Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 10:1-32

10  Èyí sì ni ọ̀rọ̀-ìtàn nípa àwọn ọmọkùnrin Nóà,+ Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì. Wàyí o, a bẹ̀rẹ̀ sí bí àwọn ọmọ fún wọn lẹ́yìn àkúnya omi.+  Àwọn ọmọkùnrin Jáfẹ́tì ni Gómérì+ àti Mágọ́gù+ àti Mádáì+ àti Jáfánì+ àti Túbálì+ àti Méṣékì+ àti Tírásì.+  Àwọn ọmọkùnrin Gómérì sì ni Áṣíkénásì+ àti Rífátì+ àti Tógámà.+  Àwọn ọmọkùnrin Jáfánì sì ni Élíṣáhì+ àti Táṣíṣì,+ Kítímù+ àti Dódánímù.+  Láti ọ̀dọ̀ àwọn wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn erékùṣù àwọn orílẹ̀-èdè ti tàn ká àwọn ilẹ̀ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú ahọ́n rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn, nípa orílẹ̀-èdè wọn.  Àwọn ọmọkùnrin Hámù sì ni Kúṣì+ àti Mísíráímù+ àti Pútì+ àti Kénáánì.+  Àwọn ọmọkùnrin Kúṣì sì ni Sébà+ àti Háfílà àti Sábítà àti Ráámà+ àti Sábítékà. Àwọn ọmọkùnrin Ráámà sì ni Ṣébà àti Dédánì.+  Kúṣì sì bí Nímírọ́dù.+ Òun ni ó bẹ̀rẹ̀ dídi alágbára ńlá ní ilẹ̀ ayé.  Ó fi ara rẹ̀ hàn ní ọdẹ alágbára ńlá ní ìlòdì sí Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí àsọjáde kan fi wà pé: “Gẹ́gẹ́ bí Nímírọ́dù ọdẹ alágbára ńlá ní ìlòdì sí Jèhófà.”+ 10  Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìjọba rẹ̀ sì wá jẹ́ Bábélì+ àti Érékì+ àti Ákádì àti Kálínè, ní ilẹ̀ Ṣínárì.+ 11  Láti ilẹ̀ yẹn ni ó ti jáde lọ sí Ásíríà,+ òun fúnra rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ títẹ Nínéfè+ àti Rehoboti-Írì àti Kálà dó 12  àti Résénì láàárín Nínéfè àti Kálà: èyí ni ìlú ńlá títóbi. 13  Mísíráímù+ sì bí Lúdímù+ àti Ánámímù àti Léhábímù àti Náfítúhímù+ 14  àti Pátírúsímù+ àti Kásílúhímù+ (láti inú àwọn tí àwọn Filísínì+ ti jáde) àti Káfítórímù.+ 15  Kénáánì sì bí Sídónì+ àkọ́bí rẹ̀ àti Hétì+ 16  àti àwọn ará Jébúsì+ àti àwọn Ámórì+ àti àwọn Gẹ́gáṣì 17  àti àwọn Hífì+ àti àwọn Ákì àti àwọn Sáínì 18  àti àwọn ọmọ Áfádì+ àti àwọn Sémárì àti àwọn ará Hámátì;+ lẹ́yìn náà, àwọn ìdílé ọmọ Kénáánì sì tú ká. 19  Nítorí náà, ààlà ọmọ Kénáánì wá jẹ́ láti Sídónì títí dé Gérárì,+ nítòsí Gásà,+ títí dé Sódómù àti Gòmórà+ àti Ádímà+ àti Sébóíímù,+ nítòsí Láṣà. 20  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Hámù ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn, ní ìbámu pẹ̀lú ahọ́n wọn, ní àwọn ilẹ̀ wọn nípa àwọn orílẹ̀-èdè wọn. 21  Àti fún Ṣémù, baba ńlá gbogbo àwọn ọmọ Ébérì,+ arákùnrin Jáfẹ́tì tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n pátápátá, a tún bí àtọmọdọ́mọ. 22  Àwọn ọmọkùnrin Ṣémù ni Élámù+ àti Áṣúrì+ àti Ápákíṣádì+ àti Lúdì àti Árámù. 23  Àwọn ọmọkùnrin Árámù sì ni Úsì àti Húlì àti Gétérì àti Máṣì.+ 24  Ápákíṣádì sì bí Ṣélà,+ Ṣélà sì bí Ébérì. 25  A sì bí ọmọkùnrin méjì fún Ébérì. Orúkọ ọ̀kan ni Pélégì,+ nítorí pé ní ọjọ́ rẹ̀ ni a pín ilẹ̀ ayé níyà;+ orúkọ arákùnrin rẹ̀ sì ni Jókítánì.+ 26  Jókítánì sì bí Álímódádì àti Ṣéléfì àti Hásámáfétì àti Jérà+ 27  àti Hádórámù àti Úsálì àti Díkílà+ 28  àti Óbálì àti Ábímáélì àti Ṣébà+ 29  àti Ófírì+ àti Háfílà+ àti Jóbábù;+ gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọkùnrin Jókítánì. 30  Ibi tí wọ́n sì ń gbé nasẹ̀ láti Méṣà títí dé Séfárì, ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ti Ìlà-Oòrùn. 31  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Ṣémù ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn, ní ìbámu pẹ̀lú ahọ́n wọn, ní àwọn ilẹ̀ wọn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè wọn.+ 32  Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọkùnrin Nóà ní ìbámu pẹ̀lú orírun ìdílé wọn, nípa àwọn orílẹ̀-èdè wọn, láti inú ìwọ̀nyí sì ni àwọn orílẹ̀-èdè ti tàn kálẹ̀ ní ilẹ̀ ayé lẹ́yìn àkúnya omi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé