Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 12:1-20

12  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún Ábúrámù pé: “Bá ọ̀nà rẹ lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ àti kúrò ní ilé baba rẹ sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́;+  èmi yóò sì mú orílẹ̀-èdè ńlá jáde lára rẹ, èmi yóò sì bù kún ọ, èmi yóò sì mú kí orúkọ rẹ di ńlá; kí ìwọ fúnra rẹ sì jẹ́ ìbùkún.+  Èmi yóò sì súre fún àwọn tí ń súre fún ọ, ẹni tí ó sì ń pe ibi sọ̀ kalẹ̀ wá sórí rẹ ni èmi yóò fi gégùn-ún,+ gbogbo ìdílé orí ilẹ̀ yóò sì bù kún ara wọn dájúdájú nípasẹ̀ rẹ.”+  Látàrí ìyẹn, Ábúrámù lọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ fún un, Lọ́ọ̀tì sì bá a lọ. Ábúrámù sì jẹ́ ẹni àrùn-dín-lọ́gọ́rin ọdún nígbà tí ó jáde kúrò ní Háránì.+  Nítorí náà, Ábúrámù mú Sáráì aya rẹ̀+ àti Lọ́ọ̀tì ọmọkùnrin arákùnrin rẹ̀+ àti gbogbo ẹrù tí wọ́n ti kó jọ rẹpẹtẹ+ àti àwọn ọkàn tí wọ́n ti ní ní Háránì, wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n láti jáde lọ sí ilẹ̀ Kénáánì. Níkẹyìn, wọ́n dé ilẹ̀ Kénáánì.+  Ábúrámù sì la ilẹ̀ náà kọjá lọ títí dé ibi tí Ṣékémù+ wà, nítòsí àwọn igi ńlá Mórè;+ ní àkókò yẹn, ọmọ Kénáánì sì wà ní ilẹ̀ náà.  Wàyí o, Jèhófà fara han Ábúrámù, ó sì wí pé: “Irú-ọmọ rẹ+ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí+ fún.” Lẹ́yìn náà, ó mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà, ẹni tí ó fara hàn án.  Nígbà tí ó ṣe, ó ṣí kúrò níbẹ̀ lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá sí ìlà-oòrùn Bẹ́tẹ́lì,+ ó sì pa àgọ́ rẹ̀, tí Bẹ́tẹ́lì wà ní ìwọ̀-oòrùn, tí Áì+ sì wà ní ìlà-oòrùn. Lẹ́yìn náà, ó mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ Jèhófà.+  Lẹ́yìn náà, Ábúrámù ṣí ibùdó, ó ń lọ láti ibùdó sí ibùdó síhà Négébù.+ 10  Wàyí o, ìyàn kan mú ní ilẹ̀ náà, Ábúrámù sì sọ̀ kalẹ̀ lọ ní ọ̀nà rẹ̀ sí Íjíbítì láti ṣe àtìpó+ níbẹ̀, nítorí pé ìyàn náà mú gidigidi ní ilẹ̀ náà.+ 11  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí ó sún mọ́ àtiwọnú Íjíbítì, nígbà náà ni ó sọ fún Sáráì aya rẹ̀ pé: “Wàyí o, jọ̀wọ́! Mo mọ̀ dáadáa pé o jẹ́ obìnrin kan tí ó lẹ́wà ní ìrísí.+ 12  Nítorí náà, ó dájú pé yóò ṣẹlẹ̀ pé àwọn ará Íjíbítì yóò rí ọ, wọn yóò sì wí pé, ‘Aya rẹ̀ nìyí.’ Dájúdájú, wọn yóò sì pa mi, ṣùgbọ́n ìwọ ni wọn yóò pa mọ́ láàyè. 13  Jọ̀wọ́, sọ pé arábìnrin mi+ ni ọ́, kí ó bàa lè lọ dáadáa fún mi ní tìtorí rẹ, ó sì dájú pé ọkàn mi yóò wà láàyè nítorí rẹ.”+ 14  Nítorí náà, ó ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Ábúrámù wọ Íjíbítì, àwọn ará Íjíbítì sì rí obìnrin náà, pé ó lẹ́wà gidigidi. 15  Àwọn ọmọ aládé Fáráò sì rí i pẹ̀lú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yìn ín lójú Fáráò, tí ó fi jẹ́ pé a mú obìnrin náà lọ sí ilé Fáráò. 16  Ó sì bá Ábúrámù lò lọ́nà dáadáa ní tìtorí obìnrin náà, ó sì wá ní àwọn àgùntàn àti àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti àwọn ràkúnmí.+ 17  Nígbà náà ni Jèhófà fọwọ́ ìyọnu àjàkálẹ̀ ńlá+ ba Fáráò àti agbo ilé rẹ̀ nítorí Sáráì, aya Ábúrámù.+ 18  Pẹ̀lú èyí, Fáráò pe Ábúrámù, ó sì wí pé: “Kí ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Èé ṣe tí ìwọ kò fi sọ fún mi pé aya rẹ ni?+ 19  Èé ṣe tí o fi sọ pé, ‘Arábìnrin mi ni,’+ tí mo fi fẹ́rẹ̀ẹ́ mú un ṣe aya mi? Wàyí o, aya rẹ rèé. Mú un, kí o sì máa lọ!” 20  Fáráò sì pa àṣẹ fún àwọn ọkùnrin nípa rẹ̀, wọ́n sì sin òun àti aya rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ní jáde.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé