Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 11:1-32

11  Wàyí o, gbogbo ilẹ̀ ayé ń bá a lọ láti jẹ́ èdè kan àti irú àwọn ọ̀rọ̀ kan.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé nínú ìrìn àjò wọn síhà ìlà-oòrùn ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n ṣàwárí pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì kan ní ilẹ̀ Ṣínárì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé níbẹ̀.  Olúkúlùkù sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún ẹnì kejì rẹ̀ pé: “Ó yá! Ẹ jẹ́ kí a ṣe àwọn bíríkì kí a sì fi ọ̀nà ìgbà sun nǹkan sun wọ́n.” Nítorí náà, bíríkì jẹ́ òkúta fún wọn, ṣùgbọ́n ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì jẹ́ erùpẹ̀ àpòrọ́ fún wọn.+  Wọ́n sọ wàyí pé: “Ó yá! Ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú ńlá kan dó fún ara wa kí a sì tún kọ́ ilé gogoro tí téńté rẹ̀ dé ọ̀run,+ ẹ sì jẹ́ kí a ṣe orúkọ lílókìkí fún ara wa,+ kí a má bàa tú ká sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”+  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ láti rí ìlú ńlá náà àti ilé gogoro tí àwọn ọmọ ènìyàn kọ́.+  Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà wí pé: “Wò ó! Ènìyàn kan ni wọ́n, èdè kan ni ó sì wà fún gbogbo wọn,+ èyí sì ni ohun tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe. Họ́wù, wàyí o, kò sí ohun kan tí wọ́n lè ní lọ́kàn láti ṣe tí yóò jẹ́ àléèbá fún wọn.+  Wá nísinsìnyí! Jẹ́ kí a+ sọ̀ kalẹ̀ kí a sì da èdè wọn rú+ níbẹ̀ kí wọ́n má bàa gbọ́ èdè ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ Jèhófà tú wọn ká kúrò níbẹ̀ sórí gbogbo ilẹ̀ ayé,+ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n sì dẹ́kun títẹ ìlú ńlá náà dó.+  Ìdí nìyẹn tí a fi pè orúkọ rẹ̀ ní Bábélì,+ nítorí pé ibẹ̀ ni Jèhófà ti da èdè gbogbo ilẹ̀ ayé rú, ibẹ̀ sì ni Jèhófà ti tú wọn ká+ sórí gbogbo ilẹ̀ ayé. 10  Èyí ni ọ̀rọ̀-ìtàn nípa Ṣémù.+ Ṣémù jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún nígbà tí ó bí Ápákíṣádì+ ní ọdún kejì lẹ́yìn àkúnya omi. 11  Lẹ́yìn tí ó sì bí Ápákíṣádì, Ṣémù ń bá a lọ láti wà láàyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún. Láàárín àkókò náà, ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.+ 12  Ápákíṣádì sì wà láàyè fún ọdún márùndínlógójì. Lẹ́yìn náà, ó bí Ṣélà.+ 13  Lẹ́yìn tí ó bí Ṣélà, Ápákíṣádì ń bá a lọ láti wà láàyè fún irínwó ọdún ó lé mẹ́ta. Láàárín àkókò náà, ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. 14  Ṣélà sì wà láàyè fún ọgbọ̀n ọdún. Lẹ́yìn náà, ó bí Ébérì.+ 15  Lẹ́yìn tí ó sì bí Ébérì, Ṣélà ń bá a lọ láti wà láàyè fún irínwó ọdún ó lé mẹ́ta. Láàárín àkókò náà, ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. 16  Ébérì sì ń bá a nìṣó láti wà láàyè fún ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n. Lẹ́yìn náà, ó bí Pélégì.+ 17  Lẹ́yìn tí ó sì bí Pélégì, Ébérì ń bá a lọ láti wà láàyè fún irínwó ọdún ó lé ọgbọ̀n. Láàárín àkókò náà, ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. 18  Pélégì sì ń bá a nìṣó láti wà láàyè fún ọgbọ̀n ọdún. Lẹ́yìn náà, ó bí Réù.+ 19  Lẹ́yìn tí ó sì bí Réù, Pélégì ń bá a lọ láti wà láàyè fún igba ọdún ó lé mẹ́sàn-án. Láàárín àkókò náà, ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. 20  Réù sì ń bá a nìṣó láti wà láàyè fún ọdún méjìlélọ́gbọ̀n. Lẹ́yìn náà, ó bí Sérúgù.+ 21  Lẹ́yìn tí ó sì bí Sérúgù, Réù ń bá a lọ láti wà láàyè fún igba ọdún ó lé méje. Láàárín àkókò náà, ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. 22  Sérúgù sì ń bá a nìṣó láti wà láàyè fún ọgbọ̀n ọdún. Lẹ́yìn náà, ó bí Náhórì.+ 23  Lẹ́yìn tí ó sì bí Náhórì, Sérúgù ń bá a lọ láti wà láàyè fún igba ọdún. Láàárín àkókò náà, ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. 24  Náhórì sì ń bá a nìṣó láti wà láàyè fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n. Lẹ́yìn náà, ó bí Térà.+ 25  Lẹ́yìn tí ó sì bí Térà, Náhórì ń bá a lọ láti wà láàyè fún ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́fà. Láàárín àkókò náà, ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. 26  Térà sì ń bá a nìṣó láti wà láàyè fún àádọ́rin ọdún, lẹ́yìn èyí tí ó bí Ábúrámù,+ Náhórì+ àti Háránì. 27  Èyí sì ni ọ̀rọ̀-ìtàn nípa Térà. Térà bí Ábúrámù, Náhórì àti Háránì; Háránì sì bí Lọ́ọ̀tì.+ 28  Nígbà tí ó ṣe, Háránì kú nígbà tí ó wà pẹ̀lú Térà baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀, ní Úrì+ ti àwọn ará Kálídíà.+ 29  Ábúrámù àti Náhórì sì tẹ̀ síwájú láti mú aya fún ara wọn. Orúkọ aya Ábúrámù ni Sáráì,+ nígbà tí orúkọ aya Náhórì ń jẹ́ Mílíkà,+ ọmọbìnrin Háránì, baba Mílíkà àti baba Ísíkà. 30  Ṣùgbọ́n Sáráì ń bá a lọ láti jẹ́ àgàn;+ kò ní ọmọ kankan. 31  Lẹ́yìn ìyẹn, Térà mú Ábúrámù ọmọkùnrin rẹ̀ àti Lọ́ọ̀tì, ọmọkùnrin Háránì, ọmọ ọmọ rẹ̀,+ àti Sáráì+ aya ọmọ rẹ̀, aya Ábúrámù ọmọkùnrin rẹ̀, wọ́n sì bá a jáde kúrò ní Úrì ti àwọn ará Kálídíà, láti lọ sí ilẹ̀ Kénáánì.+ Nígbà tí ó ṣe, wọ́n dé Háránì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé níbẹ̀. 32  Àwọn ọjọ́ Térà sì wá jẹ́ igba ọdún ó lé márùn-ún. Lẹ́yìn náà, Térà kú ní Háránì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé