Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Hébérù 5:1-14

5  Nítorí olúkúlùkù àlùfáà àgbà tí a mú láàárín àwọn ènìyàn ni a yàn sípò nítorí ènìyàn lórí àwọn ohun tí ó jẹmọ́ ti Ọlọ́run,+ kí ó lè fi àwọn ẹ̀bùn àti àwọn ohun ẹbọ rúbọ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀.+  Ó lè fi ìwọ̀ntúnwọ̀nsì bá àwọn aláìmọ̀kan àti àwọn tí ń ṣìnà lò, níwọ̀n bí àìlera+ tirẹ̀ ti yí òun pẹ̀lú ká,  àti nítorí rẹ̀, ó di dandan fún un láti ṣe ọrẹ ẹbọ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe fún àwọn ènìyàn.+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ọkùnrin kan a máa gba ọlá yìí, kì í ṣe láti inú ìdánúṣe ti ara rẹ̀,+ ṣùgbọ́n kìkì nígbà tí Ọlọ́run bá pè é,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti pe Áárónì+ pẹ̀lú.  Bákan náà pẹ̀lú, Kristi kò ṣe ara rẹ̀ lógo+ nípa dídi àlùfáà àgbà,+ ṣùgbọ́n a ṣe é lógo+ láti ọwọ́ ẹni tí ó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé: “Ìwọ ni ọmọ mi; òní ni èmi, àní èmi, di baba rẹ.”+  Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ ní ibòmíràn pẹ̀lú pé: “Ìwọ jẹ́ àlùfáà títí láé ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Melikisédékì.”+  Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀ nínú ẹran ara, [Kristi] ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti ìtọrọ+ pẹ̀lú sí Ẹni tí ó lè gbà á là kúrò nínú ikú, pẹ̀lú igbe ẹkún kíkankíkan+ àti omijé, a sì gbọ́ ọ pẹ̀lú ojú rere nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ fún Ọlọ́run.+  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ Ọmọ, ó kọ́ ìgbọràn láti inú àwọn ohun tí ó jìyà rẹ̀;+  àti lẹ́yìn tí a ti sọ ọ́ di pípé,+ ó di ẹni tí ó ní ẹrù iṣẹ́ fún mímú ìgbàlà àìnípẹ̀kun+ wá fún gbogbo àwọn tí ń ṣègbọràn sí i,+ 10  nítorí ní pàtó, Ọlọ́run ti pè é ní àlùfáà àgbà ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Melikisédékì.+ 11  Nípa rẹ̀, a ní púpọ̀ láti sọ, tí ó sì ṣòro láti ṣàlàyé, níwọ̀n bí ẹ ti yigbì ní gbígbọ́.+ 12  Nítorí, ní tòótọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí ẹ jẹ́ olùkọ́+ ní ojú ìwòye ibi tí àkókò dé yìí, ẹ tún nílò kí ẹnì kan máa kọ́ yín láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀+ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run;+ ẹ sì ti di irúfẹ́ àwọn tí ó nílò wàrà, kì í ṣe oúnjẹ líle.+ 13  Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń mu wàrà jẹ́ aláìdojúlùmọ̀ ọ̀rọ̀ òdodo, nítorí tí ó jẹ́ ìkókó.+ 14  Ṣùgbọ́n oúnjẹ líle jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú, ti àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye+ wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé