Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Hóséà 3:1-5

3  Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún mi pé: “Lọ lẹ́ẹ̀kan sí i, nífẹ̀ẹ́ obìnrin kan tí alábàákẹ́gbẹ́+ kan nífẹ̀ẹ́, tí ó sì ń ṣe panṣágà, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ti ìfẹ́ Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ nígbà tí wọ́n yí padà sí àwọn ọlọ́run mìíràn,+ tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ìṣù èso àjàrà gbígbẹ.”+  Mo sì tẹ̀ síwájú láti rà á fún ara mi ní ẹyọ+ fàdákà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti òṣùwọ̀n hómérì ọkà bálì àti ìlàjì òṣùwọ̀n hómérì ọkà bálì.  Nígbà náà ni mo wí fún un pé: “Ìwọ yóò máa gbé ní jíjẹ́ tèmi+ fún ọjọ́ púpọ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè,+ ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ wá jẹ́ ti ọkùnrin mìíràn;+ èmi pẹ̀lú yóò sì jẹ́ tìrẹ dájúdájú.”  Ó jẹ́ nítorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò máa gbé fún ọjọ́ púpọ̀ láìsí ọba+ àti láìsí ọmọ aládé àti láìsí ẹbọ+ àti láìsí ọwọ̀n àti láìsí éfódì+ àti ère tẹ́ráfímù.+  Lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò padà wá, wọn yóò sì wá Jèhófà Ọlọ́run wọn+ dájúdájú, wọ́n yóò sì wá Dáfídì ọba wọn;+ dájúdájú, wọn yóò sì fi ìgbọ̀npẹ̀pẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jèhófà+ àti sínú oore rẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé