Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Hébérù 11:1-40

11  Ìgbàgbọ́+ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí,+ ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.+  Nítorí nípasẹ̀ èyí, àwọn ènìyàn ìgbà láéláé ní ẹ̀rí tí a jẹ́ sí wọn.+  Nípa ìgbàgbọ́ ni a róye pé àwọn ètò àwọn nǹkan+ ni a mú wà létòletò nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,+ tí ó fi jẹ́ pé ohun tí a rí ti wá di èyí tí ó jáde wá láti inú àwọn ohun tí kò fara hàn.+  Nípa ìgbàgbọ́ ni Ébẹ́lì rú ẹbọ tí ó níye lórí ju ti Kéènì+ sí Ọlọ́run, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ náà tí ó fi ní ẹ̀rí tí a jẹ́ sí i pé ó jẹ́ olódodo, tí Ọlọ́run ń jẹ́rìí+ nípa àwọn ẹ̀bùn rẹ̀; àti nípasẹ̀ èyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kú, ó ń sọ̀rọ̀ síbẹ̀.+  Nípa ìgbàgbọ́ ni a ṣí Énọ́kù+ nípò padà láti má ṣe rí ikú, a kò sì rí i níbi kankan nítorí tí Ọlọ́run ti ṣí i nípò padà;+ nítorí ṣáájú ìṣínípòpadà rẹ̀, ó ní ẹ̀rí náà pé ó ti wu Ọlọ́run dáadáa.+  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, láìsí ìgbàgbọ́+ kò ṣeé ṣe láti wù ú dáadáa,+ nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ+ àti pé òun ni olùsẹ̀san+ fún àwọn tí ń fi taratara wá a.+  Nípa ìgbàgbọ́ ni Nóà,+ lẹ́yìn fífún un ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nípa àwọn ohun tí a kò tíì rí,+ fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn, ó sì kan ọkọ̀ áàkì+ fún ìgbàlà agbo ilé rẹ̀; àti nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yìí, ó dá ayé lẹ́bi,+ ó sì di ajogún òdodo+ tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́.  Nípa ìgbàgbọ́ ni Ábúráhámù,+ nígbà tí a pè é, fi ṣègbọràn ní jíjáde lọ sí ibì kan tí a ti yàn án tẹ́lẹ̀ láti gbà gẹ́gẹ́ bí ogún; ó sì jáde lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ ibi tí òun ń lọ.+  Nípa ìgbàgbọ́ ni ó ṣe àtìpó ní ilẹ̀ ìlérí bí ní ilẹ̀ òkèèrè,+ ó sì gbé nínú àwọn àgọ́+ pẹ̀lú Ísákì+ àti Jékọ́bù,+ àwọn ajogún ìlérí+ kan náà pẹ̀lú rẹ̀. 10  Nítorí tí ó ń dúró de ìlú ńlá+ tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́, ìlú ńlá tí olùtẹ̀dó àti olùṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run.+ 11  Nípa ìgbàgbọ́ ni Sárà+ fúnra rẹ̀ pẹ̀lú gba agbára láti lóyún irú-ọmọ, nígbà tí ó ti ré kọjá ààlà ọjọ́ orí+ pàápàá, níwọ̀n bí ó ti ka ẹni tí ó ṣèlérí sí olùṣòtítọ́.+ 12  Nítorí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, láti ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan,+ ẹni tí ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ má sàn ju òkú lọ,+ ni a ti bí àwọn ọmọ gẹ́gẹ́ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run ní ti ògìdìgbó àti gẹ́gẹ́ bí iyanrìn tí ó wà ní etí òkun, láìlóǹkà.+ 13  Gbogbo àwọn wọ̀nyí kú nínú ìgbàgbọ́,+ bí wọn kò tilẹ̀ rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí náà gbà,+ ṣùgbọ́n wọ́n rí wọn lókèèrè réré,+ wọ́n sì fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wọ́n, wọ́n sì polongo ní gbangba pé àwọn jẹ́ àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ náà.+ 14  Nítorí àwọn tí ó sọ irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀ pèsè ẹ̀rí pé àwọn ń fi taratara wá ibì kan tí ó jẹ́ tiwọn.+ 15  Síbẹ̀, bí wọ́n bá ti ń bá a nìṣó ní tòótọ́ ní rírántí ibi tí wọ́n ti jáde lọ,+ àyè ì bá ṣí sílẹ̀ fún wọn láti padà.+ 16  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, wọ́n ń nàgà sí ibi tí ó sàn jù, èyíinì ni, ọ̀kan tí ó jẹ́ ti ọ̀run.+ Nítorí bẹ́ẹ̀, wọn kò ti Ọlọ́run lójú, pé kí a máa ké pè é gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run wọn,+ nítorí tí ó ti pèsè ìlú ńlá+ kan sílẹ̀ fún wọn. 17  Nípa ìgbàgbọ́ ni Ábúráhámù, nígbà tí a dán an wò,+ kí a kúkú sọ pé ó ti fi Ísákì rúbọ tán, ọkùnrin tí ó sì ti fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gba àwọn ìlérí gbìdánwò láti fi ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo rúbọ,+ 18  bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti wí fún un pé: “Ohun tí a ó pè ní ‘irú-ọmọ rẹ’ yóò jẹ́ nípasẹ̀ Ísákì.”+ 19  Ṣùgbọ́n ó ṣírò pé Ọlọ́run lè gbé e dìde, àní kúrò nínú òkú;+ láti ibẹ̀, ó sì tún rí i gbà lọ́nà àpèjúwe.+ 20  Nípa ìgbàgbọ́ ni Ísákì pẹ̀lú súre fún Jékọ́bù+ àti Ísọ̀+ nípa àwọn ohun tí ń bọ̀. 21  Nípa ìgbàgbọ́ ni Jékọ́bù, nígbà tí ó máa tó kú,+ fi súre fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù,+ ó sì jọ́sìn ní sísinmi lé orí ọ̀pá rẹ̀.+ 22  Nípa ìgbàgbọ́ ni Jósẹ́fù, ní sísúnmọ́ òpin rẹ̀, mẹ́nu kan ìjádelọ+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; ó sì pa àṣẹ nípa àwọn egungun rẹ̀.+ 23  Nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn òbí Mósè fi fi í pa mọ́ fún oṣù mẹ́ta lẹ́yìn ìbí rẹ̀,+ nítorí tí wọ́n rí i pé ọmọ kékeré náà lẹ́wà,+ wọn kò sì bẹ̀rù àṣẹ ìtọ́ni+ ọba. 24  Nípa ìgbàgbọ́ ni Mósè, nígbà tí ó dàgbà,+ fi kọ̀ kí a máa pe òun ní ọmọkùnrin ti ọmọbìnrin Fáráò,+ 25  ó yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run dípò jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, 26  nítorí pé ó ka ẹ̀gàn+ Kristi sí ọrọ̀ tí ó tóbi ju àwọn ìṣúra Íjíbítì; nítorí tí ó tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà.+ 27  Nípa ìgbàgbọ́ ni ó fi Íjíbítì+ sílẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò bẹ̀rù ìbínú ọba,+ nítorí tí ó ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.+ 28  Nípa ìgbàgbọ́ ni ó fi ṣe ayẹyẹ ìrékọjá+ àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀,+ kí apanirun má bàa fọwọ́ kan àwọn àkọ́bí wọn.+ 29  Nípa ìgbàgbọ́ ni wọ́n la Òkun Pupa kọjá bí pé lórí ilẹ̀ gbígbẹ,+ ṣùgbọ́n àwọn ará Íjíbítì ni a gbé mì+ nígbà tí wọ́n dágbá lé e. 30  Nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn ògiri Jẹ́ríkò wó lulẹ̀ lẹ́yìn tí a ti pagbo yí i ká fún ọjọ́ méje.+ 31  Nípa ìgbàgbọ́ ni Ráhábù+ aṣẹ́wó kò ṣègbé pẹ̀lú àwọn tí ó ṣe àìgbọràn, nítorí tí ó gba àwọn amí pẹ̀lú ẹ̀mí àlàáfíà.+ 32  Kí ni kí n tún wí? Nítorí àkókò kì yóò tó fún mi bí mo bá ń bá a lọ láti ṣèròyìn nípa Gídíónì,+ Bárákì,+ Sámúsìnì,+ Jẹ́fútà,+ Dáfídì,+ àti Sámúẹ́lì+ àti àwọn wòlíì yòókù,+ 33  àwọn tí ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, wọ́n ṣẹ́gun àwọn ìjọba nínú ìforígbárí,+ wọ́n ṣiṣẹ́ òdodo yọrí,+ wọ́n rí àwọn ìlérí gbà,+ wọ́n dí ẹnu àwọn kìnnìún,+ 34  wọ́n dá ipá iná dúró,+ wọ́n yè bọ́ lọ́wọ́ ojú idà,+ láti ipò àìlera, a sọ wọ́n di alágbára,+ wọ́n di akíkanjú nínú ogun,+ wọ́n lé ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ilẹ̀ òkèèrè sá kìjokìjo.+ 35  Àwọn obìnrin rí àwọn òkú wọn gbà nípa àjíǹde;+ ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin mìíràn ni a dá lóró nítorí pé wọn kò jẹ́ tẹ́wọ́ gba ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà kankan, kí ọwọ́ wọn lè tẹ àjíǹde tí ó sàn jù. 36  Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn mìíràn rí àdánwò wọn gbà nípa ìfiṣẹlẹ́yà àti ìnàlọ́rẹ́, ní tòótọ́, ju èyíinì lọ, nípa àwọn ìdè+ àti ẹ̀wọ̀n.+ 37  A sọ wọ́n ní òkúta,+ a dán wọn wò,+ a fi ayùn rẹ́ wọn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n kú+ nípa fífi idà pa wọ́n, wọ́n lọ káàkiri nínú awọ àgùntàn,+ nínú awọ ewúrẹ́, nígbà tí wọ́n wà nínú àìní,+ nínú ìpọ́njú,+ lábẹ́ ìṣẹ́níṣẹ̀ẹ́;+ 38  ayé kò sì yẹ wọ́n. Wọ́n rìn káàkiri nínú àwọn aṣálẹ̀ àti àwọn òkè ńlá àti àwọn hòrò+ àti àwọn ihò inú ilẹ̀. 39  Síbẹ̀síbẹ̀, bí wọ́n tilẹ̀ ní ẹ̀rí tí a jẹ́ sí wọn nípa ìgbàgbọ́ wọn, gbogbo àwọn wọ̀nyí kò rí ìmúṣẹ ìlérí náà gbà,+ 40  gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti rí ohun tí ó dára jù+ tẹ́lẹ̀ fún wa,+ kí a má bàa sọ wọ́n+ di pípé+ láìsí àwa.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé