Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Hóséà 10:1-15

10  “Àjàrà+ jíjẹrà bàjẹ́ ni Ísírẹ́lì. Ó ń bá a lọ láti mú èso jáde fún ara rẹ̀.+ Bí èso rẹ̀ ti pọ̀ yanturu tó ni ó ṣe sọ àwọn pẹpẹ rẹ̀+ di púpọ̀ tó. Bí ohun rere ilẹ̀ rẹ̀ ti tó ni wọ́n ṣe gbé àwọn ọwọ̀n rere nà ró tó.+  Ọkàn-àyà wọ́n ti di alágàbàgebè;+ nísinsìnyí wọn yóò jẹ̀bi. “Ẹnì kan wà tí yóò fọ́ àwọn pẹpẹ wọn; yóò fi ọwọ̀n wọn ṣe ìjẹ.+  Nítorí nísinsìnyí wọn yóò wí pé, ‘Àwa kò ní ọba,+ nítorí a kò bẹ̀rù Jèhófà. Àti ní ti ọba, kí ni yóò ṣe fún wa?’  “Wọ́n sọ àwọn ọ̀rọ̀, ní bíbúra èké,+ ní dídá májẹ̀mú;+ ìdájọ́ sì ti rú jáde gẹ́gẹ́ bí ọ̀gbìn onímájèlé ní àwọn aporo pápá gbalasa.+  Jìnnìjìnnì yóò bá àwọn olùgbé Samáríà nítorí ọmọ màlúù òrìṣà Bẹti-áfénì;+ nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ dájúdájú, àti àwọn àlùfáà rẹ̀ ti ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè tí ó ti máa ń kún fún ìdùnnú lórí rẹ̀, ní tìtorí ògo rẹ̀, nítorí pé yóò ti lọ sí ìgbèkùn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.+  Àní òun ni ẹnì kan yóò mú wá sí Ásíríà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọba ńlá.+ Ìtìjú ni ohun tí yóò bá+ Éfúráímù alára, ìmọ̀ràn+ rẹ̀ yóò sì mú ìtìjú bá Ísírẹ́lì.  Samáríà àti ọba rẹ̀ ni a ó pa lẹ́nu mọ́+ dájúdájú, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí ó ti dá gbọ́n-ún sí ojú omi.  Àwọn ibi gíga Bẹti-áfénì,+ ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì,+ ni a ó sì pa rẹ́ ráúráú ní ti tòótọ́. Ẹ̀gún àti òṣùṣú+ yóò hù jáde lórí pẹpẹ wọn.+ Àwọn ènìyàn yóò sì sọ fún àwọn òkè ńlá ní ti tòótọ́ pé, ‘Ẹ bò wá mọ́lẹ̀!’ àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, ‘Ẹ wó bò wá!’+  “Láti àwọn ọjọ́ Gíbíà+ ni ìwọ ti ṣẹ̀,+ ìwọ Ísírẹ́lì. Ibẹ̀ ni wọ́n dúró jẹ́ẹ́ sí. Ogun tí ó dojú kọ àwọn ọmọ àìṣòdodo kò lé wọn bá+ ní Gíbíà. 10  Nígbà tí ó bá jẹ́ ìfàsí-ọkàn mi, èmi yóò bá wọn wí pẹ̀lú.+ Àwọn ènìyàn yóò sì kó jọ lòdì sí wọn dájúdájú nígbà tí a bá so wọ́n pọ̀ mọ́ ìṣìnà wọn+ méjèèjì. 11  “Éfúráímù sì jẹ́ ẹgbọrọ abo màlúù tí a kọ́, tí ó nífẹ̀ẹ́ pípakà;+ èmi, ní tèmi, sì kọjá lọ́rùn rẹ̀ tí ó dára ní wíwò. Mo mú kí ẹnì kan gun Éfúráímù.+ Júdà ń túlẹ̀;+ Jékọ́bù ń fọ́ ògúlùtu+ fún un. 12  Ẹ fún irúgbìn fún ara yín ní òdodo;+ ẹ kárúgbìn ní ìbámu pẹ̀lú inú-rere-onífẹ̀ẹ́.+ Ẹ ro ilẹ̀ adárafọ́gbìn+ fún ara yín nígbà tí àkókò wà fún wíwá Jèhófà, títí yóò fi dé,+ tí yóò sì fún yín ní ìtọ́ni ní òdodo.+ 13  “Ẹ̀yin ti túlẹ̀ ìwà burúkú.+ Àìṣòdodo ni ohun tí ẹ̀yin ká.+ Ẹ ti jẹ èso ẹ̀tàn,+ nítorí tí o ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọ̀nà rẹ,+ nínú ògìdìgbó àwọn alágbára ńlá rẹ.+ 14  Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ sì ti dìde láàárín àwọn ènìyàn rẹ,+ gbogbo ìlú ńlá olódi rẹ ni a ó sì fi ṣe ìjẹ,+ gẹ́gẹ́ bí ìfiṣèjẹ láti ọwọ́ Ṣálímánì ti ilé Áríbélì, ní ọjọ́ ìjà ogun nígbà tí a fọ́ ìyá fúnra rẹ̀ túútúú lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀.+ 15  Báyìí ni ẹnì kan yóò ṣe sí yín dájúdájú, ìwọ Bẹ́tẹ́lì, nítorí ìwà búburú+ yín tí ó dé góńgó. Ní ọ̀yẹ̀, pípa ni a ó pa ọba Ísírẹ́lì lẹ́nu mọ́.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé