Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Hóséà 12:1-14

12  “Éfúráímù ń fi ẹ̀fúùfù+ ṣe oúnjẹ jẹ, ó sì ń lépa ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+ Ó sọ irọ́ pípa àti ìfiṣèjẹ di púpọ̀.+ Wọ́n sì bá Ásíríà dá májẹ̀mú,+ wọ́n sì gbé òróró lọ sí Íjíbítì.  “Jèhófà sì ní ẹjọ́ láti bá Júdà+ ṣe, àní láti béèrè fún ìjíhìn lọ́wọ́ Jékọ́bù gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀nà rẹ̀;+ òun yóò san án padà+ fún un gẹ́gẹ́ bí àwọn ìbánilò rẹ̀.  Nínú ikùn, ó gbá arákùnrin rẹ̀ mú ní gìgísẹ̀,+ ó sì fi okun rẹ̀ alágbára gíga bá Ọlọ́run wọ̀jà.+  Ó sì ń bá a nìṣó láti bá áńgẹ́lì wọ̀jà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó borí.+ Ó sunkún, kí ó lè fi taratara bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere fún ara rẹ̀.”+ Bẹ́tẹ́lì ni Ó ti rí i,+ ibẹ̀ ni Ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí bá wa sọ̀rọ̀.+  Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ Jèhófà sì ni ìrántí rẹ̀.+  “Àti ní ti ìwọ, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run rẹ ni kí o padà sí,+ ní pípa inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ àti ìdájọ́ òdodo mọ́;+ kí o sì máa ní ìrètí nínú Ọlọ́run rẹ nígbà gbogbo.+  Ní ti oníṣòwò náà, àwọn òṣùwọ̀n ẹ̀tàn+ wà ní ọwọ́ rẹ̀; ó nífẹ̀ẹ́ sí líluni ní jìbìtì.+  Éfúráímù sì ń sọ pé, ‘Ní tòótọ́, mo ti di ọlọ́rọ̀;+ mo ti rí ohun níníyelórí fún ara mi.+ Ní ti gbogbo làálàá mi, wọn kì yóò rí ìṣìnà kankan tí ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,+ níhà ọ̀dọ̀ mi.’  “Ṣùgbọ́n èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ láti ilẹ̀ Íjíbítì wá.+ Síbẹ̀, èmi yóò mú kí o máa gbé nínú àwọn àgọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ ti àkókò tí a yàn kalẹ̀. 10  Mo sì bá àwọn wòlíì+ sọ̀rọ̀, èmi fúnra mi sì sọ àwọn ìran di púpọ̀, mo sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣe àwọn àkàwé+ láti ọwọ́ àwọn wòlíì. 11  “Ohun abàmì,+ àti àìṣòtítọ́,+ ti ṣẹlẹ̀ ní Gílíádì. Wọ́n ti fi àwọn akọ màlúù+ pàápàá rúbọ ní Gílígálì. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn pẹpẹ wọn dà bí ìtòjọpelemọ àwọn òkúta ní aporo pápá gbalasa.+ 12  Jékọ́bù sì tẹ̀ síwájú láti fẹsẹ̀ fẹ lọ sí pápá Síríà,+ Ísírẹ́lì+ sì ń bá a nìṣó ní sísìn nítorí aya,+ àti nítorí aya, ó ń ṣọ́ àgùntàn.+ 13  Jèhófà sì tipasẹ̀ wòlíì kan mú Ísírẹ́lì gòkè wá láti Íjíbítì,+ a sì fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ nípasẹ̀ wòlíì kan.+ 14  Éfúráímù ṣokùnfà ìmúnibínú dé orí ìkorò,+ ó sì fi ìtàjẹ̀sílẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ sórí ara rẹ̀,+ Ọ̀gá rẹ̀ Atóbilọ́lá yóò sì san ẹ̀gàn rẹ̀ padà fún un.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé