Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Hébérù 3:1-19

3  Nítorí náà, ẹ̀yin ará mímọ́, alábàápín ìpè ti ọ̀run,+ ẹ ronú nípa àpọ́sítélì+ àti àlùfáà àgbà tí àwa jẹ́wọ́+—Jésù.  Ó jẹ́ olùṣòtítọ́+ sí Ẹni tí ó ṣe é bẹ́ẹ̀, bí Mósè+ pẹ̀lú ti jẹ́ ní gbogbo ilé Ẹni yẹn.+  Nítorí tí a ka ẹnì kejì yìí yẹ fún ògo+ tí ó ju ti Mósè lọ, níwọ̀n bí ẹni+ tí ó kọ́lé ti ní ọlá ju ilé náà lọ.+  Dájúdájú, olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.+  Mósè gẹ́gẹ́ bí ẹmẹ̀wà+ sì jẹ́ olùṣòtítọ́ ní gbogbo ilé Ẹni yẹn gẹ́gẹ́ bí gbólóhùn ẹ̀rí àwọn ohun tí a ó sọ lẹ́yìn ìgbà náà,+  ṣùgbọ́n Kristi jẹ́ olùṣòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí Ọmọ+ lórí ilé Ẹni yẹn. Àwa jẹ́ ilé Ẹni yẹn,+ bí a bá di òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ wa mú ṣinṣin àti ìṣògo wa lórí ìrètí náà ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in títí dé òpin.+  Fún ìdí yìí, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí mímọ́+ ti wí pé: “Lónìí, bí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀,+  ẹ má ṣe sé ọkàn-àyà yín le bí ti àkókò fífa ìbínú kíkorò,+ bí ti ọjọ́ dídánniwò+ ní aginjù,+  nínú èyí tí àwọn baba ńlá yín fi àdánwò dán mi wò, síbẹ̀ wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́+ mi fún ogójì ọdún.+ 10  Fún ìdí yìí, ọ̀ràn ìran yìí sú mi, mo sì wí pé, ‘Nígbà gbogbo ni wọ́n ń ṣáko lọ nínú ọkàn-àyà wọn,+ àwọn fúnra wọn kò sì mọ àwọn ọ̀nà mi.’+ 11  Nítorí náà, mo búra nínú ìbínú mi pé, ‘Dájúdájú, wọn kì yóò wọnú+ ìsinmi mi.’”+ 12  Ẹ kíyè sára, ẹ̀yin ará, kí ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́ má bàa dìde nínú ẹnikẹ́ni nínú yín láé nípa lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè;+ 13  ṣùgbọ́n ẹ máa bá a nìṣó ní gbígba ara yín níyànjú+ lẹ́nì kìíní-kejì lójoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ti lè pè é ní “Òní,”+ kí agbára ìtannijẹ+ ẹ̀ṣẹ̀ má bàa sọ ẹnikẹ́ni nínú yín di aláyà líle. 14  Nítorí àwa di alábàápín nínú Kristi+ ní ti gidi kìkì bí a bá di ìgbọ́kànlé tí a ní ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ mú ṣinṣin ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in títí dé òpin,+ 15  nígbà tí a ń sọ pé: “Lónìí, bí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀,+ ẹ má ṣe sé ọkàn-àyà yín le bí ti àkókò fífa ìbínú kíkorò.”+ 16  Nítorí àwọn wo ni wọ́n gbọ́, síbẹ̀síbẹ̀ tí wọ́n ṣokùnfà ìbínú kíkorò?+ Ní tòótọ́, kì í ha ṣe gbogbo àwọn tí wọ́n jáde kúrò ní Íjíbítì lábẹ́ Mósè+ ni wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? 17  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn wo ni ọ̀ràn wọ́n sú Ọlọ́run fún ogójì ọdún?+ Kì í ha ṣe àwọn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀, tí òkú wọ́n ṣubú ní aginjù?+ 18  Ṣùgbọ́n àwọn wo ni ó búra+ fún pé wọn kò ní wọnú ìsinmi òun bí kò ṣe àwọn tí wọ́n ṣe àìgbọràn?+ 19  Nítorí náà, a rí i pé wọn kò lè wọnú rẹ̀ nítorí àìnígbàgbọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé