Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Hóséà 6:1-11

6  “Ẹ wá, ẹ̀yin ènìyàn, ẹ sì jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Jèhófà,+ nítorí òun fúnra rẹ̀ ti fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,+ ṣùgbọ́n òun yóò mú wa lára dá.+ Ó ń bá a nìṣó ní kíkọlù, ṣùgbọ́n òun yóò di ọgbẹ́ wa.+  Òun yóò sọ wá di ààyè lẹ́yìn ọjọ́+ méjì. Ní ọjọ́ kẹta, òun yóò mú kí a dìde, àwa yóò sì wà láàyè níwájú rẹ̀.+  Àwa yóò sì mọ̀, a óò lépa láti mọ Jèhófà.+ Gẹ́gẹ́ bí ọ̀yẹ̀,+ ìjáde lọ rẹ̀ fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+ Òun yóò sì wọlé sọ́dọ̀ wa bí ọ̀yamùúmùú òjò;+ bí òjò ìgbà ìrúwé tí ń mú ilẹ̀ rin gbingbin.”+  “Kí ni èmi yóò ṣe sí ọ, ìwọ Éfúráímù? Kí ni èmi yóò ṣe sí ọ, ìwọ Júdà,+ nígbà tí inú-rere yín onífẹ̀ẹ́ dà bí àwọsánmà òwúrọ̀ àti gẹ́gẹ́ bí ìrì tí ń tètè lọ?  Ìdí nìyẹn tí èmi yóò fi tipasẹ̀ àwọn wòlíì+ ké wọn lulẹ̀; èmi yóò fi àwọn àsọjáde ẹnu+ mi pa wọ́n. Ìdájọ́ tí yóò wá sórí rẹ yóò sì dà bí ìmọ́lẹ̀ tí ń jáde lọ.+  Nítorí pé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ni mo ní inú dídùn+ sí, kì í sì í ṣe ẹbọ;+ àti ìmọ̀ nípa Ọlọ́run dípò àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun.+  Ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn, gẹ́gẹ́ bí ará ayé, ti tẹ májẹ̀mú lójú.+ Ibẹ̀ ni wọ́n ti ṣe àdàkàdekè sí mi.+  Gílíádì+ jẹ́ ìlú àwọn apanilára; ojú ẹsẹ̀ wọn jẹ́ ẹ̀jẹ̀.+  Àti gẹ́gẹ́ bí ní lílúgọ de ènìyàn,+ ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà jẹ́ ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí.+ Ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà ni wọ́n ti ń ṣìkà pànìyàn ní Ṣékémù,+ nítorí pé kìkì ìwà àìníjàánu ni wọ́n ń bá a lọ ní híhù.+ 10  Mo ti rí ohun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀+ nínú ilé Ísírẹ́lì. Àgbèrè wà níbẹ̀ níhà ọ̀dọ̀ Éfúráímù.+ Ísírẹ́lì ti sọ ara rẹ̀+ di ẹlẹ́gbin. 11  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìwọ Júdà, ìkórè ni a ti gbé kalẹ̀ fún ọ, nígbà tí mo bá kó àwọn òǹdè nínú àwọn ènìyàn mi jọ padà.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé