Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jákọ́bù 5:1-20

5  Ẹ wá, nísinsìnyí, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀,+ ẹ sunkún, ẹ hu nítorí ìṣẹ́ yín tí ń bọ̀ wá sórí yín.+  Ọrọ̀ yín ti jẹrà, àwọn ẹ̀wù àwọ̀lékè yín sì ti di èyí tí òólá ti lá.+  Wúrà àti fàdákà yín ti dípẹtà dànù, ìpẹtà wọn yóò sì jẹ́ bí ẹ̀rí lòdì sí yín, yóò sì jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara yín. Ohun tí ó dà bí iná+ ni ẹ ti tò jọ pa mọ́+ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.+  Wò ó! Owó ọ̀yà tí ó tọ́ sí àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n kórè pápá yín ṣùgbọ́n tí ẹ pa mọ́wọ́,+ ń ké jáde ṣáá,+ àwọn igbe fún ìrànlọ́wọ́+ níhà ọ̀dọ̀ àwọn akárúgbìn sì ti wọ etí+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.  Ẹ ti gbé nínú fàájì lórí ilẹ̀ ayé, ẹ sì ti kó wọnú adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara.+ Ẹ ti bọ́ ọkàn-àyà yín sanra ní ọjọ́ ìfikúpa.+  Ẹ ti dáni lẹ́bi, ẹ ti ṣìkà pa olódodo. Òun kò ha ń takò yín bí?+  Nítorí náà, ẹ mú sùúrù, ẹ̀yin ará, títí di ìgbà wíwàníhìn-ín+ Olúwa. Wò ó! Àgbẹ̀ a máa dúró de èso ṣíṣeyebíye ilẹ̀ ayé, ní mímú sùúrù lórí rẹ̀ títí yóò fi rí òjò àkọ́rọ̀ àti òjò àrọ̀kúrò.+  Ẹ̀yin pẹ̀lú ẹ mú sùúrù;+ ẹ fìdí ọkàn-àyà yín múlẹ̀ gbọn-in, nítorí wíwàníhìn-ín Olúwa ti sún mọ́lé.+  Ẹ má ṣe mí ìmí ẹ̀dùn lòdì sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ̀yin ará, kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.+ Wò ó! Onídàájọ́ ń dúró níwájú àwọn ilẹ̀kùn.+ 10  Ẹ̀yin ará, ẹ fi àwọn wòlíì,+ àwọn tí wọ́n sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà+ ṣe àpẹẹrẹ+ jíjìyà ibi+ àti mímú sùúrù.+ 11  Wò ó! Àwọn tí wọ́n lo ìfaradà ní a ń pè ní aláyọ̀.+ Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù,+ ẹ sì ti rí ìyọrísí tí Jèhófà mú wá,+ pé Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.+ 12  Ṣùgbọ́n, lékè ohun gbogbo, ẹ̀yin ará mi, ẹ dẹ́kun bíbúra, bẹ́ẹ̀ ni, yálà fífi ọ̀run tàbí ilẹ̀ ayé búra tàbí ìbúra èyíkéyìí mìíràn.+ Ṣùgbọ́n kí Bẹ́ẹ̀ ni yín túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, àti Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ẹ má bàa bọ́ sábẹ́ ìdájọ́.+ 13  Ẹnikẹ́ni ha wà tí ń jìyà ibi láàárín yín bí? Kí ó máa bá a lọ ní gbígbàdúrà.+ Ẹnikẹ́ni ha wà nínú ara yíyágágá bí? Kí ó máa fi àwọn sáàmù ṣe orin kọ.+ 14  Ẹnikẹ́ni ha wà tí ń ṣàìsàn láàárín yín bí?+ Kí ó pe àwọn àgbà ọkùnrin+ ìjọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì gbàdúrà lé e lórí, ní fífi òróró pa á+ ní orúkọ Jèhófà. 15  Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì mú aláàárẹ̀ náà lára dá,+ Jèhófà yóò sì gbé e dìde.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí ó bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀, a óò dárí rẹ̀ jì í.+ 16  Nítorí náà, ẹ máa jẹ́wọ́+ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ní gbangba fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ lè gba ìmúláradá.+ Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo, nígbà tí ó bá wà lẹ́nu iṣẹ́, ní ipá púpọ̀.+ 17  Èlíjà jẹ́ ènìyàn tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa,+ síbẹ̀síbẹ̀ nínú àdúrà, ó gbàdúrà pé kí òjò má ṣe rọ̀;+ òjò kò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ náà fún ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́fà. 18  Ó sì tún gbàdúrà, ọ̀run sì rọ òjò, ilẹ̀ sì mú èso rẹ̀ jáde wá.+ 19  Ẹ̀yin ará mi, bí a bá ṣi ẹnikẹ́ni láàárín yín lọ́nà kúrò nínú òtítọ́, tí ẹlòmíràn sì yí i padà,+ 20  mọ̀ pé ẹni tí ó yí ẹlẹ́ṣẹ̀ padà kúrò nínú ìṣìnà+ rẹ̀ yóò gba ọkàn rẹ̀ là kúrò lọ́wọ́ ikú,+ yóò sì bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé