Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jákọ́bù 3:1-18

3  Kí púpọ̀ nínú yín má ṣe di olùkọ́,+ ẹ̀yin arákùnrin mi, ní mímọ̀ pé àwa yóò gba ìdájọ́ tí ó wúwo jù.+  Nítorí gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.+ Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀,+ ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé,+ tí ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ pẹ̀lú níjàánu.  Bí a bá fi ìjánu+ bọ ẹnu àwọn ẹṣin kí wọ́n lè ṣègbọràn sí wa,+ gbogbo ara wọn pẹ̀lú ni a fi sábẹ́ ìdarí.  Wò ó! Àwọn ọkọ̀ ojú omi pàápàá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n tóbi gan-an, tí ẹ̀fúùfù líle sì ń gbá wọn kiri, ìtọ́kọ̀+ tí ó kéré gan-an ni a fi ń tọ́ wọn sí ibi tí ìtẹ̀sí èrò ọkùnrin tí ó wà nídìí àgbá ìtọ́kọ̀ bá fẹ́.  Bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú, ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà ara kékeré, síbẹ̀ a máa ṣe ìfọ́nnu ńlá.+ Wò ó! Bí iná tí a fi ń dáná ran igbó igi tí ó tóbi gan-an ti kéré tó!  Tóò, ahọ́n jẹ́ iná.+ Ahọ́n jẹ́ ayé àìṣòdodo lára àwọn ẹ̀yà ara wa, nítorí ó máa ń fi èérí yí gbogbo ara,+ ó sì máa ń mú àgbá kẹ̀kẹ́ ìgbésí ayé ẹ̀dá gbiná, Gẹ̀hẹ́nà sì máa ń mú un gbiná.  Nítorí gbogbo irú ẹranko ẹhànnà àti ẹyẹ àti ohun tí ń rákò àti ẹ̀dá òkun ni a ó rọ̀ lójú, tí a sì ti rọ̀ lójú nípasẹ̀ ìran aráyé.+  Ṣùgbọ́n ahọ́n, kò sí ẹnì kan nínú aráyé tí ó lè rọ̀ ọ́ lójú. Ohun ewèlè tí ń ṣeni léṣe, ó kún fún panipani májèlé.+  Òun ni a fi ń fi ìbùkún fún Jèhófà,+ àní Baba,+ síbẹ̀ òun ni a fi ń gégùn-ún+ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n di wíwà “ní jíjọ Ọlọ́run.”+ 10  Láti inú ẹnu kan náà ni ìbùkún àti ègún ti ń jáde wá. Kò bẹ́tọ̀ọ́ mu, ẹ̀yin ará mi, kí nǹkan wọ̀nyí máa bá a lọ ní ṣíṣẹlẹ̀ lọ́nà yìí.+ 11  Ìsun+ kan kì í mú kí dídùn àti kíkorò tú jáde láti ojú ihò kan náà, àbí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀? 12  Ẹ̀yin ará mi, igi ọ̀pọ̀tọ́ kò lè mú àwọn èso ólífì jáde tàbí kí àjàrà mú àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ jáde, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀?+ Bẹ́ẹ̀ ni omi iyọ̀ kò lè mú omi dídùn jáde. 13  Ta ni nínú yín tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti olóye? Kí ó fi àwọn iṣẹ́+ rẹ̀ hàn láti inú ìwà rẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú ìwà tútù tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n. 14  Ṣùgbọ́n bí ẹ bá ní owú kíkorò+ àti ẹ̀mí asọ̀+ nínú ọkàn-àyà yín, ẹ má ṣe máa fọ́nnu,+ kí ẹ má sì máa purọ́ lòdì sí òtítọ́.+ 15  Èyí kọ́ ni ọgbọ́n tí ó sọ̀ kalẹ̀ wá láti òkè,+ ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ilẹ̀ ayé,+ ti ẹranko, ti ẹ̀mí èṣù.+ 16  Nítorí níbi tí owú+ àti ẹ̀mí asọ̀ bá wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti gbogbo ohun búburú wà.+ 17  Ṣùgbọ́n ọgbọ́n+ tí ó wá láti òkè a kọ́kọ́ mọ́ níwà,+ lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà,+ ó ń fòye báni lò,+ ó múra tán láti ṣègbọràn, ó kún fún àánú àti àwọn èso rere,+ kì í ṣe àwọn ìyàtọ̀ olójúsàájú,+ kì í ṣe àgàbàgebè.+ 18  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, èso+ òdodo+ ni a ń fún irúgbìn rẹ̀ lábẹ́ àwọn ipò tí ó kún fún àlàáfíà+ fún àwọn tí ń wá àlàáfíà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé