Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Hébérù 6:1-20

6  Fún ìdí yìí, nísinsìnyí tí a ti fi àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀+ ẹ̀kọ́ nípa Kristi+ sílẹ̀, ẹ jẹ́ kí a tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú,+ kí a má tún máa fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ mọ́,+ èyíinì ni, ìrònúpìwàdà kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́,+ àti ìgbàgbọ́ sípa Ọlọ́run,+  ẹ̀kọ́ lórí àwọn ìbatisí+ àti gbígbé ọwọ́ léni,+ àjíǹde àwọn òkú+ àti ìdájọ́ àìnípẹ̀kun.+  Èyí ni àwa yóò ṣe, bí Ọlọ́run bá yọ̀ǹda+ ní tòótọ́.  Nítorí kò ṣeé ṣe ní ti àwọn tí a ti là lóye+ lẹ́ẹ̀kan, tí wọ́n ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ti ọ̀run wò,+ tí wọ́n ti di alábàápín nínú ẹ̀mí mímọ́,+  tí wọ́n sì ti tọ́+ àtàtà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn agbára ètò àwọn nǹkan+ tí ń bọ̀ wò,  ṣùgbọ́n tí wọ́n ti yẹsẹ̀,+ láti tún mú wọn sọ jí sí ìrònúpìwàdà,+ nítorí tí wọ́n kan Ọmọ Ọlọ́run mọ́gi ní ọ̀tun fún ara wọn, wọ́n sì gbé e síta fún ìtìjú ní gbangba.+  Fún àpẹẹrẹ, ilẹ̀ tí ń fa òjò tí ó máa ń wá sórí rẹ̀ mu, àti lẹ́yìn náà, tí ń mú ewéko jáde èyí tí ó yẹ fún àwọn tí a tìtorí wọn ro ó+ pẹ̀lú, ń rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní ìdápadà.  Ṣùgbọ́n bí ó bá ń mú àwọn ẹ̀gún àti òṣùṣú jáde, a di kíkọ̀tì a sì sún mọ́ ìfigégùn-ún;+ a sì parí sí fífi iná sun ún.+  Àmọ́ ṣá o, nínú ọ̀ràn tiyín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, a gbà gbọ́ dájú nípa àwọn ohun dídárajù àti àwọn ohun tí ń bá ìgbàlà rìn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń sọ̀rọ̀ lọ́nà yìí. 10  Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀,+ ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́,+ ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́. 11  Ṣùgbọ́n a fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi akitiyan kan náà hàn, kí ẹ lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú+ ìrètí+ náà títí dé òpin,+ 12  kí ẹ má bàa di onílọ̀ọ́ra,+ ṣùgbọ́n kí ẹ jẹ́ aláfarawé+ àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.+ 13  Nítorí nígbà tí Ọlọ́run ṣe ìlérí rẹ̀ fún Ábúráhámù,+ níwọ̀n bí kò ti lè fi ẹnì kankan tí ó tóbi jù ú búra, ó fi ara rẹ̀ búra,+ 14  ní sísọ pé: “Dájúdájú, ní bíbùkún èmi yóò bù kún ọ, àti ní sísọ di púpọ̀ sí i èmi yóò sọ ọ́ di púpọ̀ sí i.”+ 15  Nípa báyìí, lẹ́yìn tí Ábúráhámù ti fi sùúrù hàn, ó rí ìlérí yìí gbà.+ 16  Nítorí àwọn ènìyàn a máa fi ẹni tí ó tóbi jù wọ́n búra,+ ìbúra wọn a sì máa jẹ́ òpin gbogbo awuyewuye, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà lábẹ́ òfin fún wọn.+ 17  Lọ́nà yìí, nígbà tí ó pète láti fi àìlèyípadà+ ìpinnu rẹ̀ hàn lọ́pọ̀ yanturu fún àwọn ajogún+ ìlérí náà, Ọlọ́run mú ìbúra kan wọ̀ ọ́, 18  pé, nípasẹ̀ ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́,+ kí àwa tí a ti sá sí ibi ìsádi lè ní ìṣírí tí ó lágbára láti gbá ìrètí+ tí a gbé ka iwájú wa mú. 19  Ìrètí+ yìí ni àwa ní gẹ́gẹ́ bí ìdákọ̀ró fún ọkàn, ó dájú, ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in, ó sì wọlé lọ sẹ́yìn aṣọ ìkélé,+ 20  níbi tí aṣíwájú kan ti wọ̀ lọ nítorí wa,+ Jésù, ẹni tí ó ti di àlùfáà àgbà ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Melikisédékì títí láé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé