Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Hébérù 7:1-28

7  Nítorí Melikisédékì yìí, ọba Sálẹ́mù, àlùfáà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ,+ ẹni tí ó pàdé Ábúráhámù tí ń padà bọ̀ lẹ́nu pípa àwọn ọba, tí ó sì súre fún un,+  ẹni tí Ábúráhámù sì pín ìdá mẹ́wàá láti inú ohun gbogbo fún,+ lákọ̀ọ́kọ́ ná, nípa ìtúmọ̀, ó jẹ́ “Ọba Òdodo,” àti lẹ́yìn náà, ó tún jẹ́ ọba Sálẹ́mù,+ èyíinì ni, “Ọba Àlàáfíà.”  Ní jíjẹ́ aláìní baba, aláìní ìyá, aláìní ìtàn ìlà ìdílé, aláìní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọjọ́+ tàbí òpin ìwàláàyè, ṣùgbọ́n tí a ṣe é bí Ọmọ Ọlọ́run,+ ó dúró gẹ́gẹ́ bí àlùfáà títí lọ fáàbàdà.+  Nígbà náà, ẹ ṣàkíyèsí bí [ọkùnrin] yìí ti tóbi tó, ẹni tí Ábúráhámù, olórí ìdílé, fún ní ìdá mẹ́wàá láti inú olórí àwọn ohun ìfiṣèjẹ.+  Ní tòótọ́, àwọn ọkùnrin láti inú àwọn ọmọ Léfì+ tí wọ́n gba ipò iṣẹ́ àlùfáà wọn, ní àṣẹ láti gba ìdá mẹ́wàá+ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn+ ní ìbámu pẹ̀lú Òfin, èyíinì ni, lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn, bí àwọn wọ̀nyí bá tilẹ̀ ti jáde láti abẹ́nú Ábúráhámù+ pàápàá;  ṣùgbọ́n ọkùnrin tí kò tọpa ìtàn ìlà ìdílé+ rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ wọn gba ìdá mẹ́wàá lọ́wọ́ Ábúráhámù,+ ó sì súre fún ẹni tí ó gba àwọn ìlérí.+  Wàyí o, láìsí awuyewuye kankan, ẹni tí ó tóbi jù ni ó máa ń súre fún ẹni tí ó rẹlẹ̀.+  Àti pé nínú ọ̀ràn kan, àwọn ènìyàn tí ń kú ní ń gba ìdá mẹ́wàá,+ ṣùgbọ́n nínú ọ̀ràn kejì, ó jẹ́ ẹnì kan tí a jẹ́rìí nípa rẹ̀ pé ó wà láàyè.+  Àti pé, bí mo bá lè lo ọ̀rọ̀ náà pé, nípasẹ̀ Ábúráhámù, àní Léfì tí ń gba ìdá mẹ́wàá ti san ìdá mẹ́wàá, 10  nítorí tí ó ṣì wà ní abẹ́nú+ baba ńlá rẹ̀ nígbà tí Melikisédékì pàdé rẹ̀.+ 11  Nígbà náà, bí ìjẹ́pípé+ bá jẹ́ nípasẹ̀ iṣẹ́ àlùfáà àwọn ọmọ Léfì+ ní ti tòótọ́, (nítorí a fún àwọn ènìyàn náà ní Òfin+ pẹ̀lú òun gẹ́gẹ́ bí apá pàtàkì kan,) àìní mìíràn wo ni ì bá tún wà+ fún àlùfáà mìíràn láti dìde ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Melikisédékì,+ tí a kò sì sọ pé ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Áárónì? 12  Nítorí níwọ̀n bí a ti ń pààrọ̀ iṣẹ́ àlùfáà,+ ó di dandan kí ìpààrọ̀ òfin pẹ̀lú wáyé.+ 13  Nítorí ọkùnrin tí a sọ nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ jẹ́ mẹ́ńbà ẹ̀yà mìíràn,+ láti inú èyí tí kò tíì sí ẹnì kankan tí ó bójú tó iṣẹ́ nídìí pẹpẹ.+ 14  Nítorí ó ṣe kedere pé Olúwa wa jáde wá láti inú Júdà,+ ẹ̀yà kan nípa èyí tí Mósè kò sọ ohunkóhun nípa àwọn àlùfáà. 15  Ó sì ṣe kedere lọ́pọ̀lọpọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ síbẹ̀ pé ní ìfarajọra pẹ̀lú Melikisédékì,+ àlùfáà+ mìíràn dìde, 16  ẹni tí ó ti dà bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú òfin àṣẹ tí ó sinmi lórí ẹran ara,+ ṣùgbọ́n ní ìbámu pẹ̀lú agbára ìwàláàyè tí kò ṣeé pa run,+ 17  nítorí nínú ìjẹ́rìí a sọ ọ́ pé: “Ìwọ jẹ́ àlùfáà títí láé ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Melikisédékì.”+ 18  Dájúdájú, nígbà náà, pípa àṣẹ tí ó ti wà ṣáájú tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan ti wáyé ní tìtorí àìlera+ àti àìgbéṣẹ́+ rẹ̀. 19  Nítorí tí Òfin kò sọ ohunkóhun di pípé,+ ṣùgbọ́n mímú ìrètí+ dídárajù wọlé lọ́tọ̀ ni ó ṣe bẹ́ẹ̀, nípasẹ̀ èyí tí àwa ń sún mọ́ Ọlọ́run.+ 20  Pẹ̀lúpẹ̀lù, dé àyè tí ó fi jẹ́ pé kò wà láìsí ìbúra tí a ṣe, 21  (nítorí àwọn ènìyàn wà ní tòótọ́ tí wọ́n ti di àlùfáà láìsí ìbúra tí a ṣe, ṣùgbọ́n ọ̀kan wà pẹ̀lú ìbúra kan tí a ṣe láti ọwọ́ Ẹni tí ó sọ nípa rẹ̀ pé: “Jèhófà ti búra+ (kì yóò sì pèrò dà), ‘Ìwọ jẹ́ àlùfáà títí láé,’”)+ 22  dé àyè yẹn pẹ̀lú, Jésù ti di ẹni tí a fi ṣe ohun ìdógò fún májẹ̀mú tí ó dára jù.+ 23  Síwájú sí i, ó ti di dandan fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti di àlùfáà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé+ nítorí tí ikú+ ṣèdíwọ́ fún wọn láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ bẹ́ẹ̀, 24  ṣùgbọ́n òun nítorí bíbá a lọ ní wíwàláàyè títí láé,+ ó ní iṣẹ́ àlùfáà rẹ̀ láìsí àwọn arọ́pò kankan. 25  Nítorí náà, ó lè gba àwọn tí ń tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀ là pátápátá pẹ̀lú, nítorí tí òun wà láàyè nígbà gbogbo láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wọn.+ 26  Nítorí irúfẹ́ àlùfáà àgbà yìí ni ó yẹ wá,+ adúróṣinṣin,+ aláìlẹ́tàn,+ aláìlẹ́gbin,+ tí a yà sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,+ tí ó sì di ẹni gíga ju ọ̀run lọ.+ 27  Òun kò nílò láti máa rú àwọn ẹbọ lójoojúmọ́,+ lákọ̀ọ́kọ́ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀+ àti lẹ́yìn náà fún ti àwọn ènìyàn,+ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà wọnnì ti ń ṣe: (nítorí èyí ni ó ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo+ láìtún tún un ṣe mọ́ láé nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rúbọ;)+ 28  nítorí tí Òfin ń yan àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àìlera+ sípò gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà,+ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ìbúra+ tí a ṣe tí ó wá lẹ́yìn Òfin yan Ọmọ sípò, ẹni tí a sọ di pípé+ títí láé.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé