Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Hóséà 1:1-11

1  Ọ̀rọ̀ Jèhófà+ tí ó tọ Hóséà+ ọmọkùnrin Béérì wá ní àwọn ọjọ́+ Ùsáyà,+ Jótámù,+ Áhásì+ àti Hesekáyà,+ àwọn ọba Júdà, àti ní àwọn ọjọ́ Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Jóáṣì,+ ọba Ísírẹ́lì.  Ọ̀rọ̀ Jèhófà nípasẹ̀ Hóséà bẹ̀rẹ̀, Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Hóséà pé: “Lọ,+ mú àgbèrè aya àti àwọn ọmọ àgbèrè fún ara rẹ, nítorí pé nípasẹ̀ àgbèrè, ilẹ̀ yìí ti yí padà dájúdájú kúrò ní títọ Jèhófà+ lẹ́yìn.”  Ó sì lọ, ó fẹ́ Gómérì ọmọbìnrin Díbíláímù, ó sì lóyún, nígbà tí ó ṣe, ó bí ọmọkùnrin+ kan fún un.  Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún un pé: “Pe orúkọ rẹ̀ ní Jésíréélì,+ nítorí ní ìgbà díẹ̀ sí i, èmi yóò béèrè ìjíhìn fún ìtàjẹ̀sílẹ̀ Jésíréélì lọ́wọ́ ilé Jéhù,+ èmi yóò sì mú kí ìṣàkóso ọba ilé Ísírẹ́lì kásẹ̀ nílẹ̀.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé, èmi yóò ṣẹ́ ọrun+ Ísírẹ́lì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Jésíréélì.”  Ó sì lóyún ní ìgbà mìíràn, ó sì bí ọmọbìnrin kan. Ó sì ń bá a lọ láti sọ fún un pé: “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-rúhámà,+ nítorí èmi kì yóò tún fi àánú hàn sí ilé Ísírẹ́lì mọ́,+ nítorí pé kíkó ni èmi yóò kó wọn lọ.+  Ṣùgbọ́n èmi yóò fi àánú hàn sí ilé Júdà,+ dájúdájú, èmi yóò sì gbà wọ́n là nípasẹ̀ Jèhófà Ọlọ́run wọn;+ ṣùgbọ́n èmi kì yóò gbà wọ́n là nípasẹ̀ ọrun tàbí nípasẹ̀ idà tàbí nípasẹ̀ ogun, nípasẹ̀ àwọn ẹṣin tàbí àwọn ẹlẹ́ṣin.”+  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó já ọmú lẹ́nu Lo-rúhámà, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan.  Nítorí náà, Ó sọ pé: “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-ámì, nítorí ẹ kì í ṣe ènìyàn mi, èmi alára kì yóò sì jẹ́ tiyín. 10  “Iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò sì dà bí egunrín iyanrìn òkun tí a kò lè díwọ̀n tàbí ka iye+ rẹ̀. Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ní ibi tí a ti máa ń sọ fún wọn rí pé, ‘Ẹ kì í ṣe ènìyàn mi,’+ a ó sọ fún wọn pé, ‘Àwọn ọmọ Ọlọ́run alààyè.’+ 11  A ó sì kó àwọn ọmọ Júdà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọpọ̀ sínú ìṣọ̀kan,+ wọn yóò sì gbé olórí kan kalẹ̀ fún ara wọn ní ti tòótọ́, wọn yóò sì gòkè lọ kúrò ní ilẹ̀ náà,+ nítorí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jésíréélì+ yóò jẹ́.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé