Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Hóséà 5:1-15

5  “Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin àlùfáà,+ ẹ sì fiyè sílẹ̀, ilé Ísírẹ́lì, àti ẹ̀yin, ilé ọba,+ ẹ fi etí sí i, nítorí pé ẹ̀yin ni ẹ fẹ́ gba ìdájọ́; nítorí pé ẹ ti di pańpẹ́+ fún Mísípà àti gẹ́gẹ́ bí àwọ̀n tí a nà bo Tábórì.+  Àwọn tí ó yapa sì ti lọ jinlẹ̀-jinlẹ̀+ sínú iṣẹ́ ìpakúpa, mo sì jẹ́ agbani-níyànjú fún gbogbo wọn.+  Èmi gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan mọ Éfúráímù,+ Ísírẹ́lì alára kò sì pa mọ́ fún mi.+ Nítorí nísinsìnyí, Éfúráímù, ìwọ ti ṣe sí àwọn obìnrin bí aṣẹ́wó;+ Ísírẹ́lì ti sọ ara rẹ̀+ di ẹlẹ́gbin.  Àwọn ìbánilò wọn kò fàyè gba pípadà sọ́dọ̀ Ọlọ́run wọn,+ nítorí pé ẹ̀mí àgbèrè+ wà ní àárín wọn; Jèhófà alára ni wọn kò sì kà sí.+  Ìgbéraga Ísírẹ́lì sì ti jẹ́rìí kò ó lójú;+ Ísírẹ́lì àti Éfúráímù alára ni a sì mú kọsẹ̀ nínú ìṣìnà wọn.+ Bákan náà, Júdà ti kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn.+  Ti àwọn ti agbo ẹran wọn àti ọ̀wọ́ ẹran wọn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ láti wá Jèhófà, ṣùgbọ́n wọn kò rí i.+ Ó ti lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn.  Wọ́n ti ṣe àdàkàdekè+ sí Jèhófà fúnra rẹ̀, nítorí wọ́n ti bí àwọn àjèjì ọmọ.+ Wàyí o, oṣù yóò jẹ wọ́n run pẹ̀lú ìpín wọn.+  “Ẹ fun ìwo+ ní Gíbíà,+ àti kàkàkí ní Rámà! Ẹ kígbe ogun ní Bẹti-áfénì+—tẹ̀ lé ọ, ìwọ Bẹ́ńjámínì!+  Ìwọ Éfúráímù, ohun ìyàlẹ́nu lásán-làsàn ni ìwọ yóò dà ní ọjọ́ ìbáwí mímúná.+ Láàárín àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni èmi ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ aṣeégbẹ́kẹ̀lé+ di mímọ̀. 10  Àwọn ọmọ aládé Júdà rí gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ń sún ààlà+ sẹ́yìn. Orí wọn ni èmi yóò da ìbínú kíkan mi jáde sí gan-an gẹ́gẹ́ bí omi. 11  A ni Éfúráímù lára, a fi ìdájọ́ òdodo tẹ̀ ẹ́ rẹ́,+ nítorí ó ti dáwọ́ lé e láti tọ elénìní rẹ̀+ lẹ́yìn. 12  Mo sì dà bí òólá+ sí Éfúráímù àti gẹ́gẹ́ bí ìjẹrà gẹ́lẹ́ sí ilé Júdà. 13  “Éfúráímù sì wá rí àìsàn rẹ̀, Júdà sì rí egbò rẹ̀.+ Éfúráímù sì tẹ̀ síwájú láti lọ sí Ásíríà,+ ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá.+ Ṣùgbọ́n ẹni yẹn pàápàá kò lè mú yín lára dá,+ kò sì lè fi ìwòsàn èyíkéyìí mú egbò kúrò lára yín.+ 14  Nítorí èmi yóò dà bí ẹgbọrọ kìnnìún sí Éfúráímù+ àti bí ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ sí ilé Júdà. Èmi, èmi fúnra mi yóò fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, èmi yóò lọ, èmi yóò sì gbé lọ, kì yóò sì sí olùdáǹdè.+ 15  Èmi yóò lọ, dájúdájú, èmi yóò padà sí ipò mi títí di ìgbà tí wọn yóò ru ẹ̀bi wọn;+ dájúdájú, wọn yóò sì wá ojú mi.+ Nígbà tí wọ́n bá wà nínú hílàhílo,+ wọn yóò wá mi.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé