Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 1:1-31

1  Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀,+ Ọlọ́run++ ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.+  Wàyí o, ilẹ̀ ayé wà ní bọrọgidi, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi;+ ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run sì ń lọ síwá-sẹ́yìn+ lójú omi.+  Ọlọ́run sì tẹ̀ síwájú láti wí pé:+ “Kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà.” Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀+ wá wà.  Lẹ́yìn ìyẹn, Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, Ọlọ́run sì mú kí ìpínyà wà láàárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.+  Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ ní Ọ̀sán,+ ṣùgbọ́n ó pe òkùnkùn ní Òru.+ Alẹ́ sì wá wà, òwúrọ̀ sì wá wà, èyí ni ọjọ́ kìíní.  Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: “Kí òfuurufú+ wà láàárín omi, kí ìpínyà sì ṣẹlẹ̀ láàárín omi àti omi.”+  Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí ṣe òfuurufú, ó sì mú kí ìpínyà wà láàárín omi tí ó yẹ kí ó wà lábẹ́ òfuurufú àti omi tí ó yẹ kí ó wà lókè òfuurufú.+ Ó sì wá rí bẹ́ẹ̀.  Ọlọ́run sì pe òfuurufú ní Ọ̀run.+ Alẹ́ sì wá wà, òwúrọ̀ sì wá wà, èyí ni ọjọ́ kejì.  Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: “Kí omi tí ó wà lábẹ́ ọ̀run wọ́ jọpọ̀ sí ibì kan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì fara hàn.”+ Ó sì wá rí bẹ́ẹ̀. 10  Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ ní Ilẹ̀ Ayé,+ ṣùgbọ́n ìwọ́jọpọ̀ omi ni ó pè ní Òkun.+ Síwájú sí i, Ọlọ́run rí i pé ó dára.+ 11  Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: “Kí ilẹ̀ ayé mú koríko jáde, ewéko tí ń mú irúgbìn jáde,+ àwọn igi eléso tí ń so èso ní irú tiwọn,+ tí irúgbìn rẹ̀ wà nínú rẹ̀,+ lórí ilẹ̀ ayé.” Ó sì wá rí bẹ́ẹ̀. 12  Ilẹ̀ ayé sì bẹ̀rẹ̀ sí mú koríko jáde, ewéko tí ń mú irúgbìn jáde ní irú tirẹ̀+ àti àwọn igi tí ń so èso, tí irúgbìn rẹ̀ wà nínú rẹ̀, ní irú tirẹ̀.+ Nígbà náà, Ọlọ́run rí i pé ó dára. 13  Alẹ́ sì wá wà, òwúrọ̀ sì wá wà, èyí ni ọjọ́ kẹta. 14  Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: “Kí orísun ìmọ́lẹ̀ wà ní òfuurufú ọ̀run láti mú ìpínyà wà láàárín ọ̀sán àti òru;+ wọn yóò sì wà fún àmì àti fún àwọn àsìkò àti fún àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún.+ 15  Wọn yóò sì wà fún orísun ìmọ́lẹ̀ ní òfuurufú ọ̀run láti tàn sórí ilẹ̀ ayé.”+ Ó sì wá rí bẹ́ẹ̀. 16  Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn orísun ìmọ́lẹ̀ ńlá méjì, orísun ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbi láti jọba lórí ọ̀sán àti orísun ìmọ́lẹ̀ tí ó kéré láti jọba lórí òru, àti àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú.+ 17  Nípa báyìí, Ọlọ́run fi wọ́n sí òfuurufú ọ̀run láti tàn sórí ilẹ̀ ayé,+ 18  àti láti jọba ní ọ̀sán àti ní òru àti láti mú kí ìpínyà wà láàárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.+ Ọlọ́run wá rí i pé ó dára.+ 19  Alẹ́ sì wá wà, òwúrọ̀ sì wá wà, èyí ni ọjọ́ kẹrin. 20  Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: “Kí omi mú àwọn alààyè ọkàn+ agbáyìn-ìn máa gbá yìn-ìn, kí àwọn ẹ̀dá tí ń fò sì máa fò lókè ilẹ̀ ayé lójú òfuurufú ọ̀run.”+ 21  Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá àwọn abàmì+ ẹran ńlá inú òkun àti olúkúlùkù alààyè ọkàn tí ń rìn kiri,+ èyí tí omi ń mú gbá yìn-ìn ní irú tiwọn, àti olúkúlùkù ẹ̀dá abìyẹ́lápá tí ń fò ní irú tirẹ̀.+ Ọlọ́run sì wá rí i pé ó dára. 22  Látàrí ìyẹn, Ọlọ́run súre fún wọn, pé: “Ẹ máa so èso kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún inú omi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ òkun,+ kí àwọn ẹ̀dá tí ń fò sì di púpọ̀ ní ilẹ̀ ayé.” 23  Alẹ́ sì wá wà, òwúrọ̀ sì wá wà, èyí ni ọjọ́ karùn-ún. 24  Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: “Kí ilẹ̀ ayé+ mú alààyè ọkàn jáde ní irú tiwọn, ẹran agbéléjẹ̀+ àti ẹran tí ń rìn ká+ àti ẹranko ìgbẹ́+ ilẹ̀ ayé ní irú tirẹ̀.” Ó sì wá rí bẹ́ẹ̀. 25  Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ẹranko ìgbẹ́ ilẹ̀ ayé ní irú tirẹ̀ àti ẹran agbéléjẹ̀ ní irú tirẹ̀+ àti olúkúlùkù ẹran tí ń rìn ká ilẹ̀ ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì wá rí i pé ó dára. 26  Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: “Jẹ́ kí a+ ṣe ènìyàn ní àwòrán+ wa, ní ìrí+ wa, kí wọ́n sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti àwọn ẹran agbéléjẹ̀ àti gbogbo ilẹ̀ ayé àti olúkúlùkù ẹran tí ń rìn ká, tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.”+ 27  Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a;+ akọ àti abo ni ó dá wọn.+ 28  Síwájú sí i, Ọlọ́run súre+ fún wọn, Ọlọ́run sì wí fún wọn pé: “Ẹ máa so èso,+ kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́+ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí+ ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.” 29  Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: “Kíyè sí i, mo ti fi gbogbo ewéko tí ń mú irúgbìn jáde fún yín, èyí tí ó wà lórí gbogbo ilẹ̀ ayé, àti gbogbo igi lórí èyí tí èso igi tí ń mú irúgbìn jáde wà.+ Kí ó jẹ́ oúnjẹ+ fún yín. 30  Àti fún olúkúlùkù ẹranko ìgbẹ́ ilẹ̀ ayé àti olúkúlùkù ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti fún ohun gbogbo tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé ní inú èyí tí ìwàláàyè wà gẹ́gẹ́ bí ọkàn, [ni mo ti fún] ní gbogbo ewéko tútù yọ̀yọ̀ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ.”+ Ó sì wá rí bẹ́ẹ̀. 31  Lẹ́yìn ìyẹn, Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára+ gan-an ni. Alẹ́ sì wá wà, òwúrọ̀ sì wá wà, èyí ni ọjọ́ kẹfà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé