Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Hébérù 9:1-28

9  Ní tirẹ̀, nígbà náà, májẹ̀mú ti ìṣáájú máa ń ní àwọn ìlànà ààtò iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀+ àti ibi mímọ́+ rẹ̀ ti ayé.  Nítorí a kọ́ ojúlé+ àgọ́ àkọ́kọ́ nínú èyí tí ọ̀pá fìtílà+ wà àti tábìlì+ pẹ̀lú àti ìfihàn àwọn ìṣù búrẹ́dì;+ a sì ń pè é ní “Ibi Mímọ́.”+  Ṣùgbọ́n lẹ́yìn aṣọ ìkélé kejì+ ni ojúlé àgọ́ tí a ń pè ní “Ibi Mímọ́ Jù Lọ”+ wà.  Èyí ní àwo+ tùràrí oníwúrà nínú àti àpótí májẹ̀mú+ tí a fi wúrà bò yí ká,+ nínú èyí tí ìṣà wúrà wà tí ó ní mánà+ àti ọ̀pá Áárónì tí ó rudi+ àti àwọn wàláà+ májẹ̀mú;  ṣùgbọ́n lókè orí rẹ̀ ni àwọn kérúbù+ ológo tí ń ṣíji bo ìbòrí ìpẹ̀tù+ wà. Ṣùgbọ́n ìsinsìnyí kọ́ ni àkókò láti sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí.  Lẹ́yìn tí a ti kọ́ nǹkan wọ̀nyí lọ́nà yìí, àwọn àlùfáà a máa wọ ojúlé+ àgọ́ àkọ́kọ́ ní gbogbo ìgbà láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀;+  ṣùgbọ́n inú ojúlé kejì ni àlùfáà àgbà nìkan ṣoṣo ń wọ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún,+ kì í ṣe láìsí ẹ̀jẹ̀,+ èyí tí ó fi ń rúbọ fún ara rẹ̀+ àti fún ẹ̀ṣẹ̀ àìmọ̀ àwọn ènìyàn náà.+  Báyìí ni ẹ̀mí mímọ́ mú un ṣe kedere pé ọ̀nà+ sí ibi mímọ́ ni a kò tíì fi hàn kedere nígbà tí àgọ́ àkọ́kọ́ ṣì wà ní ìdúró.+  Àgọ́ yìí gan-an jẹ́ àpèjúwe+ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀ tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí,+ àti pé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀, àwọn ẹ̀bùn àti ohun ẹbọ ni a fi ń rúbọ.+ Àmọ́ ṣá o, ìwọ̀nyí kò lè sọ ènìyàn tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ di pípé+ ní ti ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀,+ 10  ṣùgbọ́n ó ní í ṣe pẹ̀lú kìkì àwọn oúnjẹ+ àti ohun mímu+ àti onírúurú ìbatisí.+ Wọ́n jẹ́ àwọn ohun tí òfin béèrè tí ó jẹmọ́ ẹran ara,+ a sì gbé wọn kani lórí títí di àkókò tí a yàn kalẹ̀ láti mú àwọn nǹkan tọ́.+ 11  Àmọ́ ṣá o, nígbà tí Kristi dé gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà+ àwọn ohun rere tí ó ti ṣẹlẹ̀, nípasẹ̀ àgọ́ títóbi jù àti pípé jù tí a kò fi ọwọ́ ṣe èyíinì ni pé, kì í ṣe ti ìṣẹ̀dá yìí,+ 12  ó wọlé sínú ibi mímọ́, rárá, kì í ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀+ àwọn ewúrẹ́ àti ti àwọn ẹgbọrọ akọ màlúù, bí kò ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀+ òun fúnra rẹ̀, lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé, ó sì gba ìdáǹdè àìnípẹ̀kun fún wa.+ 13  Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ àwọn ewúrẹ́+ àti ti àwọn akọ màlúù+ àti eérú+ ẹgbọrọ abo màlúù tí a fi wọ́n àwọn tí ó di ẹlẹ́gbin+ bá ń sọni di mímọ́ dé àyè ìmọ́tónítóní ara,+ 14  mélòómélòó ni ẹ̀jẹ̀+ Kristi, ẹni tí ó tipasẹ̀ ẹ̀mí àìnípẹ̀kun fi ara rẹ̀ rúbọ+ sí Ọlọ́run láìní àbààwọ́n, yóò wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́+ kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́+ kí a lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀+ fún Ọlọ́run alààyè? 15  Nítorí náà, ìdí nìyẹn tí òun fi jẹ́ alárinà+ májẹ̀mú tuntun, kí àwọn tí a ti pè lè gba ìlérí ogún àìnípẹ̀kun,+ nítorí tí ikú kan ti ṣẹlẹ̀ fún ìtúsílẹ̀ wọn nípasẹ̀ ìràpadà+ kúrò nínú àwọn ìrélànàkọjá lábẹ́ májẹ̀mú ti ìṣáájú.+ 16  Nítorí níbi tí májẹ̀mú+ bá wà, ikú ẹ̀dá ènìyàn olùdámájẹ̀mú náà ni a ní láti pèsè. 17  Nítorí májẹ̀mú lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ lórí àwọn ẹran ẹbọ tí ó ti kú, níwọ̀n bí kò ti sí lẹ́nu iṣẹ́ ní àkókò èyíkéyìí tí ẹ̀dá ènìyàn olùdámájẹ̀mú náà ń bẹ láàyè. 18  Nítorí náà, a kò ṣe ìfilọ́lẹ̀ májẹ̀mú ti ìṣáájú+ láìsí ẹ̀jẹ̀.+ 19  Nítorí nígbà tí Mósè ti sọ gbogbo àṣẹ ní ìbámu pẹ̀lú Òfin fún gbogbo ènìyàn náà,+ ó gbé ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹgbọrọ akọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́ pẹ̀lú omi àti irun àgùntàn rírẹ̀dòdò àti ewéko hísópù,+ ó sì fi wọ́n ìwé náà àti gbogbo àwọn ènìyàn náà, 20  ní sísọ pé: “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti gbé kà yín lórí gẹ́gẹ́ bí àṣẹ.”+ 21  Ó sì fi ẹ̀jẹ̀+ náà wọ́n àgọ́+ àti gbogbo ohun èlò iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn bákan náà. 22  Bẹ́ẹ̀ ni, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ohun gbogbo ni a fi ẹ̀jẹ̀+ wẹ̀ mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú Òfin, bí kò sì ṣe pé a tú ẹ̀jẹ̀ jáde,+ ìdáríjì kankan kì í wáyé.+ 23  Nítorí náà, ó pọndandan pé kí a wẹ àwọn àwòrán ìṣàpẹẹrẹ+ àwọn ohun ti ọ̀run mọ́ nípasẹ̀ ohun àmúlò wọ̀nyí,+ ṣùgbọ́n àwọn ohun ti ọ̀run pẹ̀lú àwọn ẹbọ tí ó dára ju irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ lọ. 24  Nítorí tí Kristi kò wọlé sí ibi mímọ́ tí a fi ọwọ́ ṣe,+ tí ó jẹ́ ẹ̀dà ti òtítọ́,+ bí kò ṣe sí ọ̀run,+ nísinsìnyí láti fara hàn níwájú Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fún wa.+ 25  Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe kí ó lè máa fi ara rẹ̀ rubọ lọ́pọ̀ ìgbà, gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà ti máa ń wọ ibi mímọ́+ lọ ní tòótọ́ láti ọdún dé ọdún+ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ tí kì í ṣe tirẹ̀. 26  Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, òun ì bá ní láti máa jìyà lọ́pọ̀ ìgbà láti ìgbà pípilẹ̀+ ayé. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípasẹ̀ ẹbọ òun fúnra rẹ̀,+ ó ti fi ara rẹ̀ hàn kedere+ ní ìparí àwọn ètò àwọn nǹkan+ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo+ láìtún tún un ṣe mọ́ láé. 27  Bí a sì ti fi í lélẹ̀ gedegbe fún àwọn ènìyàn+ láti kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún kú mọ́ láé, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí ìdájọ́,+ 28  bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a fi Kristi rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo+ láìtún tún un ṣe mọ́ láé láti ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀;+ ní ìgbà kejì+ tí ó bá sì fara hàn,+ yóò jẹ́ láìsí ẹ̀ṣẹ̀+ àti fún àwọn tí ń fi taratara wá a fún ìgbàlà wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé