jèhófà ti gbọ́ nípa ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ ọ níṣẹ̀ẹ́.+ 12  Ní tirẹ̀, òun yóò di ènìyàn tí ó dàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà. Ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára ẹni gbogbo, ọwọ́ ẹni gbogbo yóò sì wà lára rẹ̀;+ iwájú gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ ni òun yóò sì pàgọ́ sí.”+ 13  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ Jèhófà, ẹni tí ń bá a sọ̀rọ̀ pé: “Ìwọ ni Ọlọ́run ìrí,”+ nítorí ó sọ pé: “Èmi, níhìn-ín ní ti tòótọ́, ha ti wo ẹni tí ó rí mi bí?” 14  Ìdí nìyẹn ti a fi pe kànga náà ní Bia-laháí-róì.+ Kíyè sí i, ó wà láàárín Kádéṣì àti Bérédì. 15  Lẹ́yìn náà, Hágárì bí ọmọkùnrin kan fún Ábúrámù, Ábúrámù sì pe orúkọ ọmọkùnrin rẹ̀ tí Hágárì bí ní Íṣímáẹ́lì.+ 16  Ábúrámù sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìn-dín-láàádọ́rùn-ún ní ìgbà tí Hágárì bí Íṣímáẹ́lì fún Ábúrámù.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé