Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Hóséà 7:1-16

7  “Ní ìgbà tí èmi ì bá mú Ísírẹ́lì+ lára dá, ìṣìnà Éfúráímù pẹ̀lú ni a tú síta+ ní ti tòótọ́, àti àwọn ohun búburú Samáríá;+ nítorí wọ́n ti fi èké+ ṣe ìwà hù, olè pàápàá sì wọlé; ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí rọ́ gììrì lóde+ ní ti tòótọ́.  Wọn kò sì sọ fún ọkàn-àyà+ wọn pé gbogbo ìwà búburú wọn ni èmi yóò rántí+ dájúdájú. Wàyí o, ìbánilò wọn ti yí wọn ká.+ Wọ́n ti wá wà ní iwájú mi.+  Nípa ìwà búburú wọn, wọ́n mú kí ọba yọ̀, àti pé, nípa ẹ̀tàn wọn, àwọn ọmọ aládé yọ̀.+  Gbogbo wọ́n jẹ́ panṣágà,+ bí ìléru tí olùṣe búrẹ́dì dá kí ó máa jó, ẹni tí ó ṣíwọ́ kíkoná lẹ́yìn pípo àpòrọ́ títí ó fi di wíwú.  Ní ọjọ́ ọba wa, àwọn ọmọ aládé ti mú ara wọn ṣàìsàn+—ìhónú wà nítorí wáìnì.+ Ó ti na ọwọ́ rẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ti àwọn afiniṣẹ̀sín.  Nítorí wọ́n ti mú ọkàn-àyà wọn sún mọ́ tòsí bí ẹni pé síbi ìléru;+ ó ń jó nínú wọn.+ Oorun ni olùṣe búrẹ́dì wọn ń sùn láti òru mọ́jú; ní òwúrọ̀, ìléru náà ń jó bí iná tí ń jó fòfò.+  Wọ́n gbóná, gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí ìléru, wọ́n sì jẹ àwọn onídàájọ́ wọn run ní ti tòótọ́. Gbogbo ọba wọn ti ṣubú;+ kò sí ìkankan lára wọn tí ó ké pè mí.+  “Ní ti Éfúráímù, òun gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́+ àwọn ènìyàn náà. Éfúráímù alára ti di àkàrà ribiti tí a kò yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kejì padà.+  Àwọn àjèjì ti jẹ agbára rẹ̀ tán,+ òun fúnra rẹ̀ kò sì mọ̀ nípa rẹ̀.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ewú pàápàá ti di funfun lórí rẹ̀, ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ kò mọ̀. 10  Ìgbéraga Ísírẹ́lì sì ti jẹ́rìí kò ó lójú,+ wọn kò sì tíì padà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wọn,+ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò wá a nítorí gbogbo èyí.+ 11  Éfúráímù sì wá dà bí òpè àdàbà+ tí kò ní ọkàn-àyà.+ Wọ́n ti pe Íjíbítì;+ wọ́n ti lọ sí Ásíríà.+ 12  “Ọ̀nà yòówù tí wọn ì báà lọ, èmi yóò na àwọ̀n+ mi lé wọn. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run ni èmi yóò mú wọn sọ̀ kalẹ̀.+ Èmi yóò bá wọn wí ní ìbámu pẹ̀lú ìròyìn tí ó dé àpéjọ wọn.+ 13  Ègbé ni fún wọn,+ nítorí wọ́n ti sá lọ kúrò lọ́dọ̀ mi!+ Kí a fi wọ́n ṣe ìjẹ, nítorí pé wọ́n ti ré ìlànà mi kọjá! Èmi fúnra mi sì tẹ̀ síwájú láti tún wọn rà padà,+ ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn ti pa irọ́ mọ́ èmi gan-an.+ 14  Wọn kò sì fi ọkàn-àyà wọn+ ké pè mí fún ìrànlọ́wọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń hu ṣáá lórí ibùsùn wọn. Ní tìtorí ọkà wọn àti wáìnì dídùn, wọ́n ń fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri;+ wọ́n ń bá a nìṣó ní kíkẹ̀yìn sí mi.+ 15  Èmi, ní tèmi, sì bá wọn wí;+ mo fún apá+ wọn lókun, ṣùgbọ́n wọ́n ń bá a nìṣó ní pípète-pèrò ohun tí ó burú sí mi.+ 16  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí padà, kì í ṣe sí ohunkóhun tí ó ga sí i;+ wọ́n ti dà bí ọrun dídẹ̀.+ Àwọn ọmọ aládé wọn yóò tipa idà ṣubú nítorí ìdálẹ́bi ahọ́n wọn.+ Èyí ni yóò jẹ́ ẹ̀sín tí a ó fi wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Íjíbítì.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé