Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Hébérù 8:1-13

8  Wàyí o, ní ti àwọn ohun tí a ń jíròrò, lájorí kókó rẹ̀ nìyí: Àwa ní irúfẹ́ àlùfáà àgbà+ yìí, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọba Ọlọ́lá ní ọ̀run,+  ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn ní ibi mímọ́+ àti ní àgọ́ tòótọ́, tí Jèhófà+ gbé ró, kì í sì í ṣe ènìyàn.+  Nítorí olúkúlùkù àlùfáà àgbà ni a yàn sípò láti fi àwọn ẹ̀bùn àti ohun ẹbọ+ rúbọ; nípa bẹ́ẹ̀, ó pọndandan fún ẹni yìí pẹ̀lú láti ní ohun kan láti fi rúbọ.+  Wàyí o, bí ó bá jẹ́ pé orí ilẹ̀ ayé ni ó wà, kì yóò jẹ àlùfáà,+ bí ó ti jẹ́ pé àwọn ènìyàn wà tí ń fi àwọn ẹ̀bùn rúbọ ní ìbámu pẹ̀lú Òfin,  ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ ní àwòrán ìṣàpẹẹrẹ+ àti ní òjìji+ àwọn ohun ti ọ̀run; gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti fún Mósè ní àṣẹ àtọ̀runwá,+ nígbà tí ó máa tó ṣe àgọ́+ náà ní àṣeparí: Nítorí tí ó wí pé: “Rí i pé o ṣe ohun gbogbo ní ìbámu pẹ̀lú àwòṣe wọn tí a fi hàn ọ́ ní òkè ńlá náà.”+  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí Jésù ti rí iṣẹ́ ìsìn kan fún gbogbo ènìyàn gbà tí ó tayọ lọ́lá, tí ó fi jẹ́ pé òun tún ni alárinà+ májẹ̀mú+ tí ó dára jù lọ́nà tí ó ṣe rẹ́gí, èyí tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin lórí àwọn ìlérí dídára jù.+  Nítorí bí májẹ̀mú àkọ́kọ́ yẹn bá ti jẹ́ aláìní-àléébù, a kì bá ti wá àyè kankan fún èkejì;+  nítorí ó rí àléébù lára àwọn ènìyàn náà nígbà tí ó wí pé: “‘Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun;+  kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú+ tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá ní ọjọ́ tí mo di ọwọ́ wọn mú láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ nítorí tí wọn kò bá a lọ ní wíwà nínú májẹ̀mú mi,+ tí mo fi dẹ́kun títọ́jú wọn,’ ni Jèhófà wí.”+ 10  “‘Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ọjọ́ wọnnì,’ ni Jèhófà wí. ‘Ṣe ni èmi yóò fi àwọn òfin mi sínú èrò inú wọn, inú ọkàn-àyà+ wọn sì ni èmi yóò kọ wọ́n sí. Èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn,+ àwọn fúnra wọn yóò sì di ènìyàn mi.+ 11  “‘Lọ́nàkọnà, olúkúlùkù wọn kì yóò sì máa kọ́ aráàlú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àti olúkúlùkù wọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Mọ Jèhófà!”+ Nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí,+ láti orí ẹni tí ó kéré jù lọ títí dé orí ẹni tí ó tóbi jù lọ nínú wọn. 12  Nítorí tí èmi yóò jẹ́ aláàánú sí àwọn ìṣe àìṣòdodo wọn, lọ́nàkọnà èmi kì yóò sì rántí ẹ̀ṣẹ̀+ wọn mọ́.’”+ 13  Ní sísọ tí ó sọ pé “májẹ̀mú tuntun,” ó ti sọ èyí ti ìṣáájú di aláìbódemu+ mọ́. Wàyí o, èyíinì ti a sọ di aláìbódemu mọ́, tí ó sì ń gbó lọ ti sún mọ́ pípòórá.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé