Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jákọ́bù 4:1-17

4  Láti orísun wo ni àwọn ogun ti wá, láti orísun wo sì ni àwọn ìjà ti wá láàárín yín? Wọn kì í ha ṣe láti orísun yìí,+ èyíinì ni, láti inú àwọn ìfàsí-ọkàn yín fún adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara èyí tí ń bá ìforígbárí nìṣó nínú àwọn ẹ̀yà ara yín?+  Ẹ ń fẹ́, síbẹ̀ ẹ kò ní. Ẹ ń bá a lọ ní ṣíṣìkàpànìyàn+ àti ní ṣíṣojúkòkòrò,+ síbẹ̀ ẹ kò lè rí gbà. Ẹ ń bá a lọ ní jíjà,+ ẹ sì ń ja ogun. Ẹ kò ní nítorí tí ẹ kì í béèrè.  Lóòótọ́ ẹ ń béèrè, síbẹ̀ ẹ kò rí gbà, nítorí tí ẹ ń béèrè fún ète tí kò tọ́,+ kí ẹ lè lò ó lórí àwọn ìfàsí-ọkàn yín fún adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara.+  Ẹ̀yin panṣágà obìnrin,+ ẹ kò ha mọ̀ pé ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run?+ Nítorí náà, ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́+ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.+  Tàbí lójú yín, ó ha dà bí ẹni pé lásán ni ìwé mímọ́ wí pé: “Ó jẹ́ pẹ̀lú ìtẹ̀sí láti ṣe ìlara ni ẹ̀mí+ tí ń gbé inú wa fi ń yánhànhàn”?  Àmọ́ ṣá o, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí ó fi fúnni tóbi jù.+ Nítorí bẹ́ẹ̀, ó wí pé: “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera,+ ṣùgbọ́n ó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”+  Nítorí náà, ẹ fi ara yín sábẹ́+ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù,+ yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.+  Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.+ Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀,+ kí ẹ sì wẹ ọkàn-àyà yín mọ́ gaara,+ ẹ̀yin aláìnípinnu.+  Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí ṣíṣẹ̀ẹ́, kí ẹ sì ṣọ̀fọ̀, kí ẹ sì sunkún.+ Kí ẹ̀rín yín di ọ̀fọ̀, kí ìdùnnú yín sì di ìdoríkodò.+ 10  Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ ní ojú Jèhófà,+ yóò sì gbé yín ga.+ 11  Ẹ jáwọ́ nínú sísọ̀rọ̀ lòdì sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ̀yin ará.+ Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ lòdì sí arákùnrin kan tàbí tí ń dá arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́+ ń sọ̀rọ̀ lòdì sí òfin, ó sì ń dá òfin lẹ́jọ́. Wàyí o, bí o bá ń dá òfin lẹ́jọ́, ìwọ kì í ṣe olùṣe ohun tí òfin wí bí kò ṣe onídàájọ́.+ 12  Ẹnì kan ni ó wà tí ó jẹ́ afúnnilófin àti onídàájọ́,+ ẹni tí ó lè gbà là, tí ó sì lè pa run.+ Ṣùgbọ́n ìwọ, ta ni ọ́ tí o fi ní láti máa ṣèdájọ́ aládùúgbò rẹ?+ 13  Ẹ wá, nísinsìnyí, ẹ̀yin tí ẹ ń sọ pé: “Lónìí tàbí lọ́la a ó rin ìrìn àjò lọ sí ìlú ńlá yìí, a ó sì lo ọdún kan níbẹ̀, a ó sì kó wọnú iṣẹ́ òwò, a ó sì jèrè,”+ 14  nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ kò mọ ohun tí ìwàláàyè yín yóò jẹ́ lọ́la.+ Nítorí ìkùukùu ni yín tí ń fara hàn fún ìgbà díẹ̀ àti lẹ́yìn tí ń dàwátì.+ 15  Dípò bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ sọ pé: “Bí Jèhófà bá fẹ́,+ àwa yóò wà láàyè, a ó sì ṣe èyí tàbí èyíinì pẹ̀lú.”+ 16  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ẹ ń yangàn nínú ìfọ́nnu ìjọra-ẹni-lójú yín.+ Irú gbogbo ìyangàn bẹ́ẹ̀ burú. 17  Nítorí náà, bí ẹnì kan bá mọ bí a ti ń ṣe ohun tí ó tọ́, síbẹ̀ tí kò ṣe é,+ ẹ̀ṣẹ̀+ ni fún un.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé