Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Hébérù 13:1-25

13  Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ ará tí ẹ ní máa bá a lọ.+  Ẹ má gbàgbé aájò àlejò,+ nítorí nípasẹ̀ rẹ̀, àwọn kan ṣe àwọn áńgẹ́lì+ lálejò, láìjẹ́ pé àwọn fúnra wọn mọ̀.  Ẹ máa fi àwọn tí ń bẹ nínú àwọn ìdè+ ẹ̀wọ̀n sọ́kàn bí ẹni pé a dè yín pẹ̀lú wọn,+ àti àwọn tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́,+ níwọ̀n bí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú ti wà nínú ara síbẹ̀.  Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin,+ nítorí Ọlọ́run yóò dá àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà lẹ́jọ́.+  Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó,+ bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn+ pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí.+ Nítorí òun ti wí pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.”+  Kí a lè jẹ́ onígboyà gidi gan-an,+ kí a sì sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà. Kí ni ènìyàn lè fi mí ṣe?”+  Ẹ máa rántí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín,+ tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, bí ẹ sì ti ń fẹ̀sọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò bí ìwà wọ́n ti rí, ẹ máa fara wé+ ìgbàgbọ́ wọn.+  Jésù Kristi jẹ́ ọ̀kan náà lánàá àti lónìí, àti títí láé.+  Kí a má ṣe fi onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́+ gbé yín lọ; nítorí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ kí a fún ọkàn-àyà ní ìfìdímúlẹ̀ gbọn-in nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí,+ kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn ohun jíjẹ,+ èyí tí kò ṣàǹfààní fún àwọn tí ó fi ara wọn fún nǹkan wọ̀nyí. 10  Àwa ní pẹpẹ kan láti orí èyí tí àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ níbi àgọ́ kò ní ọlá àṣẹ láti jẹ.+ 11  Nítorí ara ẹran wọnnì tí àlùfáà àgbà ń mú ẹ̀jẹ̀ wọn wọ ibi mímọ́ fún ẹ̀ṣẹ̀ ni a ń sun lẹ́yìn òde ibùdó.+ 12  Nítorí bẹ́ẹ̀, Jésù pẹ̀lú, kí ó lè fi ẹ̀jẹ̀+ ara rẹ sọ àwọn ènìyàn náà di mímọ́,+ jìyà lẹ́yìn òde ibodè.+ 13  Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí a jáde lọ bá a lẹ́yìn òde ibùdó, ní ríru ẹ̀gàn tí ó rù,+ 14  nítorí a kò ní ìlú ńlá kan níhìn-ín tí ń bá a lọ ní wíwà,+ ṣùgbọ́n a ń fi taratara wá ọ̀kan tí ń bọ̀.+ 15  Nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn+ sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè+ tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.+ 16  Ní àfikún, ẹ má gbàgbé rere ṣíṣe+ àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.+ 17  Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín,+ kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba,+ nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn;+ kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.+ 18  Ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà+ fún wa, nítorí àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé a ní ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí, gẹ́gẹ́ bí a ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.+ 19  Ṣùgbọ́n mo gbà yín níyànjú pàápàá jù lọ láti ṣe èyí, kí a lè tètè mú mi padà bọ̀ sípò sọ́dọ̀ yín.+ 20  Wàyí o, kí Ọlọ́run àlàáfíà,+ ẹni tí ó gbé olùṣọ́ àgùntàn ńlá+ ti àwọn àgùntàn+ dìde kúrò nínú òkú+ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú àìnípẹ̀kun,+ Olúwa wa Jésù, 21  fi ohun rere gbogbo mú yín gbára dì láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ní ṣíṣe èyíinì tí ó dára gidigidi ní ojú rẹ̀+ nínú wa nípasẹ̀ Jésù Kristi; ẹni tí ògo jẹ́ tirẹ̀ títí láé àti láéláé.+ Àmín. 22  Wàyí o, mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, láti gba ọ̀rọ̀ ìṣírí yìí mọ́ra, nítorí ní tòótọ́, mo ti kọ lẹ́tà kan sí yín ní ọ̀rọ̀ díẹ̀.+ 23  Ẹ fiyè sí i pé a ti tú arákùnrin wa Tímótì+ sílẹ̀, ẹni tí èmi pẹ̀lú rẹ̀ yóò rí yín, bí ó bá tètè dé láìpẹ́. 24  Ẹ bá mi kí gbogbo àwọn tí ń mú ipò iwájú+ láàárín yín àti gbogbo ẹni mímọ́. Àwọn tí ń bẹ ni Ítálì+ kí yín. 25  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ wà pẹ̀lú gbogbo yín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé