Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jákọ́bù 2:1-26

2  Ẹ̀yin ará mi, ẹ kò di ìgbàgbọ́ Olúwa wa Jésù Kristi, ògo wa,+ mú pẹ̀lú ìṣègbè,+ àbí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀?  Nítorí, bí ọkùnrin kan pẹ̀lú àwọn òrùka wúrà ní àwọn ìka rẹ̀, tí ó sì wọ aṣọ dídángbinrin bá wọlé sínú ìpéjọpọ̀+ yín, ṣùgbọ́n tí òtòṣì kan tí ó wọ aṣọ eléèérí pẹ̀lú wọlé,+  síbẹ̀ tí ẹ fi ojú rere+ wo ẹni tí ó wọ aṣọ dídángbinrin, tí ẹ sì wí pé: “Ìwọ mú ìjókòó yìí tí ó wà níhìn-ín ní ibi tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀,” tí ẹ sì wí fún òtòṣì náà pé: “Ìwọ wà ní ìdúró,” tàbí: “Mú ìjókòó tí ó wà ní ibẹ̀ yẹn lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi,”  ẹ̀yin ní ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ láàárín ara yín,+ ẹ sì ti di onídàájọ́+ tí ń ṣe àwọn ìpinnu burúkú,+ àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?  Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ara mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n. Ọlọ́run yan àwọn tí í ṣe òtòṣì+ ní ti ayé láti jẹ́ ọlọ́rọ̀+ nínú ìgbàgbọ́ àti ajogún ìjọba náà, èyí tí ó ṣèlérí fún àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ àbí kò ṣe bẹ́ẹ̀?  Ṣùgbọ́n, ẹ̀yin, ti tàbùkù sí òtòṣì náà. Àwọn ọlọ́rọ̀ a máa ni yín lára,+ wọn a sì máa wọ́ yín lọ sí àwọn kóòtù òfin,+ àbí wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀?  Wọn a máa sọ̀rọ̀ òdì+ sí orúkọ àtàtà tí a fi ń pè yín,+ àbí wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀?  Nísinsìnyí, bí ẹ bá sọ ọ́ dàṣà láti máa mú ọba òfin+ ṣẹ ní ìbámu pẹ̀lú ìwé mímọ́ náà: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ,”+ ẹ ń ṣe dáadáa ní ti gidi.  Ṣùgbọ́n bí ẹ bá ń bá a lọ ní fífi ìṣègbè hàn,+ ẹ ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, nítorí tí òfin+ fi ìbáwí tọ́ yín sọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùrélànàkọjá. 10  Nítorí ẹnì yòówù tí ó bá ń pa gbogbo Òfin mọ́ ṣùgbọ́n tí ó ṣi ẹsẹ̀ gbé nínú kókó kan, ó ti di olùrú gbogbo wọn.+ 11  Nítorí ẹni tí ó wí pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà,”+ wí pẹ̀lú pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn.”+ Wàyí o, bí ìwọ kò bá ṣe panṣágà ṣùgbọ́n tí o ṣìkà pànìyàn ní tòótọ́, o ti di olùré òfin kọjá. 12  Ẹ máa bá a nìṣó ní sísọ̀rọ̀ ní irúfẹ́ ọ̀nà bẹ́ẹ̀, kí ẹ sì máa bá a nìṣó ní irúfẹ́ ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ní ṣíṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a ó fi òfin àwọn ẹni òmìnira dá lẹ́jọ́ ti ń ṣe.+ 13  Nítorí ẹni tí kò bá sọ àánú ṣíṣe dàṣà yóò gba ìdájọ́ rẹ̀ láìsí àánú.+ Àánú a máa yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìdájọ́. 14  Àǹfààní wo ni ó jẹ́, ẹ̀yin ará mi, bí ẹnì kan bá sọ pé òun ní ìgbàgbọ́+ ṣùgbọ́n tí kò ní àwọn iṣẹ́?+ Ìgbàgbọ́ yẹn kò lè gbà á là, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀?+ 15  Bí arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan bá wà ní ipò ìhòòhò, tí ó sì ṣaláìní oúnjẹ tí ó tó fún òòjọ́,+ 16  síbẹ̀ tí ẹnì kan nínú yín sọ fún wọn pé: “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà, kí ara yín yá gágá, kí ẹ sì jẹun yó dáadáa,” ṣùgbọ́n tí ẹ kò fún wọn ní àwọn ohun kò-ṣeé-má-nìí fún ara wọn, àǹfààní wo ni ó jẹ́?+ 17  Bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú, ìgbàgbọ́, bí kò bá ní àwọn iṣẹ́,+ jẹ́ òkú nínú ara rẹ̀. 18  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹnì kan yóò wí pé: “Ìwọ ní ìgbàgbọ́, èmi sì ní àwọn iṣẹ́. Fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn mí láìsí àwọn iṣẹ́, èmi yóò sì fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa àwọn iṣẹ́ mi.”+ 19  Ìwọ gbà gbọ́ pé Ọlọ́run kan ni ń bẹ, àbí?+ Ìwọ ń ṣe dáadáa ní ti gidi. Àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbà gbọ́, wọ́n sì fi ẹ̀rù wárìrì.+ 20  Ṣùgbọ́n ìwọ ha bìkítà láti mọ̀, ìwọ òfìfo ènìyàn, pé ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ aláìṣiṣẹ́? 21  A kò ha polongo Ábúráhámù baba wa+ ní olódodo nípa àwọn iṣẹ́ lẹ́yìn tí ó ti fi Ísákì ọmọkùnrin rẹ̀ rúbọ lórí pẹpẹ?+ 22  Ẹ̀yin rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àti nípa àwọn iṣẹ́ rẹ̀ a sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ di pípé,+ 23  a sì mú ìwé mímọ́ náà ṣẹ tí ó wí pé: “Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, a sì kà á sí òdodo fún un,”+ ó sì di ẹni tí a ń pè ní “ọ̀rẹ́ Jèhófà.”+ 24  Ẹ̀yin rí i pé a ó polongo ènìyàn kan ní olódodo+ nípa àwọn iṣẹ́,+ kì í sì í ṣe nípa ìgbàgbọ́ nìkan.+ 25  Lọ́nà kan náà, a kò ha polongo Ráhábù+ aṣẹ́wó pẹ̀lú ní olódodo nípa àwọn iṣẹ́, lẹ́yìn tí ó ti gba àwọn ońṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò, tí ó sì rán wọn jáde gba ọ̀nà mìíràn?+ 26  Ní tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí ara láìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú,+ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé