Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́nẹ́sísì 15:1-21

15  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Ábúrámù wá nínú ìran,+ pé: “Má bẹ̀rù,+ Ábúrámù. Èmi jẹ́ apata fún ọ.+ Èrè rẹ yóò pọ̀ gidigidi.”+  Látàrí èyí, Ábúrámù sọ pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, kí ni ìwọ yóò fi fún mi, bí èmi ti ń bá a lọ láìbímọ, ẹni tí yóò sì ni ilé mi ni Élíésérì,+ ọkùnrin ará Damásíkù?”  Ábúrámù sì fi kún un pé: “Wò ó! Ìwọ kò tíì fi irú-ọmọ kankan fún mi,+ sì wò ó! ọmọkùnrin+ kan nínú agbo ilé mi ni yóò rọ́pò mi gẹ́gẹ́ bí ajogún.”  Ṣùgbọ́n, wò ó! ọ̀rọ̀ Jèhófà fún un sì ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Ọkùnrin yìí kò ní rọ́pò rẹ gẹ́gẹ́ bí ajogún, ṣùgbọ́n ẹni tí yóò jáde wá láti àwọn ìhà inú ara ìwọ fúnra rẹ ni yóò rọ́pò rẹ gẹ́gẹ́ bí ajogún.”+  Wàyí o, ó mú un jáde, ó sì wí pé: “Jọ̀wọ́, gbé ojú sókè sí ọ̀run, kí o sì ka àwọn ìràwọ̀, bí ó bá lè ṣeé ṣe fún ọ láti kà wọ́n.”+ Ó sì ń bá a lọ láti wí fún un pé: “Bẹ́ẹ̀ ni irú-ọmọ rẹ yóò dà.”+  Ó sì ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà;+ òun sì bẹ̀rẹ̀ sí kà á sí òdodo fún un.+  Lẹ́yìn náà, ó fi kún un fún un pé: “Èmi ni Jèhófà, ẹni tí ó mú ọ jáde kúrò ní Úrì ti àwọn ará Kálídíà láti fi ilẹ̀ yìí fún ọ láti gbà á fi ṣe ìní.”+  Ó fèsì pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, nípa kí ni èmi yóò fi mọ̀ pé èmi yóò gbà á fi ṣe ìní?”+  Ẹ̀wẹ̀, ó sọ fún un pé: “Mú ẹgbọrọ abo màlúù kan ọlọ́dún mẹ́ta àti abo ewúrẹ́ kan ọlọ́dún mẹ́ta àti àgbò kan ọlọ́dún mẹ́ta àti oriri kan àti ọmọ ẹyẹlé+ kan wá fún mi.” 10  Nítorí náà, ó mú gbogbo ìwọ̀nyí wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì gé wọn sí méjì-méjì, ó sì mú kí apá kọ̀ọ̀kan wọn bá èkejì dọ́gba, ṣùgbọ́n àwọn ẹyẹ náà ni òun kò gé sí wẹ́wẹ́.+ 11  Àwọn ẹyẹ aṣọdẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ sórí àwọn òkú+ náà, ṣùgbọ́n Ábúrámù ń lé wọn kúrò ṣáá. 12  Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, oòrùn ń wọ̀ lọ, oorun àsùnwọra kan sì gbé Ábúrámù lọ,+ sì wò ó! òkùnkùn ńláǹlà tí ń da jìnnìjìnnì boni ṣú bò ó. 13  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún Ábúrámù pé: “Kí o mọ̀ dájú pé irú-ọmọ rẹ yóò di àtìpó ní ilẹ̀ kan tí kì í ṣe tiwọn,+ wọn yóò sì ní láti sìn wọ́n, àwọn wọ̀nyí yóò sì ṣẹ́ wọn níṣẹ̀ẹ́ dájúdájú fún irínwó ọdún.+ 14  Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè tí wọn yóò sìn ni èmi yóò dá lẹ́jọ́,+ lẹ́yìn náà, wọn yóò sì jáde kúrò pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ẹrù.+ 15  Ní tìrẹ, ìwọ yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá rẹ ní àlàáfíà; a ó sin ọ́ ní ọjọ́ ogbó gidi gan-an.+ 16  Ṣùgbọ́n ní ìran kẹrin, wọn yóò padà síhìn-ín,+ nítorí pé ìṣìnà àwọn Ámórì kò tíì parí síbẹ̀.”+ 17  Wàyí o, oòrùn ti ń wọ̀ lọ, òkùnkùn biribiri kan sì dé, sì wò ó! ìléru tí ń rú èéfín àti ògùṣọ̀ oníná tí ó kọjá láàárín àwọn ègé wọ̀nyí.+ 18  Ní ọjọ́ yẹn Jèhófà bá Ábúrámù dá májẹ̀mú+ kan, pé: “Irú-ọmọ rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún,+ láti odò Íjíbítì dé odò ńlá náà, Odò Yúfírétì:+ 19  àwọn Kénì+ àti àwọn ọmọ Kénásì àti àwọn Kádímónì 20  àti àwọn ọmọ Hétì+ àti àwọn Pérísì+ àti àwọn Réfáímù+ 21  àti àwọn Ámórì àti àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn Gẹ́gáṣì àti àwọn ará Jébúsì.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé