Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Hóséà 13:1-16

13  “Nígbà tí Éfúráímù sọ̀rọ̀, ìwárìrì wà; òun fúnra rẹ̀ tẹ̀wọ̀n ní Ísírẹ́lì.+ Ṣùgbọ́n ó bẹ̀rẹ̀ sí jẹ̀bi ní ti Báálì,+ ó sì kú.+  Wàyí o, wọ́n dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n sì ṣe ère dídà fún ara wọn láti inú fàdákà wọn,+ àwọn òrìṣà ní ìbámu pẹ̀lú òye wọn,+ gbogbo rẹ̀,+ iṣẹ́ àwọn oníṣẹ́ ọnà. Wọ́n ń sọ fún wọn pé, ‘Kí àwọn olùrúbọ tí wọ́n jẹ́ ènìyàn fi ẹnu ko àwọn ọmọ màlúù lásán-làsàn lẹ́nu.’+  Nítorí náà, wọn yóò dà bí àwọsánmà òwúrọ̀+ àti bí ìrì tí ń tètè lọ; bí ìyàngbò tí ìjì gbé lọ kúrò ní ilẹ̀ ìpakà+ àti bí èéfín kúrò nínú ihò òrùlé.  “Ṣùgbọ́n èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ láti ilẹ̀ Íjíbítì,+ kò sì sí Ọlọ́run kankan bí kò ṣe èmi tí ìwọ ti mọ̀; kò sì sí olùgbàlà kankan bí kò ṣe èmi.+  Èmi fúnra mi mọ̀ ọ́ ní aginjù,+ ní ilẹ̀ àwọn ibà.+  Ní ìbámu pẹ̀lú pápá ìjẹko wọn, wọ́n sì yó.+ Wọ́n yó, ọkàn-àyà wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ga.+ Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi gbàgbé mi.+  Èmi yóò sì dà bí ẹgbọrọ kìnnìún sí wọn.+ Èmi yóò máa wò bí àmọ̀tẹ́kùn tí ó wà lẹ́bàá ọ̀nà.+  Èmi yóò yọ sí wọn bí béárì tí ó ti pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀,+ èmi yóò sì la àkámọ́ ọkàn-àyà wọn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Èmi yóò sì jẹ wọ́n run níbẹ̀ bí kìnnìún;+ ẹranko ẹhànnà inú pápá yóò fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.+  Dájúdájú, yóò run ọ́,+ ìwọ Ísírẹ́lì, nítorí pé ó jẹ́ ní ìlòdìsí mi, ní ìlòdìsí olùrànlọ́wọ́ rẹ.+ 10  “Ibo wá ni ọba rẹ wà, kí ó lè gbà ọ́ là nínú gbogbo ìlú ńlá rẹ,+ àti àwọn onídàájọ́ rẹ, àwọn tí o sọ nípa wọn pé, ‘Fún mi ní ọba àti àwọn ọmọ aládé’?+ 11  Mo tẹ̀ síwájú láti fún ọ ní ọba nínú ìbínú mi,+ èmi yóò sì mú un kúrò nínú ìbínú mi kíkan.+ 12  “A pọ́n ìṣìnà Éfúráímù, a to ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pa mọ́.+ 13  Ìroragógó ìrọbí ti obìnrin tí ń bímọ ni yóò dé bá a.+ Ó jẹ́ ọmọ tí kò gbọ́n,+ nítorí pé ní àsìkò, kì yóò dúró jẹ́ẹ́ nígbà ìjáde wá àwọn ọmọ láti inú ilé ọlẹ̀.+ 14  “Èmi yóò tún wọn rà padà láti ọwọ́ Ṣìọ́ọ̀lù;+ èmi yóò mú wọn padà láti inú ikú.+ Ìwọ Ikú,+ ìtani rẹ dà? Ìwọ Ṣìọ́ọ̀lù,+ ìpanirun rẹ dà? A ó fi ìyọ́nú fúnra rẹ̀ pa mọ́ kúrò ní ojú mi.+ 15  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé òun fúnra rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọ̀gbìn esùsú, bá fi jíjẹ́ eléso hàn,+ ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn, ẹ̀fúùfù Jèhófà, yóò dé.+ Aginjù ni ó ti ń gòkè bọ̀, yóò sì gbẹ kànga rẹ̀ táútáú, yóò sì fa ìsun rẹ̀ gbẹ.+ Ẹni yẹn yóò sì kó ìṣúra gbogbo àwọn ohun èlò fífani-lọ́kàn-mọ́ra ní ìkógun.+ 16  “A ó ka Samáríà sí ẹlẹ́bi,+ nítorí pé ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ní ti tòótọ́ sí Ọlọ́run rẹ̀.+ Wọn yóò tipa idà ṣubú.+ Àwọn ọmọ wọn ni a óò fọ́ túútúú,+ àwọn aboyún wọn pàápàá ni a ó sì la inú wọn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé