Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Hóséà 9:1-17

9  “Má yọ̀, ìwọ Ísírẹ́lì.+ Má dunnú bí àwọn ènìyàn.+ Nítorí nípasẹ̀ àgbèrè, o ti lọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ.+ O ti nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹ̀bùn ìháyà lórí gbogbo ilẹ̀ ìpakà.+  Ilẹ̀ ìpakà àti ibi ìfúntí wáìnì kò bọ́ wọn,+ wáìnì dídùn alára sì já a kulẹ̀.+  Wọn kì yóò máa bá a lọ ní gbígbé ilẹ̀ Jèhófà,+ Éfúráímù yóò sì padà sí Íjíbítì,+ wọn yóò sì máa jẹ ohun àìmọ́+ ní Ásíríà.  Wọn kì yóò máa bá a lọ láti da wáìnì jáde sí Jèhófà.+ Àwọn ẹbọ wọn kì yóò sì mú inú rẹ̀ dùn;+ wọ́n dà bí oúnjẹ àwọn àkókò ìṣọ̀fọ̀+ fún wọn; gbogbo àwọn tí ó bá jẹ ẹ́ yóò sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin. Nítorí oúnjẹ wọn wà fún ọkàn ara wọn; kì yóò wọ inú ilé Jèhófà.+  Kí ni ẹ̀yin yóò ṣe ní ọjọ́ ìpàdé àti ní ọjọ́ àjọyọ̀ Jèhófà?+  Nítorí, wò ó! wọn yóò ní láti lọ nítorí ìfiṣèjẹ.+ Íjíbítì alára yóò kó wọn jọpọ̀;+ Mémúfísì,+ ní tirẹ̀, yóò sin wọ́n. Ní ti àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra wọn ti fàdákà, àwọn èsìsì gan-an ni yóò gbà wọ́n;+ àwọn igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún-lára yóò wà nínú àwọn àgọ́ wọn.+  “Àwọn ọjọ́ ìfúnni ní àfiyèsí yóò dé;+ àwọn ọjọ́ ẹ̀san yíyẹ yóò dé.+ Àwọn tí ó wà ní Ísírẹ́lì yóò mọ̀ nípa rẹ̀.+ Wòlíì yóò ya òmùgọ̀,+ ọkùnrin tí ó ní àgbéjáde onímìísí yóò ya wèrè ní tìtorí ọ̀pọ̀ yanturu ìṣìnà rẹ,+ kèéta pàápàá yóò pọ̀ yanturu.”  Olùṣọ́+ Éfúráímù wà pẹ̀lú Ọlọ́run mi.+ Ní ti wòlíì,+ pańpẹ́ pẹyẹpẹyẹ wà ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀;+ kèéta wà ní ilé Ọlọ́run rẹ̀.  Wọ́n ti lọ jinlẹ̀-jinlẹ̀ ní mímú ìparun wá,+ bí ti àwọn ọjọ́ Gíbíà.+ Òun yóò rántí ìṣìnà wọn;+ yóò fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní àfiyèsí. 10  “Bí àwọn èso àjàrà ní aginjù ni mo rí Ísírẹ́lì.+ Bí ọ̀pọ̀tọ́ àkọ́kọ́ tí ó wà lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ ni mo rí àwọn baba ńlá yín.+ Àwọn fúnra wọn wọlé tọ Báálì ti Péórù,+ wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti ya ara wọn sí mímọ́ fún ohun tí ń tini lójú,+ wọ́n sì wá di ìríra bí ohun ìfẹ́ wọn.+ 11  Ní ti Éfúráímù, bí ẹ̀dá tí ń fò ni ògo wọn ṣe fò lọ,+ tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi sí bíbímọ, kò sì sí ikùn tí ó lóyún, kò sì sí ìlóyún.+ 12  Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà, dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ ọmọ, tí kò fi ní sí ọkùnrin kankan;+ nítorí pé—ègbé ni fún wọn pẹ̀lú nígbà tí mo bá yí padà kúrò lọ́dọ̀ wọn!+ 13  Éfúráímù, tí mo ti rí gẹ́gẹ́ bí Tírè tí a gbìn sí ilẹ̀ ìjẹko,+ àní Éfúráímù ni a ti yàn tẹ́lẹ̀ fún mímú àwọn ọmọ rẹ̀ jáde àní fún olùpani.”+ 14  Jèhófà, fún wọn ní ohun tí ìwọ yóò fún wọn.+ Fún wọn ní ilé ọlẹ̀+ tí ń fa ìṣẹ́nú àti àwọn ọmú pẹlẹbẹ gbígbẹ. 15  “Gbogbo ìwà búburú wọn ṣẹlẹ̀ ní Gílígálì,+ nítorí ibẹ̀ ni ó ti wá di pé mo kórìíra wọn.+ Ní tìtorí ìbánilo wọn lọ́nà ibi, èmi yóò lé wọn lọ kúrò ní ilé mi.+ Èmi kì yóò máa bá a lọ láti nífẹ̀ẹ́ wọn.+ Gbogbo ọmọ aládé wọn ní ń ṣagídí.+ 16  A óò ṣá Éfúráímù balẹ̀.+ Gbòǹgbò wọn gan-an yóò gbẹ dànù.+ Wọn kì yóò so èso kankan.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n bí ọmọ, àní ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra ikùn wọn+ ni èmi yóò fi ikú pa dájúdájú.” 17  Ọlọ́run mi+ yóò kọ̀ wọ́n, nítorí tí wọn kò fetí sí i,+ wọn yóò sì di ìsáǹsá láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé