Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́nẹ́sísì 13:1-18

13  Lẹ́yìn ìyẹn, Ábúrámù gòkè lọ kúrò ní Íjíbítì, òun àti aya rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ní, àti Lọ́ọ̀tì pẹ̀lú rẹ̀, sí Négébù.+  Ábúrámù sì ní ọ̀pọ̀ wọ̀ǹtìwọnti ọ̀wọ́ ẹran àti fàdákà àti wúrà.+  Ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ láti ibùdó sí ibùdó jáde kúrò ní Négébù àti sí Bẹ́tẹ́lì, sí ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní àkọ́kọ́, láàárín Bẹ́tẹ́lì àti Áì,+  sí ibi pẹpẹ tí ó ti ṣe síbẹ̀ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀;+ Ábúrámù sì bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ Jèhófà níbẹ̀.+  Wàyí o, Lọ́ọ̀tì pẹ̀lú, ẹni tí ń bá Ábúrámù lọ, ní àwọn àgùntàn àti màlúù àti àwọn àgọ́.  Nítorí èyí, ilẹ̀ náà kò gba gbogbo wọn láti máa gbé pa pọ̀, nítorí pé ẹrù wọn ti di púpọ̀, gbogbo wọn kò sì lè máa gbé pa pọ̀.+  Aáwọ̀ sì dìde láàárín àwọn olùda ohun ọ̀sìn Ábúrámù àti àwọn olùda ohun ọ̀sìn Lọ́ọ̀tì; ní àkókò yẹn, àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn Pérísì sì ń gbé ní ilẹ̀ náà.+  Fún ìdí yìí, Ábúrámù sọ fún Lọ́ọ̀tì+ pé: “Jọ̀wọ́, má ṣe jẹ́ kí aáwọ̀ máa bá a lọ láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín àwọn olùṣọ́ agbo ẹran mi àti àwọn olùṣọ́ agbo ẹran rẹ, nítorí arákùnrin ni wá.+  Gbogbo ilẹ̀ kò ha wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ? Jọ̀wọ́, yà sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi. Bí ìwọ bá lọ sí apá òsì, nígbà náà, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, nígbà náà, èmi yóò lọ sí apá òsì.”+ 10  Nítorí náà, Lọ́ọ̀tì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì rí gbogbo Àgbègbè Jọ́dánì,+ pé gbogbo rẹ̀ jẹ́ ẹkùn ilẹ̀ olómi púpọ̀ kí Jèhófà tó run Sódómù àti Gòmórà, bí ọgbà Jèhófà,+ bí ilẹ̀ Íjíbítì títí dé Sóárì.+ 11  Nígbà náà, Lọ́ọ̀tì yan gbogbo Àgbègbè Jọ́dánì fún ara rẹ̀, Lọ́ọ̀tì sì ṣí ibùdó rẹ̀ lọ sí ìlà-oòrùn. Nítorí náà, wọ́n yà sọ́tọ̀, ẹnì kìíní kúrò lọ́dọ̀ ẹnì kejì. 12  Ábúrámù ń gbé ní ilẹ̀ Kénáánì, ṣùgbọ́n Lọ́ọ̀tì ń gbé láàárín àwọn ìlú ńlá Àgbègbè náà.+ Níkẹyìn, ó pàgọ́ sí tòsí Sódómù. 13  Àwọn ọkùnrin Sódómù sì burú, wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku sí Jèhófà.+ 14  Jèhófà sì wí fún Ábúrámù lẹ́yìn tí Lọ́ọ̀tì ti yà sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ pé: “Gbé ojú rẹ sókè, jọ̀wọ́, kí o sì wo ìhà àríwá àti ìhà gúúsù àti ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn,+ láti ibi tí o wà, 15  nítorí pé gbogbo ilẹ̀ náà tí ìwọ ń wò, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ ni èmi yóò fi fún títí di àkókò tí ó lọ kánrin.+ 16  Èmi yóò sì sọ irú-ọmọ rẹ dà bí egunrín ekuru ilẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé, bí ènìyàn kan bá lè ka egunrín ekuru ilẹ̀, nígbà náà, irú-ọmọ rẹ ni a ó lè kà.+ 17  Dìde, lọ káàkiri la ilẹ̀ náà já ní gígùn rẹ̀ àti ní ìbú rẹ̀, nítorí pé ìwọ ni èmi yóò fi í fún.”+ 18  Nítorí náà, Ábúrámù ń bá a lọ láti gbé nínú àwọn àgọ́. Lẹ́yìn náà, ó wá, ó sì ń gbé láàárín àwọn igi ńlá Mámúrè,+ èyí tí ó wà ní Hébúrónì;+ ibẹ̀ ni ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí mọ pẹpẹ kan fún Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé