Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Hóséà 11:1-12

11  “Nígbà tí Ísírẹ́lì jẹ́ ọmọdékùnrin, nígbà náà, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ láti Íjíbítì ni mo sì ti pe ọmọkùnrin mi.+  “Wọ́n pè wọ́n.+ Dé àyè kan náà yẹn ni wọ́n lọ kúrò níwájú wọn.+ Àwọn ère Báálì ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ sí,+ àwọn ère fífín sì ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rú èéfín+ ẹbọ sí.  Ṣùgbọ́n ní tèmi, mo kọ́ Éfúráímù ní ìrìn,+ ní gbígbé wọn sí apá mi;+ wọn kò sì mọ̀ pé mo ti mú wọn lára dá.+  Mo ń bá a nìṣó láti fi àwọn ìjàrá ará ayé fà wọ́n, pẹ̀lú àwọn okùn ìfẹ́,+ tí ó fi jẹ́ pé, sí wọn, mo dà bí àwọn tí ó gbé àjàgà kúrò ní páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn,+ lẹ́sọ̀lẹsọ̀ sì ni mo gbé oúnjẹ wá fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.+  Òun kì yóò padà sí ilẹ̀ Íjíbítì, ṣùgbọ́n Ásíríà ni yóò jẹ́ ọba rẹ̀,+ nítorí pé wọ́n kọ̀ láti padà.+  Idà yóò sì máa fì yí ká kíkankíkan ní àwọn ìlú ńlá rẹ̀+ dájúdájú, yóò sì fi òpin sí àwọn ọ̀pá gbọọrọ rẹ̀, yóò sì jẹ run+ nítorí àwọn ète wọn.+  Àwọn ènìyàn mi sì ń tẹ̀ sí àìṣòótọ́ sí mi.+ Wọ́n pè é sókè; kò sí ẹyọ ẹnì kan tí ó dìde.  “Èmi yóò ha ṣe jọ̀wọ́ rẹ lọ́wọ́, ìwọ Éfúráímù?+ Èmi yóò ha ṣe fà ọ́ léni lọ́wọ́, ìwọ Ísírẹ́lì?+ Èmi yóò ha ṣe gbé ọ kalẹ̀ bí Ádímà?+ Èmi yóò ha ṣe gbé ọ kalẹ̀ bí Sébóíímù?+ Ọkàn-àyà mi ti yí padà nínú mi;+ lẹ́sẹ̀ kan náà, ìyọ́nú mi ti gbóná.  Èmi kì yóò tú ìbínú mi jíjófòfò jáde.+ Èmi kì yóò tún run Éfúráímù mọ́,+ nítorí Ọlọ́run ni mí,+ èmi kì í sì í ṣe ènìyàn, Ẹni Mímọ́ láàárín rẹ;+ èmi kì yóò sì wá pẹ̀lú ìrusókè. 10  Wọn yóò máa tẹ̀ lé Jèhófà.+ Bí kìnnìún, òun yóò ké ramúramù;+ nítorí òun fúnra rẹ̀ yóò ké ramúramù,+ àwọn ọmọ yóò sì fi ìwárìrì wá láti ìwọ̀-oòrùn.+ 11  Gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ, wọn yóò fi ìwárìrì jáde wá láti Íjíbítì,+ àti gẹ́gẹ́ bí àdàbà, láti ilẹ̀ Ásíríà;+ dájúdájú, èmi yóò sì mú kí wọ́n máa gbé ní ilé wọn,” ni àsọjáde Jèhófà.+ 12  “Éfúráímù ti fi irọ́ pípa yí mi ká,+ ilé Ísírẹ́lì sì ti fi ẹ̀tàn yí mi ká. Ṣùgbọ́n Júdà ṣì ń bá Ọlọ́run rìn kiri,+ òun sì jẹ́ aṣeégbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ Jù Lọ.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé