Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Hóséà 4:1-19

4  Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí Jèhófà ní ẹjọ́ kan pẹ̀lú àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,+ nítorí kò sí òtítọ́+ tàbí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tàbí ìmọ̀ nípa Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.+  Gígégùn-ún+ àti ṣíṣe ẹ̀tàn+ àti ìṣìkàpànìyàn+ àti jíjalè+ àti ṣíṣe panṣágà+ ti bẹ́ sílẹ̀, ìtàjẹ̀sílẹ̀+ sì ti kan ìtàjẹ̀sílẹ̀ mìíràn.  Ìdí nìyẹn tí ilẹ̀ náà yóò fi ṣọ̀fọ̀,+ tí gbogbo àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò sì ní láti rẹ̀ dànù pẹ̀lú ẹranko inú pápá àti pẹ̀lú ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run, àní àwọn ẹja òkun pàápàá ni a óò kó jọ nínú ikú.+  “Bí ó ti wù kí ó rí, kí ọkùnrin kankan má ṣàríyànjiyàn,+ bẹ́ẹ̀ ni kí ọkùnrin kan má fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, níwọ̀n bí àwọn ènìyàn rẹ ti dà bí àwọn tí ń bá àlùfáà+ ṣàríyànjiyàn.  Dájúdájú, ìwọ yóò sì kọsẹ̀ ní ìgbà ọ̀sán,+ wòlíì pàápàá yóò kọsẹ̀ pẹ̀lú rẹ, bí ti òru.+ Èmi yóò sì pa ìyá rẹ lẹ́nu mọ́+ dájúdájú.  Àwọn ènìyàn mi ni a ó pa lẹ́nu mọ́ dájúdájú, nítorí pé kò sí ìmọ̀.+ Nítorí pé ìmọ̀ ni ìwọ alára ti kọ̀,+ èmi pẹ̀lú yóò kọ̀ ọ́ ní sísìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún mi;+ àti nítorí pé ìwọ ń gbàgbé òfin Ọlọ́run rẹ+ ṣáá, èmi yóò gbàgbé àwọn ọmọ rẹ, àní èmi.+  Bí ògìdìgbó wọ́n ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ti ṣẹ̀ sí mi+ tó. Ògo tèmi ni wọ́n ti fi ṣe pàṣípààrọ̀ fún àbùkù+ lásán-làsàn.  Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi ni wọ́n ń jẹ run, wọ́n sì ń gbé ọkàn+ wọn sókè ṣáá sí ìṣìnà wọn.  “Dájúdájú, yóò sì wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn náà gẹ́gẹ́ bí yóò ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn àlùfáà;+ dájúdájú, èmi yóò sì béèrè ìjíhìn lọ́wọ́ wọn fún ọ̀nà wọn;+ ìbánilò wọn ni èmi yóò sì mú padà wá sórí wọn.+ 10  Wọn yóò sì jẹun ní ti tòótọ́, ṣùgbọ́n wọn kì yóò yó.+ Ní ti tòótọ́, wọn yóò ṣe sí àwọn obìnrin bí aṣẹ́wó; ṣùgbọ́n wọn kì yóò pọ̀ sí i,+ nítorí pé wọ́n ti dẹ́kun fífún Jèhófà alára+ ní àfiyèsí. 11  Àgbèrè àti wáìnì àti wáìnì dídùn ni ohun tí ń gba ète rere kúrò.+ 12  Àwọn ènìyàn mi ń bá a nìṣó ní ṣíṣe ìwádìí+ lọ́dọ̀ òrìṣà wọn tí a fi igi ṣe,+ ọ̀pá ọwọ́ wọn sì ń bá a lọ ní sísọ fún wọn; nítorí pé ẹ̀mí àgbèrè gan-an ti mú kí wọ́n rìn gbéregbère lọ,+ àti nípasẹ̀ àgbèrè, wọ́n jáde kúrò lábẹ́ Ọlọ́run wọn.+ 13  Orí àwọn òkè ńlá ni wọ́n ti ń rúbọ,+ orí àwọn òkè kéékèèké ni wọ́n sì ti ń rú èéfín+ ẹbọ, lábẹ́ igi ràgàjì àti igi tórásì àti igi ńlá, nítorí pé ibòji rẹ̀ dára.+ Ìdí nìyẹn tí àwọn ọmọbìnrin yín fi ń ṣe àgbèrè, tí aya àwọn ọmọ yín sì ń ṣe panṣágà. 14  “Èmi kì yóò béèrè ìjíhìn lọ́wọ́ àwọn ọmọbìnrin yín nítorí pé wọ́n ṣe àgbèrè, àti lọ́wọ́ aya àwọn ọmọ yín nítorí pé wọ́n ṣe panṣágà. Nítorí pé, ní ti àwọn ọkùnrin wọnnì, àwọn aṣẹ́wó ni wọ́n ya ara wọn sápá kan fún,+ wọ́n sì ń bá àwọn kárùwà+ obìnrin inú tẹ́ńpìlì rúbọ; àwọn ènìyàn tí kò lóye+ ni a ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀. 15  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ń ṣe àgbèrè, ìwọ Ísírẹ́lì,+ má ṣe jẹ́ kí Júdà jẹ̀bi,+ kí ẹ má sì ṣe wá sí Gílígálì,+ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má gòkè lọ sí Bẹti-áfénì+ tàbí kí ẹ búra pé ‘Bí Jèhófà ti ń bẹ!’+ 16  Nítorí, gẹ́gẹ́ bí abo màlúù alágídí,+ Ísírẹ́lì ti di alágídí. Ìsinsìnyí ha ni Jèhófà yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn gẹ́gẹ́ bí ẹgbọrọ àgbò ní ibi aláyè gbígbòòrò? 17  Éfúráímù ni a ti so pọ̀ mọ́ àwọn òrìṣà.+ Jọ̀wọ́ rẹ̀ sí!+ 18  Níwọ̀n bí ọtí bíà àlìkámà wọ́n ti lọ,+ dájúdájú, wọ́n ti ṣe sí obìnrin bí aṣẹ́wó.+ Àwọn tí ó dáàbò bò ó+ nífẹ̀ẹ́ àbùkù+ dájúdájú. 19  Ẹ̀fúùfù ti pọ́n ọn sínú àwọn ìyẹ́ apá rẹ̀.+ Àwọn ẹbọ wọn+ yóò sì kó ìtìjú bá wọn.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé